ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 1 TẸSALÓNÍKÀ 1-5
“Ẹ Máa Fún Ara Yín Níṣìírí, Kí Ẹ sì Máa Gbé Ara Yín Ró”
Gbogbo àwa Kristẹni la lè fún ẹlòmíì níṣìírí. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe káwọn ará wa máa kojú “ọ̀pọ̀ àtakò,” bóyá torí àìlera tàbí àwọn ìṣòro míì, àmọ́ ìṣírí ńlá ló máa jẹ́ fún wọn tá a bá ń wá sípàdé déédéé, tá a sì ń lọ sí òde ẹ̀rí. (1Tẹ 2:2) Tá a bá ti ronú nípa wọn ṣáájú, tá a sì ṣèwádìí, ó máa rọrùn fún wa láti sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ará wa tó nílò ìṣírí.
Ibo lo ti lè rí àwọn ìsọfúnni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fún ẹni tó ní ìṣòro níṣìírí?
Ta lo máa fẹ́ fún níṣìírí nínú ìjọ yín?