ORÍ 14
Ìjọba Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo Là Ń Tì Lẹ́yìn
1, 2. (a) Ìlànà wo ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń tẹ̀ lé títí di òní? (b) Báwo ni àwọn ọ̀tá ṣe gbìyànjú láti borí wa? Ibo lọ̀rọ̀ já sí?
NÍGBÀ tí Jésù wà níwájú Pílátù, tó jẹ́ adájọ́ tó láṣẹ jù lọ láàárín àwọn Júù, ó sọ ìlànà kan tí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ń tẹ̀ lé títí di òní. Ó ní: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòh. 18:36) Pílátù ní kí wọ́n pa Jésù, àmọ́ ayọ̀ wọn lórí ikú Jésù kò tọ́jọ́ torí pé Ọlọ́run jí Jésù dìde. Àwọn Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù tó jẹ́ alágbára gbìyànjú láti rẹ́yìn àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí. Àwọn Kristẹni polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ayé ìgbàanì.—Kól. 1:23.
2 Lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ní ọdún 1914, àwọn kan lára ẹgbẹ́ ológun tó lágbára jù lọ nínú ìtàn gbìyànjú láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Ṣùgbọ́n kò sí ìkankan lára wọn tó borí wa. Ọ̀pọ̀ ìjọba àti ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń fẹ́ fipá mú wa láti gbè sẹ́yìn wọn nígbà rògbòdìyàn. Àmọ́ kò ṣeé ṣe fún wọn láti pín wa níyà. Lóde òní, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwa ọmọ Ìjọba Ọlọ́run wà. Síbẹ̀, a wà níṣọ̀kan torí a jẹ́ ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé, a kì í sì í dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. Bí a ṣe wà ní ìṣọ̀kan jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso àti pé Jésù Kristi tó jẹ́ Ọba ṣì ń darí àwọn tó wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀, ó ń ṣàtúnṣe tó yẹ, ó sì ń dáàbò bò wọ́n. Jẹ́ ká wo ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀, ká sì wo díẹ̀ lára àwọn ẹjọ́ tó mú ká jàre rẹ̀ tó sì ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, bí a ti ń bá a nìṣó láti ‘má ṣe jẹ́ apá kan ayé.’—Jòh. 17:14.
Ọ̀rọ̀ Pàtàkì Kan Jẹ Yọ
3, 4. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso? (b) Ṣé gbogbo nǹkan tó rọ̀ mọ́ bó ṣe yẹ ká ta kété sí ogun àti òṣèlú ló yé àwọn èèyàn Ọlọ́run níbẹ̀rẹ̀? Ṣàlàyé.
3 Ogun kan wáyé ní ọ̀run lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso, wọ́n sì ju Sátánì sísàlẹ̀ sórí ilẹ̀ ayé. (Ka Ìṣípayá 12:7-10, 12.) Ogun míì tún bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó sì dán ìṣòtítọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run wò. Síbẹ̀, wọ́n pinnu láti má ṣe jẹ́ apá kan ayé ní àfarawé Jésù. Àmọ́ níbẹ̀rẹ̀, òye wọn kò kún rẹ́rẹ́ tó nípa gbogbo ohun tó rọ̀ mọ́ bó ṣe yẹ kí wọ́n ta kété sí ogun àti òṣèlú.
4 Bí àpẹẹrẹ, ìwé Millennial Dawn Apá Kẹfà,a tí a tẹ̀ jáde ní ọdún 1904, gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n má ṣe lọ́wọ́ sí ogun. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé tí wọ́n bá fipá mú Kristẹni kan láti wọṣẹ́ ológun, kó rí i pé iṣẹ́ tí kò ní mú kó lo ohun ìjà ló ń ṣe. Tí ìyẹn kò bá ṣeé ṣe, tí wọ́n sì rán an lọ sójú ogun, kó rí i pé òun kò pa èèyàn. Arákùnrin Herbert Senior tó ń gbé nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, tó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1905 sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà yẹn, ó ní: “Ohun tó yẹ kí àwọn ará ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí kò yé wọn rárá, kò sì sí ìtọ́ni tó ṣe gúnmọ́ nípa bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́ láti bá àwọn ológun ṣiṣẹ́ láìgbé ohun ìjà.”
