Orin 119
Ẹ Wá Gba Ìtura!
1. Ayé yìí ti ṣìnà, ó dorí kodò;
Wọn kò mọ ọ̀nà Ọlọ́run.
A nílò amọ̀nà táá máa darí wa;
A kò lè darí ara wa.
Ìpàdé la ti ńrítura, ìrètí;
Ó ńfún ìgbàgbọ́ wa lókun.
Ó ńmú ká gbọ́rọ̀ tó ńmú wa ṣe rere,
A ńgba okun táa fi ńbá a lọ.
A kò jẹ́ pa àṣẹ Jèhófà tì láé;
Ìfẹ́ rẹ̀ gan-an la fẹ́ máa ṣe.
Ìpàdé wa ńfi ọ̀nà tó tọ́ hàn wá;
Ìfẹ́ táa ní fóòótọ́ ńdọ̀tun.
2. Jèhófà mọ ohun tó yẹ wá dáadáa;
Ó yẹ ká gbọ́ ìmọ̀ràn rẹ̀.
Táa bá ńri dájú pé a ńlọ sípàdé,
Ọgbọ́n àtìgbàgbọ́ la ní.
Ìtọ́ni àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run
Ńkọ́ wa báa ṣe lè lògbàgbọ́.
Ìrànwọ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé
Ńjẹ́ ká mọ̀ pé aò nìkan wà.
Bí a sì ṣe ńwọ̀nà fún ìgbà ọ̀tun,
Aó báwọn táa nífẹ̀ẹ́ pàdé.
Nípàdé yìí laó sì ti kọ́ báó ṣe máa
Lo ọgbọ́n tó ti ọ̀run wá.
(Tún wo Sm. 37:18; 140:1; Òwe 18:1; Éfé. 5:16; Ják. 3:17.)