Orin 52
Máa Ṣọ́ Ọkàn Rẹ
Bíi Ti Orí Ìwé
(Òwe 4:23)
1. Ṣọ́ ọkàn rẹ, ìwọ yóò yè;
Ta kété sí ẹ̀ṣẹ̀.
Ọlọ́run ńrínú ọkàn wa,
Ó mẹni táa jẹ́ gan-an.
Ọkàn wa ńtàn wá nígbà míì,
Ó lè ṣì wá lọ́nà.
Máa ṣọ́ ohun tọ́kàn rẹ ńrò,
Sì dúró lọ́nà Jáà.
2. Fi ọkàn rẹ wá Ọlọ́run
Nípasẹ̀ àdúrà.
Máa fìyìn fúnun nígbà gbogbo;
Sọ ohun tóo fẹ́ fúnun.
Ohun tí Jèhófà ńkọ́ wa
Lohun tó yẹ ká ṣe.
Máa dúró ṣinṣin lọ́kàn rẹ,
Kóo máa múnú rẹ̀ dùn.
3. Kọ́kàn rẹ má ṣe ro ibi;
Ire ni kóo máa rò.
Kọ́rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ọ́ lọ́kàn,
Kó fún ọ lágbára.
Ó dájú, Jèhófà fẹ́ràn
Adúróṣinṣin rẹ̀.
Máa sìnín pẹ̀lú gbogbo ọkàn
Bí ọ̀rẹ́ títí láé.
(Tún wo Sm. 34:1; Fílí. 4:8; 1 Pét. 3:4.)