ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • sjj orin 90
  • Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú
  • “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ká Máa Fún Ara Wa Níṣìírí
    Kọrin sí Jèhófà
  • “Ẹ Máa Fún Ara Yín Níṣìírí, Kí Ẹ sì Máa Gbé Ara Yín Ró”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Má Ṣe Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ẹ Máa Ru Ara Yín Lọ́kàn Sókè Sí Ìfẹ́ àti Sí Àwọn Iṣẹ́ Àtàtà—Báwo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
“Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
sjj orin 90

ORIN 90

Ẹ Máa Gba Ara Yín Níyànjú

Bíi Ti Orí Ìwé

(Hébérù 10:24, 25)

  1. 1. Bá a ṣe ńkóra jọ láti jọ́sìn,

    Tí à ń fòótọ́ inú sin Jáà,

    À ń ru àwọn ará wa sókè;

    Sífẹ̀ẹ́ àti iṣẹ́ rere.

    Ibi ààbò ni ìjọ wa jẹ́,

    Ọkàn wa máa ń balẹ̀ níbẹ̀.

    Àlàáfíà wà láàárín gbogbo wa,

    A nífẹ̀ẹ́ ara wa dénú.

  2. 2. Ọ̀rọ̀ tá a sọ lákòókò tó yẹ

    Máa ń tura, ó sì ńgbéni ró!

    Ó máa ń jẹ́ káwọn tó sorí kọ́

    Rítùnú, kí wọ́n sì láyọ̀.

    Bí a ṣe jọ ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan,

    À ń wọ̀nà fún ayé tuntun!

    À ń gbéra wa ró, a sì ńlókun;

    A tún ń dúró ti ara wa.

  3. 3. Ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé.

    Ojú ìgbàgbọ́ la fi ń rí i.

    Torí náà, a ó máa pé jọ déédéé

    Ká lè máa rìn lọ́nà ìyè.

    Títí láé la ó máa sin Jèhófà,

    Àwa àti ẹgbẹ́ ará.

    Torí náà, ká máa gbéra wa ró

    Ká lè jẹ́ adúróṣinṣin.

(Tún wo Lúùkù 22:32; Ìṣe 14: 21, 22; Gál. 6:2; 1 Tẹs. 5:14.)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́