Orin 63
Jẹ́ Adúróṣinṣin
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Dúró ṣinṣin sí Jèhófà,
Jẹ́ ká dúró láìyẹsẹ̀.
Àwa tó ṣèyàsímímọ́,
Àṣẹ rẹ̀ laó máa pa mọ́.
Ìmọ̀ràn rẹ̀ kò ní kùnà,
Ìtọ́ni rẹ̀ laó tẹ̀ lé.
Olóòótọ́ ni; a gbẹ́kẹ̀ lée.
Ọ̀dọ̀ rẹ̀ laó wà láéláé.
2. Dúró ṣinṣin sáwọn ará.
Má kúrò nígbà ’ṣòro.
Ká tọ́jú wọn, gbẹ́kẹ̀ lé wọn,
Onínúure ni ká jẹ́.
Ká máa bọlá fáwọn ará,
Bọ̀wọ̀ fún wọn látọkàn.
Kí Bíbélì sọ wá dọ̀kan;
Ọ̀dọ̀ wọn laó wà láéláé.
3. Dúró ṣinṣin, gbọ́ ìtọ́ni
Àwọn tó ńmúpò ’wájú.
Tí wọ́n bá fún wa nímọ̀ràn,
Ká tẹ̀ lée tọkàntọkàn.
Aó rí ìbùkún Jèhófà,
Aó sì di alágbára.
Táa bá dúró ṣinṣin láìyẹ̀,
Aó jẹ́ ti Jèhófà láé.
(Tún wo Sm. 149:1; 1 Tím. 2:8; Héb. 13:17.)