5. Báwo ni Ilé Ìṣọ́ September 1, 1915, ṣe mú kí ohun tó yẹ ká ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere?
5 Àmọ́ ohun tí Ilé Ìṣọ́ September 1, 1915 lédè Gẹ̀ẹ́sì sọ mú kí ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kedere. Ó sọ nípa àbá inú ìwé Studies in the Scriptures pé: “A wò ó pé àfàìmọ̀ ni ẹni tó bá ń bá àwọn ológun ṣiṣẹ́ àmọ́ tí kò gbé ohun ìjà kò ní ṣe ohun tó ta ko ìlànà tó yẹ kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ lé.” Tó bá wá jẹ́ pé ṣe ni wọ́n fi ìbọn halẹ̀ mọ́ Kristẹni kan pé ó gbọ́dọ̀ bá wọn ja ogun tàbí pé kó wọ aṣọ ọmọ ogun ńkọ́? Àpilẹ̀kọ náà ṣàlàyé pé: “Ǹjẹ́ kò ní dára jù tí wọ́n bá pa ẹnì kan torí pé ó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọmọ Aládé Àlàáfíà tí kò sì fẹ́ ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó pa dípò kí wọ́n pa á níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ fún àwọn ọba ayé yìí, tó sì ń tì wọ́n lẹ́yìn, tó wà láàárín wọn tí kò sì tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Ọba wa ọ̀run? Ó tẹ́ wa lọ́rùn kí wọ́n pa wá torí pé a jẹ́ olóòótọ́ sí Ọba wa Ọ̀run dípò ká kú sẹ́nu iṣẹ́ àwọn ọba ayé yìí.” Láìka bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe rinlẹ̀ sí, àpilẹ̀kọ náà sọ ní ìparí pé: “A kò kàn án nípá fún ẹnikẹ́ni láti ṣe ohun tá a sọ yìí. Ṣe la wulẹ̀ ń dábàá rẹ̀.”
6. Kí lo rí kọ́ lára Arákùnrin Herbert Senior?
6 Ọ̀rọ̀ yẹn yé àwọn ará kan kedere, wọ́n sì pinnu pé ohun tó bá gbà làwọ́n máa fún un. Arákùnrin Herbert Senior, tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níṣàájú sọ pé: “Lójú tèmi, ojú kan náà ló yẹ ká fi wo kẹ́nì kan máa bá wọn já ohun ìjà ogun sílẹ̀ látinú ọkọ̀ [iṣẹ́ tó yàtọ̀ sí ogun jíjà] àti kó máa bá wọn ki ìbọn tí wọn máa yìn lójú ogun.” (Lúùkù 16:10) Wọ́n rán Arákùnrin Senior lẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò jẹ́ kó wọṣẹ́ ológun. Òun àti arákùnrin mẹ́rin míì wà lára àwọn mẹ́rìndínlógún [16] tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Àwọn míì tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára wọn. Wọ́n fi wọ́n sí ẹ̀wọ̀n Richmond nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ wọ́n sí Richmond 16 nígbà tó yá. Ìgbà kan wà tí wọ́n fi ọkọ̀ òkun gbé Arákùnrin Herbert àtàwọn míì bíi tiẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́ lọ sí ibi tí ogun ti le gan-an nílẹ̀ Faransé. Ibẹ̀ ni wọ́n ti dájọ́ pé kí wọ́n lọ yìnbọn pa wọ́n. Nígbà tí wọ́n ti wà lórí ìlà, tó kù díẹ̀ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn sí wọn, wọ́n bá yí ìdájọ́ náà pa dà. Wọ́n ní kí wọ́n lọ ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá.
“Mo wá rí i pé ó yẹ kí àlàáfíà wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run àti gbogbo èèyàn, kódà nígbà ogun.” —Simon Kraker (Wo ìpínrọ̀ 7)
