ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | Ẹ́KÍSÓDÙ 15-16
Máa Fi Orin Yin Jèhófà
Orin máa ń tuni lára, ó sì lè nípa lórí wa gan-an. Orin jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà.
Mósè àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọrin ìyìn sí Jèhófà nígbà tó gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́nà ìyanu ní Òkun Pupa
Ọba Dáfídì ṣètò ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin láti máa kọrin ní tẹ́ńpìlì
Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú Jésù, òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ kọrin ìyìn sí Jèhófà
Àwọn ìgbà wo ni mo lè kọrin ìyìn sí Jèhófà?