Orin 65
“Èyí Ni Ọ̀nà”
1. Ọ̀nà ayọ̀ kan wà,
Ọ̀nà tóo ti kọ́ ni.
Ọ̀nà tóo ti mọ̀ ni,
Ọ̀nà tó ti pẹ́ ni,
Ọ̀nà tí Jésù kọ́ọ
Nígbà tóo gbóhùn rẹ̀.
Èyí lọ̀nà ayọ̀,
Táa rí ń’nú Bíbélì.
(ÈGBÈ)
Èyí ni Ọ̀nà náà, Ọ̀nà ìyè.
Má yà bàrá; Má ṣe wọ̀tún wòsì!
Ọlọ́run ńwí pé: ‘Èyí lọ̀nà.
Má ṣe wẹ̀yìn, torí Èyí lọ̀nà.’
2. Ọ̀nà ìfẹ́ kan wà,
Má ṣe dààmú kiri.
Jáà ti fi wá mọ̀nà;
Ó fara rẹ̀ hàn wá.
Ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ púpọ̀;
Ìfẹ́ tòótọ́ sì ni.
Èyí lọ̀nà ìfẹ́;
Ó sì ńhàn láyé wa.
(ÈGBÈ)
Èyí ni Ọ̀nà náà, Ọ̀nà ìyè.
Má yà bàrá; Má ṣe wọ̀tún wòsì!
Ọlọ́run ńwí pé: ‘Èyí lọ̀nà.
Má ṣe wẹ̀yìn, torí Èyí lọ̀nà.’
3. Ọ̀nà ìyè kan wà,
Má ṣe bojú wẹ̀yìn.
Ọlọ́run ti sọ pé:
Kò sọ́nà rere míì,
Kò sọ́nà ayọ̀ míì,
Kò sọ́nà ìfẹ́ míì.
Èyí lọ̀nà ìyè,
Ọpẹ́ yẹ Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Èyí ni Ọ̀nà náà, Ọ̀nà ìyè.
Má yà bàrá; Má ṣe wọ̀tún wòsì!
Ọlọ́run ńwí pé: ‘Èyí lọ̀nà.
Má ṣe wẹ̀yìn, torí Èyí lọ̀nà.’