7. Kí ló ti wá ṣe kedere sí àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi máa bẹ̀rẹ̀?
7 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì fi máa bẹ̀rẹ̀, ó ti wá ṣe kedere sí àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ pé kò yẹ kí wọ́n lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ológun lọ́nàkọnà, wọ́n sì wá mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Mát. 26:51-53; Jòh. 17:14-16; 1 Pét. 2:21) Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ kan tó ṣe kókó jáde nínú Ilé Ìṣọ́ November 1, 1939 tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Àìdá-sí-tọ̀túntòsì.” Ó sọ pé: “Òfin tó yẹ kí àwa èèyàn Jèhófà máa tẹ̀ lé báyìí ni pé ká má ṣe gbè sẹ́yìn èyíkéyìí lára àwọn orílẹ̀-èdè tó ń bára wọn jagun lọ́nàkọnà.” Arákùnrin Simon Kraker, tó wá ṣiṣẹ́ nígbà tó yá ní orílé-iṣẹ́ wa nílùú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York sọ nípa àpilẹ̀kọ yẹn pé: “Mo wá rí i pé ó yẹ kí àlàáfíà wà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run àti gbogbo èèyàn, kódà nígbà ogun.” Oúnjẹ tẹ̀mí yẹn bọ́ sí àkókò tó yẹ, ó sì ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún inúnibíni tírú rẹ̀ kò tíì wáyé rí, tó máa dán ìṣòtítọ́ wọn sí Ìjọba Ọlọ́run wò.
Sátánì fi “Odò” Ìṣàpẹẹrẹ Halẹ̀
8, 9. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ àpọ́sítélì Jòhánù ṣe ṣẹ?
8 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn tí Ìjọba Ọlọ́run bá bẹ̀rẹ̀ àkóso ní 1914, Sátánì Èṣù tó jẹ́ dírágónì náà máa gbìyànjú láti pa àwọn alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run rẹ́, ní ti pé ó máa pọ odò ìṣàpẹẹrẹ jáde láti ẹnu rẹ̀.b (Ka Ìṣípayá 12:9, 15.) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jòhánù yìí ṣe ṣẹ? Láti ọdún 1920, àwọn ọ̀tá ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ inúnibíni sí àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ní Amẹ́ríkà ti àríwá, wọ́n fi Arákùnrin Kraker sẹ́wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì torí pé ó fi tọkàntọkàn rọ̀ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Kódà, nígbà ogun náà, ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn tó wà lẹ́wọ̀n ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun ló jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
9 Sátánì àtàwọn alátìlẹyìn rẹ̀ ń sa gbogbo ipá wọn láti mú kí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run di aláìṣòótọ́ láìka ibi tí wọ́n ń gbé sí. Ní gbogbo ilẹ̀ Áfíríkà, Yúróòpù àti Amẹ́ríkà, wọ́n gbé wọn lọ sílé ẹjọ́ àti sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń dá ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀. Torí wọ́n rọ̀ mọ́ ìpinnu wọn pé àwọn kò ní wọṣẹ́ ológun, wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n lù wọ́n, wọ́n sì sọ àwọn kan di aláàbọ̀ ara. Lórílẹ̀-èdè Jámánì, wọ́n fúngun mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run gan-an torí pé wọn ò kókìkí Hitler, wọn ò sì lọ́wọ́ sí ogun. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ni wọ́n fi sí ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà ìjọba Násì. Ó lé ní ẹgbẹ̀jọ [1,600] Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó kú lọ́wọ́ àwọn tó ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́. Síbẹ̀, gbogbo ìpalára tí Èṣù bá ṣe fún àwọn èèyàn Ọlọ́run kò lè wà títí ayérayé.—Máàkù 8:34, 35.
“Ilẹ̀ Ayé” Gbé “Odò Náà” Mì
10. Kí ni “ilẹ̀ ayé” ṣàpẹẹrẹ? Báwo ló sì ṣe ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́?
10 Àsọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ jẹ́ ká mọ̀ pé “ilẹ̀ ayé,” tó ṣàpẹẹrẹ àwọn tó jẹ́ ara ètò àwọn nǹkan yìí àmọ́ tí wọ́n ń fòye báni lò, máa gbé inúnibíni tó dà bí “odò náà” mì, á sì tipa bẹ́ẹ̀ ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́. Báwo ni apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe ṣẹ? Láwọn ọdún tó tẹ̀ lé Ogun Àgbáyé Kejì, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí pè ní “ilẹ̀ ayé” dá sọ́rọ̀ àwọn tó ń fi tọkàntọkàn ti Ìjọba Mèsáyà lẹ́yìn. (Ka Ìṣípayá 12:16.) Bí àpẹẹrẹ, onírúurú ilé ẹjọ́ tó láṣẹ ti gbèjà ẹ̀tọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní láti má ṣe wọ iṣẹ́ ológun ká sì yẹra fún àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ẹjọ́ mánigbàgbé tó dá lórí ọ̀rọ̀ wíwọ iṣẹ́ ológun, èyí tí Jèhófà ti jẹ́ ká jàre rẹ̀.—Sm. 68:20.
11, 12. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Sicurella àti Arákùnrin Thlimmenos? Ibo lọ̀rọ̀ wọn já sí?
11 Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí Anthony Sicurella, ọmọ mẹ́fà sì ni wọ́n bí. Ó ṣèrìbọmi lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15]. Nígbà tó pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21], ó forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ tó ń gbani síṣẹ́ ológun pé ajíhìnrere ni òun. Nígbà tó di ọdún 1950, ìyẹn ọdún méjì lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé sí ìgbìmọ̀ náà pé kí wọ́n kọ orúkọ òun mọ́ tàwọn tí ẹ̀rí ọkàn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ́fíìsì Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ìjọba Àpapọ̀ fara mọ́ ọn, Ọ́fíìsì Ìjọba Tó Ń Rí Sí Ọ̀rọ̀ Ìdájọ́ kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọlé. Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò léraléra, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà gbọ́ ẹjọ́ Arákùnrin Sicurella, wọ́n dá a láre, wọ́n sì fagi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ tó kọ́kọ́ gbọ́ ẹjọ́ náà ṣe. Ìdájọ́ yìí ti di àwòfiṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n bá ń gbé ọ̀rọ̀ àwọn míì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà yẹ̀ wò lórí pé ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun.
12 Orílẹ̀-Èdè Gíríìsì. Ní ọdún 1983, wọ́n dá Iakovos Thlimmenos lẹ́bi lórí ẹ̀sùn pé ó kọ̀ láti wọ aṣọ ológun, wọ́n sì fi sẹ́wọ̀n. Lẹ́yìn tí wọ́n tú u sílẹ̀, ó fẹ́ máa ṣiṣẹ́ ìṣirò owó, àmọ́ wọn kò gbà á síṣẹ́ torí pé ó ti ṣẹ̀wọ̀n rí. Ó gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí ilé ẹjọ́. Àmọ́ lẹ́yìn tí àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Gíríìsì dá a lẹ́bi, ó gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ní ọdún 2000, àwọn adájọ́ mẹ́tàdínlógún [17] tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá a láre, ìdájọ́ yìí sì wá di àwòfiṣàpẹẹrẹ nígbà tí wọ́n bá ń gbé irú ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. Kí wọ́n tó dá ẹjọ́ yìí, àwọn ará tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] ni àkọsílẹ̀ fi hàn pé wọ́n ti ṣẹ̀wọ̀n rí torí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ dá wa láre, ìjọba ilẹ̀ Gíríìsì ṣe òfin kan tó mú kí wọ́n wọ́gi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn arákùnrin yìí. Bákan náà, wọ́n tún fìdí òfin tó fàyè gba gbogbo ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun múlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ṣàtúnṣe Òfin Ilẹ̀ Gíríìsì.
“Kí n tó wọ ilé ẹjọ́, mo máa ń gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà, mo sì máa ń rí i pé ó jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.” —Ivailo Stefanov (Wo ìpínrọ̀ 13)
13, 14. Ẹ̀kọ́ wo lo rò pé a lè rí kọ́ nínú ẹjọ́ Arákùnrin Stefanov àti ti Bayatyan?
