Àpótí Ìbéèrè
◼ Ìgbà wo ló yẹ ká dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó ń tẹ̀ síwájú dúró?
Ohun tó dáa jù ni pé ká máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹnì kan tó ń tẹ̀ síwájú nìṣó títí tó fi máa parí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ méjì, ìyẹn Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àti ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run.’ Ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe nìyẹn, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ṣèrìbọmi kó tó ka ìwé méjèèjì tán. Lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi, a ṣì lè máa ròyìn àkókò, ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí akéde kan bá wà pẹ̀lú yín nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, tó sì kópa nínú rẹ̀, òun náà lè ròyìn àkókò tẹ́ ẹ lò.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2009, ojú ìwé 2.
Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ẹni tuntun fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú òtítọ́ kó tó di pé a dá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró. Ó yẹ kí wọ́n “ta gbòǹgbò” nínú Kristi kí wọ́n sì “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́,” kí wọ́n lè kojú àwọn ìṣòro tó máa dojú kọ wọ́n. (Kól. 2:6, 7; 2 Tím. 3:12; 1 Pét. 5:8, 9) Láfikún sí i, kí wọ́n tó lè kọ́ àwọn míì lọ́nà tó múná dóko, wọ́n gbọ́dọ̀ ní “ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Tá a bá fi ìwé méjì ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wa, tá a sì parí rẹ̀, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọwọ́ kí wọ́n lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní “ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè.”—Mát. 7:14.
Kí àwọn alàgbà tó fọwọ́ sí i pé kí ẹnì kan ṣèrìbọmi, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i pé ó lóye ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa, kí ìgbé ayé rẹ̀ sì bá ohun tó ń kọ́ mu. Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidigidi tí wọ́n bá fẹ́ fọwọ́ sí ìrìbọmi akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tí kò tíì parí ìwé àkọ́kọ́. Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan kò tíì tóótun láti ṣe ìrìbọmi, kí àwọn alàgbà rí i pé àwọn fún onítọ̀hún ní ìrànlọ́wọ́ tó bá yẹ, kó bàa lè tóótun láti ṣèrìbọmi nígbà míì.—Wo ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà, ojú ìwé 217 sí 218.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 2]
Ó ṣe pàtàkì pé káwọn ẹni tuntun fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú òtítọ́