Ẹ Jẹ́ Alayọ Ki Ẹ Sì Wà Letoleto
WÍWÀ letoleto ń mú ki a ṣe awọn nǹkan daradara. Jíjẹ́ ẹni ti o jafafa ń ràn wá lọwọ lati lo akoko ati awọn ohun àmúṣọrọ wa lọna ti o dara julọ. (Galatia 6:16; Filippi 3:16; 1 Timoteu 3:2) Ṣugbọn igbesi-aye ní ninu ju kìkì iwaletoleto ati ijafafa lọ. Olorin ti a mísí naa kọwe pe: “Alayọ ni awọn eniyan ti Ọlọrun wọn jẹ Jehofa!” (Orin Dafidi 144:15, NW) Ipenija naa ni lati jẹ́ alayọ ati lati jẹ́ ẹni ti o wà letoleto ninu ohun gbogbo ti a bá ń ṣe.
Jíjẹ́ Ẹni Ti O Wà Letoleto ati Alayọ
Jehofa Ọlọrun ni apẹẹrẹ giga julọ nipa iṣeto daradara. Gbogbo awọn iṣẹda rẹ̀, lati ori awọn ẹ̀dá onísẹ́ẹ̀lì kanṣoṣo si awọn ẹ̀dá alaaye ti o dijupọ, lati ori awọn atom bín-íntín de awọn iṣupọ irawọ arabaribi, fi eto ati ìwànírẹ́gí hàn. Awọn ofin agbaye rẹ̀ mu ki a wewee igbesi-aye wa pẹlu ifọkanbalẹ. A mọ̀ pe oorun yoo yọ ni oroorọ ati pe ìgbà ẹẹrun yoo tẹle ìgbà otutu.—Genesisi 8:22; Isaiah 40:26.
Ṣugbọn Jehofa ju kìkì Ọlọrun eto nikan lọ. Oun tun jẹ́ “Ọlọrun alayọ” pẹlu. (1 Timoteu 1:11, NW; 1 Korinti 14:33) Ayọ rẹ̀ ni a rí ninu awọn iṣẹda rẹ̀. Awọn ọmọ ológìní ti ń ṣere, wíwọ̀ oorun ẹlẹwa, ounjẹ ti ń danilọrun, orin ti ń funni lokun, iṣẹ ti ń tunilara, ati ọpọ awọn nǹkan miiran fihàn pe ó ní i lọ́kàn pe ki a gbadun igbesi-aye. Awọn ofin rẹ̀ kìí ṣe ikalọwọko aronilara ṣugbọn wọn ń daabobo ayọ wa.
Jesu Kristi tẹle apẹẹrẹ Baba rẹ̀. Oun ni “ẹni alayọ ati Ọba Alagbara kanṣoṣo” ti ó sì ń huwa gẹlẹ bi Baba rẹ̀ ti ń ṣe. (1 Timoteu 6:15, NW; Johannu 5:19) Nigba ti o ṣiