Orin 58
Àdúrà Ìyàsímímọ́ Mi
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Gba ọkàn mi, jẹ́ kó fẹ́
Òótọ́ òun ọgbọ́n tọ̀run.
Gbàrònú mi, Jèhófà,
Kí nlè sìn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́.
2. Gba ọwọ́ àtẹsẹ̀ mi;
Kí wọ́n máa ṣohun tóo fẹ́.
Gba ohùn mi jẹ́ kó máa
Kọrin ìyìn sọ́ba mi.
3. Gba ayé mi Ọlọ́run,
Mú kó bá ìfẹ́ rẹ mu.
Gba èmi gan-an kíwà mi
Lè máa wù ọ́ Olúwa.
(Tún wo Sm. 40:8; Jòh. 8:29; 2 Kọ́r. 10:5.)