Orin 48
Bíbá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
(Míkà 6:8)
1. Baba wa ló ńfà wá lọ́wọ́,
A sì ńfi ìrẹ̀lẹ̀ bá a rìn.
Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí
Tó fáwọn tó ńwá ọ̀nà rẹ̀ pọ̀!
Ọlọ́run ti ṣètò fún wa
Ká bàa lè dìí lọ́wọ́ mú.
A ti yara wa sí mímọ́;
A dúró sọ́dọ̀ Jèhófà.
2. Bí òpin ti ńsún mọ́lé yìí,
Tí ìdájọ́ ayé ńlọ lọ́wọ́,
Àtakò tó ńdojú kọ wá
Lè fẹ́ mú kí ẹ̀rù máa bà wá.
Jèhófà ló ńdáàbò bò wá;
Ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ la fẹ́ máa wà
Ká bàa lè máa sìnín títí láé.
Ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká dúró gbọn-in.
3. Ọlọ́run ńpèsè ìrànwọ́
Nípa ẹ̀mí àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀,
Nípa ìjọ Kristẹni rẹ̀,
Nípa àdúrà wa tó ń gbọ́.
Báa sì ṣe ńbá Jèhófà rìn,
Yóò jẹ́ ká ṣohun tó tọ́,
Yóò jẹ́ ká ní inú rere,
Aó fi ìrẹ̀lẹ̀ bá a rìn.
(Tún wo Jẹ́n. 5:24; 6:9; 1 Ọba 2:3, 4.)