13 Orílẹ̀-Èdè Bulgaria. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] ni Ivailo Stefanov lọ́dún 1994 nígbà tí wọ́n ní kó wá wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ ó kọ̀, kò sì bá wọn ṣe iṣẹ́ tí kò jẹ́ mọ ogun jíjà lọ́dọ̀ àwọn ológun. Wọ́n bá rán an ní ẹ̀wọ̀n ọdún kan ààbọ̀. Ó lo ẹ̀tọ́ tó ní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Nígbà tó yá, ẹjọ́ rẹ̀ dé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù. Ṣùgbọ́n lọ́dún 2001, kó tó di pé ilé ẹjọ́ náà gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, àwọn tó fẹ̀sùn kan Arákùnrin Stefanov yanjú ọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Ìjọba orílẹ̀-èdè Bulgaria sì mú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan arákùnrin náà kúrò, èyí mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ náà láti yan iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun.c
14 Orílẹ̀-Èdè Àméníà. Ọdún 2001 ni ọjọ́ orí Vahan Bayatyan pé ti àwọn tí ìjọba lè fi dandan pè wá ṣiṣẹ́ ológun.d Ó sọ fún wọn pé òun kò ní lè ṣiṣẹ́ náà, àmọ́ ṣe ni wọ́n dá a lẹ́bi ní gbogbo ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Àméníà tó gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní September ọdún 2002, wọ́n rán an lẹ́wọ̀n ọdún méjì ààbọ̀, àmọ́ wọ́n dá a sílẹ̀ lẹ́yìn tó lo oṣù mẹ́wàá àtààbọ̀ lẹ́wọ̀n. Láàárín àkókò yìí, ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù, wọ́n sì gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Àmọ́ ní October 27, 2009, ilé ẹjọ́ yìí tún dá Arákùnrin Bayatyan lẹ́bi. Ibi tọ́rọ̀ yìí já sí dun àwọn ará wa tó ní irú ìṣòro kan náà lórílẹ̀-èdè Àméníà gan-an. Àmọ́ ṣá o, Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní ilé ẹjọ́ náà tún ẹjọ́ rẹ̀ gbọ́. Ní July 7, 2011, wọ́n dá Vahan Bayatyan láre. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù fara mọ́ ọn pé kí wọ́n yọ̀ǹda àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Ìdí ni pé wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti sọ èrò wọn, láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn gbà láyè àti láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n. Kì í ṣe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni ìdájọ́ yìí wúlò fún, ó tún máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Yúróòpù lè máa lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní.e
Wọ́n dá àwọn arákùnrin tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀ lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá wọn láre
Àwọn Ayẹyẹ Tó Ń Gbé Ìfẹ́ Orílẹ̀-Èdè Ẹni Lárugẹ
15. Kí nìdí táwa èèyàn Jèhófà fi máa ń yẹra fún àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ?
15 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe iṣẹ́ ológún, a sì máa ń fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ yẹra fún àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ torí pé tọkàntọkàn la fi rọ̀ mọ́ Ìjọba Mèsáyà. Ní pàtàkì, látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti túbọ̀ gbilẹ̀ káàkiri ayé. Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa ń ní kí àwọn ọmọ ìlú wọn ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè, kí wọ́n kọ orin orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n kí àsíá láti fi jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn máa jẹ́ olóòótọ́ sí ilẹ̀ baba wọn. Àmọ́ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni à ń sìn. (Ẹ́kís. 20:4, 5) Èyí sì ti mú kí wọ́n ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ inúnibíni sí wa. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà ti lo “ilẹ̀ ayé” láti gbé àwọn kan lára àtakò tó dà bí odò náà mì. Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára irú àwọn ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà ti mú ká jàre rẹ̀ nípasẹ̀ Jésù.—Sm. 3:8.
16, 17. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Lillian àti William àbúrò rẹ̀? Kí lo rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn?
16 Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lọ́dún 1940, adájọ́ mẹ́jọ nínú mẹ́sàn-án tó gbọ́ ẹjọ́ tó wáyé láàárín Minersville School District àti Gobitis ní Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi. Torí pé tọkàntọkàn ni Lillian Gobitas,f tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá àti William, àbúrò rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá fi ń sin Jèhófà, wọ́n kọ̀ láti kí àsíá, wọn kò sì ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè. Tórí náà, wọ́n lé wọn kúrò ní iléèwé. Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, ilé ẹjọ́ náà fara mọ́ ohun tí àwọn aláṣẹ iléèwé náà ṣe pé ó bófin mu torí pé “ìṣọ̀kan orílẹ̀-èdè” ni wọ́n ń jà fún. Ìdájọ́ yìí mú kí inúnibíni tó le koko bẹ̀rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n tún lé kúrò níléèwé, wọ́n sì lé àwọn tó jẹ́ àgbàlagbà kúrò níbi iṣẹ́, àwọn èèyàn tún dáwọ́ jọ lu àwọn míì lára wọn. Ìwé kan tó ń jẹ́ The Lustre of Our Country sọ pé “inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún 1941 sí 1943 ni ẹ̀tanú tó le jù táwọn èèyàn ti ṣe sáwọn ẹlẹ́sìn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1901 sí 2000.”
17 Ayọ̀ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí kò tọ́jọ́ rárá. Lọ́dún 1943, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ míì tó fara jọ ti Gobitis. Èyí tó wáyé láàárín ọ́fíìsì ìjọba tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́, ìyẹn West Virginia State Board of Education àti Barnette. Lọ́tẹ̀ yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ilé ẹjọ́ dá láre. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí nínú ìtàn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti orílẹ̀-èdè náà máa yí ìdájọ́ tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ pa dà láàárín àkókò kúkúrú. Lẹ́yìn ìdájọ́ yìí, inúnibíni tó hàn sójútáyé tí wọ́n ń ṣe sáwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wá rọlẹ̀ gan-an. Èyí mú kí gbogbo ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lè túbọ̀ máa lo ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin.
