Ẹ̀KỌ́ 29
Ìró Ohùn
OHUN tí a ń sọ nìkan kọ́ ló ń nípa lórí àwọn èèyàn, ọ̀nà tí a gbà sọ ọ́ ń nípa lórí wọn pẹ̀lú. Bí ẹnì kan bá ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ tó tura bá ọ sọ̀rọ̀, tó sì sọ̀rọ̀ lọ́nà ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ àti ti onínúure, ǹjẹ́ o kò ní fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ju ìgbà tí ọ̀yàyà kò hàn nínú ohùn onítọ̀hún tàbí tí ohùn rẹ̀ bá le?
Dídi ẹni tí ohùn rẹ̀ fa àwọn èèyàn mọ́ra kò sinmi lórí kíkọ́ nípa bí ohùn ṣe ń dún jáde àti bí a ṣe lè lò ó nìkan. Ó tún kan irú ìwà tí onítọ̀hún ní pẹ̀lú. Bí èèyàn ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì àti nínú bí ó ṣe ń fi í sílò, àyípadà rẹ̀ yóò máa hàn kedere nínú ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ayọ̀ àti inú rere á máa hàn nínú ohùn rẹ̀. (Gál. 5:22, 23) Bí ohun tó ṣe ọmọnìkejì rẹ̀ bá ká a lára ní ti gidi, á hàn nínú ohùn rẹ̀. Bí ẹ̀mí ìmoore bá ti rọ́pò ẹ̀mí ìráhùn, á hàn nínú ọ̀rọ̀ tí a sọ àti ohùn tí a fi sọ ọ́. (Ìdárò 3:39-42; 1 Tím. 1:12; Júúdà 16) Kódà bí o kò bá tiẹ̀ gbọ́ èdè tí àwọn kan ń sọ, bí ọ̀kan nínú àwọn tó ń sọ ọ́ bá ń fọ́nnu, tó ń kanra, tó ń ṣàríwísí, tó sì ń sọ̀rọ̀ líle, ṣùgbọ́n tí òmíràn ń fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ̀rọ̀, tó ń sọ ọ́ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lọ́nà onínúure àti onífẹ̀ẹ́, kò ní ṣòro fún ọ láti mọ ìyàtọ̀ nínú ohùn àwọn méjèèjì.
Nígbà mìíràn, àìsàn lè ba gògòńgò ẹnì kan jẹ́ tí onítọ̀hún kò fi ní lóhùn tó jọ̀lọ̀ mọ́, àbùkù inú ara tí èèyàn jogún sì lè fà á kí ohùn ẹni má jọ̀lọ̀. Irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀ lè burú débi pé àtúnṣe pátápátá kò ní sí láyé eléyìí tá a wà yìí. Àmọ́, ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé béèyàn bá kọ́ bí a ṣe ń lo àwọn ẹ̀yà ara ọ̀rọ̀ sísọ bó ṣe tọ́, ohùn rẹ̀ lè sunwọ̀n sí i.
Àmọ́ lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé bí ohùn kálukú ṣe rí yàtọ̀ síra. Kò yẹ kí o máa lépa bí wàá ṣe mú kí ohùn rẹ dà bí ohùn tẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, agbára ohùn rẹ àti àwọn adùn rẹ̀ ni kí o kọ́ bí wàá ṣe máa gbé yọ. Kí ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìyẹn? Ohun méjì pàtàkì ló lè ràn ọ́ lọ́wọ́.
Darí Afẹ́fẹ́ Tí Ò Ń Mí Sínú Sóde Bó Ṣe Tọ́. Kí ohùn rẹ lè dún ketekete, afẹ́fẹ́ tí ò ń mí sínú sóde ní láti pọ̀ tó, o sì ní láti darí ọ̀nà tí o gbà ń mí bó ṣe tọ́. Láìṣe nǹkan méjèèjì yìí, ohùn rẹ á máa dún hẹ́rẹ́hẹ́rẹ́, ọ̀rọ̀ rẹ ò sì ní lọ geerege.
Òkè igbáàyà kọ́ ni ẹ̀dọ̀fóró ti fẹ̀ jù lọ; egungun èjìká ló kàn jẹ́ kó dà bíi pé apá ibẹ̀ ló ti fẹ̀ jù. Dípò ìyẹn, apá òkè abonú gẹ́lẹ́ ló ti fẹ̀ jù lọ. Abonú yìí, tó so mọ́ ẹfọ́nhà nísàlẹ̀, ló la igbáàyà àti ikùn láàárín.
Bí ó bá jẹ́ pé kìkì òkè ẹ̀dọ̀fóró rẹ nìkan lo ń fa afẹ́fẹ́ kún nígbà tí o bá mí sínú, kò ní pẹ́ tí èémí tí o mí sínú á fi tán. Ohùn rẹ kò ní lágbára tó, kò sì ní pẹ́ tí yóò fi rẹ̀ ọ́. Láti lè mí bó ṣe yẹ, o ní láti jókòó dáadáa tàbí kí o nàró ṣánṣán, kí o sì ti èjìká rẹ sẹ́yìn. Kí o máa dìídì sapá láti má ṣe máa mí èémí kún kìkì apá òkè igbáàyà rẹ nìkan nígbà tí o bá mí sínú láti sọ̀rọ̀. Apá ìsàlẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró rẹ ni kí o kọ́kọ́ máa mí èémí kún ná. Tí afẹ́fẹ́ bá kún ibẹ̀, apá ìsàlẹ̀ ẹfọ́nhà rẹ yóò fẹ̀ sẹ́yìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì. Lẹ́sẹ̀ kan náà, abonú yóò wá sí ìsàlẹ̀, yóò rọra ti ikùn àti ìfun síwájú díẹ̀, ìyẹn lo máa ń jẹ́ kí o mọ̀ pé ìgbànú tàbí aṣọ tí o wọ̀ fún mọ́ ọ níkùn. Àmọ́ ṣá o, ibi ikùn nísàlẹ̀ kọ́ ni ẹ̀dọ̀fóró rẹ méjèèjì wà; inú igbáàyà rẹ ni wọ́n wà. Láti dánra wò, gbé ọwọ́ kọ̀ọ̀kan lé apá ìsàlẹ̀ ẹfọ́nhà rẹ méjèèjì. Wá mí sínú kanlẹ̀ dáadáa. Bí o bá mí sínú lọ́nà tó tọ́, o kò ní máa pánú kí o sì wá máa ga èjìká méjèèjì ga-n-ga. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wàá rí i pé ẹfọ́nhà rẹ rọra gbé sókè tó sì fẹ̀ síta.
Ohun tó kàn ni pé kí o darí ọ̀nà tí o gbà ń mí afẹ́fẹ́ síta. Má ṣe fi afẹ́fẹ́ tí o mí sínú ṣòfò nípa jíjẹ́ kí ó kàn rọ́ jáde. Ńṣe ni kí o jẹ́ kó rọra máa jáde díẹ̀díẹ̀. Má tìtorí pé o fẹ́ darí rẹ̀ kí o wá fún ọ̀nà ọ̀fun pọ̀ o. Ohùn rẹ kò ní pẹ́ há tàbí kó máa hanni létí tí o bá fún un pọ̀. Ìsúnkì àwọn iṣan ikún àti àwọn iṣan tó so ẹfọ́nhà pọ̀ ló ń ti afẹ́fẹ́ tí a mí sínú jáde, abonú sì ń darí bí ó ṣe máa yára jáde sí.
Bí eléré ìje ṣe ń fi eré sísá kọ́ra náà ni olùbánisọ̀rọ̀ ṣe lè máa tipa ìdánrawò kọ́ bí èèyàn ṣe ń darí èémí lọ́nà tó tọ́. Dìde dúró ṣánṣán kí o sì ti èjìká sẹ́yìn. Mí sínú láti fa afẹ́fẹ́ kún apá ìsàlẹ̀ ẹ̀dọ̀fóró rẹ méjèèjì, kí o wá rọra máa mí afẹ́fẹ́ inú rẹ sóde díẹ̀díẹ̀ kí o sì máa ka ení, èjì, ẹ̀ta lọ títí dórí iye tí o bá lè tètè kà á dé wọ́ọ́rọ́wọ́ kí èémí ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo yẹn tó tán. Lẹ́yìn náà, mí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ kí o wá máa kàwé síta láti fi dánra wò.
Dẹ Àwọn Iṣan Ara Tó Le. Ohun pàtàkì mìíràn tó tún ń mú kí ohùn dára ni pé kí o túra ká! Yóò yà ọ́ lẹ́nu gidigidi láti rí bí ohùn rẹ ṣe máa dára sí i tó bí o bá fi kọ́ra láti máa túra ká nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀. O ní láti fún ọkàn àti ara rẹ ní ìdẹ̀ra, nítorí bí ọpọlọ kò bá silẹ̀ ńṣe ni iṣan ara á le.
Ohun tó máa jẹ́ kí ọpọlọ rẹ silẹ̀ ni pé kí o ní èrò tí ó tọ́ nípa àwọn olùgbọ́ rẹ. Bí ó bá jẹ́ àwọn tí o bá pàdé lóde ẹ̀rí ni, rántí pé ká tiẹ̀ ní kò tíì ju oṣù bíi mélòó kan tí o bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o mọ àwọn nǹkan pàtàkì nípa ète Jèhófà tí o lè sọ fún wọn. Ohun tó sì jẹ́ kí o wá wọn wá ni pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́, yálà wọ́n mọ̀ bẹ́ẹ̀ tàbí wọn kò mọ̀. Ẹ̀wẹ̀, bó bá wá jẹ́ inú Gbọ̀ngàn Ìjọba lo ti ń sọ̀rọ̀, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn tó ń gbọ́ ọ ló jẹ́ èèyàn Jèhófà. Ọ̀rẹ́ rẹ ni wọ́n, àṣeyọrí ni wọ́n sì ń fẹ́ kí o ṣe. Kò sí àwọn olùbánisọ̀rọ̀ mìíràn láyé yìí tó lè rí àwùjọ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ wọn tó sì fẹ́ràn wọn bí àwùjọ tí àwa ń rí bá sọ̀rọ̀ déédéé.
Dẹ iṣan ọ̀nà ọ̀fun rẹ nípa fífọkàn sí i pé ò ń fẹ́ kí àwọn iṣan yẹn dẹ̀ kí o sì máa dìídì fúnra rẹ dẹ̀ wọ́n. Rántí pé àwọn tán-án-ná, tàbí okùn ohùn rẹ, máa ń gbọ̀n rìrì tí afẹ́fẹ́ bá kọjá lára wọn. Gẹ́lẹ́ bí ohùn ìlù dùndún tàbí ti gìtá ṣe ń yí padà bí a bá fa ọṣán rẹ̀ tàbí tí a bá dẹ̀ ẹ́, ni dídún ohùn ṣe máa ń yí padà níbàámu pẹ̀lú bí iṣan ọ̀nà ọ̀fun ṣe ń sún kì tàbí bí ó ṣe ń dẹ̀ sí. Nígbà tí o bá dẹ tán-án-ná ọ̀fun rẹ, ohùn rẹ yóò lọ sílẹ̀. Dídẹ iṣan ọ̀nà ọ̀fun rẹ máa ń mú kí káà imú rẹ ṣí sílẹ̀ pẹ̀lú, èyí yóò sì nípa lórí bí ohùn rẹ yóò ṣe dún ketekete sí.
Dẹ gbogbo ara rẹ, títí kan orúnkún, ọwọ́, èjìká, àti ọrùn rẹ. Ìyẹn á jẹ́ kí ohùn rẹ lè ró bó ṣe yẹ kí ó sì rìn jìnnà dáadáa. Gbogbo ara ló máa ń kù rìrì bíi gbohùngbohùn láti mú ìró ohùn jáde, téèyàn ò bá sì ti túra ká, ìdíwọ́ á wà fún ìkùrìrì ara. Bí ohùn bá dún jáde látinú gògòńgò, yàtọ̀ sí pé ó máa ń ró lọ sínú káà imú, ó tún máa ń ró lára egungun igbáàyà, lára eyín, lára káà ẹnu àti inú ihò imú. Gbogbo ìwọ̀nyí ló sì lè nípa lórí bí ìró ohùn ṣe máa dún ketekete sí. Bí o bá gbé nǹkan kan sórí agogo tó o sì lu agogo yẹn, yóò máa dún pọ̀-pọ̀-pọ̀ ni; kó tó lè máa dún gbọn-un bó ṣe tọ́, o ní láti kọ́kọ́ gbé nǹkan tó wà lórí rẹ̀ kúrò ná. Bí egungun ara tí ẹran ara wa so pọ̀ gírígírí ṣe rí náà nìyẹn. Bí ohùn rẹ bá ró dáadáa wàá lè yí ohùn padà bó ṣe yẹ nínú ọ̀rọ̀ rẹ, wàá sì lè fi bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára hàn lónírúurú ọ̀nà. Àwùjọ ńlá yóò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ketekete láìjẹ́ pé o ń fi agbára kígbe.