18, 19. Kí ni Pablo Barros sọ pé ó ran òun lọ́wọ́ láti dúró lórí ìpinnu òun? Báwo ni àwa ìránṣẹ́ Jèhófà tó kù ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
18 Orílẹ̀-Èdè Ajẹntínà. Wọ́n lé tẹ̀gbọ́ntàbúrò kan tó ń jẹ Pablo àti Hugo Barros nílé ìwé ní ọdún 1976 torí pé wọn kò bá wọn lọ́wọ́ sí ayẹyẹ kan tó gba pé kí wọ́n gbé àsíá. Ọmọ ọdún méje ni Hugo, Pablo sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá ilé ìwé wọn ti Pablo dà nù, ó sì gbá a ní orí. Ó tún dá àwọn méjèèjì dúró lẹ́yìn ilé ìwé fún wákàtí kan gbáko, ó ń fúngun mọ́ wọn kí wọ́n lè lọ́wọ́ sí àwọn ayẹyẹ tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ. Nígbà tí Pablo ń sọ bọ́rọ̀ yẹn ṣe ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ká ní kì í ṣe pé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ ni, mi ò bá ti bọ́hùn nígbà yẹn.”
19 Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí dé ilé ẹjọ́, adájọ́ fara mọ́ bí wọ́n ṣe lé Pablo àti Hugo kúrò níléèwé. Àmọ́, wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ti Orílẹ̀-Èdè Ajẹntínà. Ní ọdún 1979, Ilé Ẹjọ́ yìí wọ́gi lé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ ṣe, ó ní: “Ìyà tí wọ́n fi jẹ àwọn ọmọ yìí [ìyẹn bí wọ́n ṣe lé wọn kúrò níléèwé] kò bá ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní láti kẹ́kọ̀ọ́ mú (nínú Abala 14 ìwé òfin), ó sì tún ta ko ojúṣe tí ìjọba ní láti rí i pé àwọn ọmọ ka ìwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ (bó ṣe wà nínú Abala 5 nínú ìwé òfin).” Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún [1,000] ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jàǹfààní bí wọ́n ṣe dá wa láre yìí. Wọ́n gba àwọn kan lára wọn pa dà sí iléèwé, àwọn míì bíi Pablo àti Hugo sì láǹfààní láti pa dà sí ilé ìwé ìjọba.
Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ni kò yẹsẹ̀ lójú àdánwò
20, 21. Báwo ni ẹjọ́ Roel Embralinag àti Emily ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ṣe mú kí ìgbàgbọ́ rẹ túbọ̀ lágbára?
20 Orílẹ̀-Èdè Philippines. Lọ́dún 1990, wọ́n lé Roel Embralinag,g tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-àn àti Emily, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá, pẹ̀lú àwọn bíi mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] míì tó jẹ́ ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò níléèwé torí pé wọn kò kí àsíá. Leonardo, tó jẹ́ bàbá wọn lọ bá àwọn ọ̀gá ilé ìwé náà sọ̀rọ̀, àmọ́ wọn kò gba àwọn ọmọ náà pa dà. Nígbà tí ọ̀rọ̀ yẹn le gan-an, Leonardo gbé ẹjọ́ náà lọ sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ. Àmọ́ Leonardo kò ní owó tó máa fi gba agbẹjọ́rò tó máa ṣojú fún un. Ìdílé rẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà gan-an lórí ọ̀rọ̀ yìí kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. Ní gbogbo àkókò yìí, àwọn èèyàn ń kẹ́gàn àwọn ọmọ rẹ̀, wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Lójú Leonardo, ó wò ó pé bóyá lòun máa lè jàre ẹjọ́ yìí torí kò mọ nǹkan kan nípa bí wọ́n ṣe ń rojọ́ nílé ẹjọ́.
21 Bọ́rọ̀ yìí ṣe wá rí nígbà tó yá ni pé Arákùnrin Felino Ganal, tó jẹ́ agbẹjọ́rò tó ń ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ ní ilé iṣẹ́ agbẹjọ́rò kan táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó lórílẹ̀-èdè náà ló wá ṣojú ìdílé yìí nílé ẹjọ́. Lásìkò ìgbẹ́jọ́ yìí, Arákùnrin Ganal ti kúrò ní ilé iṣẹ́ náà, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ gbọ́ ẹjọ́ yìí, ó dá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre, ó sì wọ́gi lé àṣẹ tí wọ́n fi lé àwọn ọmọ náà kúrò níléèwé. Bí ìsapá àwọn tó fẹ́ káwọn èèyàn Ọlọ́run di aláìṣòótọ́ tún ṣe já sí pàbó nìyẹn.
Bí A Kò Ṣe Lọ́wọ́ sí Ogun àti Òṣèlú Ń Jẹ́ Ká Lè Wà Níṣọ̀kan
22, 23. (a) Kí ló jẹ́ ká lè jàre ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tó jẹ́ mánigbàgbé? (b) Kí ni ẹgbẹ́ ará wa tó wà ní àlàáfíà kárí ayé ń fi hàn?
22 Kí ló jẹ́ kí àwa èèyàn Jèhófà lè jàre ọ̀pọ̀ ẹjọ́ tó jẹ́ mánigbàgbé? A ò ní àwọn olóṣèlú tó ń tì wá lẹ́yìn. Síbẹ̀, ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan ilé ẹjọ́, àwọn adájọ́ tí kò ṣe ojúsàájú ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣàtakò tó le koko, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ìlànà lélẹ̀ fún àwọn amòfin tó bá fẹ́ yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó dá wa lójú gbangba pé, Kristi ló ń tì wá lẹ́yìn ká lè jàre àwọn ẹjọ́ yìí. (Ka Ìṣípayá 6:2.) Kí nìdí tá a fi ń gbé ọ̀rọ̀ lọ sílé ẹjọ́? Kì í ṣe pé a fẹ́ yí ètò òfin táwọn èèyàn ń tẹ̀ lé pa dà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí à ń fẹ́ ni pé ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn fún Jésù Kristi, tó jẹ́ Ọba wa, láìsí ìdíwọ́ kankan.—Ìṣe 4:29.
23 Nínú ayé tí rògbòdìyàn òṣèlú ti ń pín àwọn èèyàn níyà, tí wọ́n sì túbọ̀ ń kórìíra ẹlòmíì tìkà tẹ̀gbin, Jésù Kristi, Ọba wa tó ń ṣàkóso ti bù kún ìsapá àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kárí ayé láti má ṣe lọ́wọ́ sí ogun àti òṣèlú. Gbogbo ìsapá Sátánì láti pín wa níyà kó lè rẹ́yìn wa ló ti já sí pàbó. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí kò “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́” ló ń wá sábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ti pé a wà lára ẹgbẹ́ ará wa kárí ayé tó wà ní àlàáfíà jẹ́ iṣẹ́ ìyanu, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso!—Aísá. 2:4.
a Wọ́n tún máa ń pe apá yìí ní The New Creation. Àmọ́ Studies in the Scriptures ni wọ́n wá ń pe àpapọ̀ ìwé Millennial Dawn nígbà tó yá.
b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé Ìṣípayá—Ìparí Rẹ̀ Ológo Kù sí Dẹ̀dẹ̀!, orí 27, ojú ìwé 184 sí 186.
c Ara ọ̀nà tí wọ́n gbà yanjú ọ̀rọ̀ náà ni pé ìjọba orílẹ̀-èdè Bulgaria ní láti gba gbogbo àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun láyè láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú tí kò sí lábẹ́ àwọn ológun.
d Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo European Court Upholds the Right to Conscientious ObjectionIlé Ìṣọ́ November 1, 2012, ojú ìwé 29 sí 31.
e Ó ju àádọ́ta lé nírínwó [450] ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ìjọba ilẹ̀ Àméníà ti fi sẹ́wọ̀n láàárín ogún ọdún. Wọ́n fi ẹni tó kẹ́yìn lára wọn sílẹ̀ ní oṣù November 2013.
f Wọ́n ṣi orúkọ yìí kọ nínú àkọsílẹ̀ ilé ẹjọ́, Gobitis ni wọ́n pè é dípò Gobitas.
g Wọ́n ṣi orúkọ yìí kọ sílẹ̀ ní ilé ẹjọ́, Ebralinag ni wọ́n pè é dípò Embralinag.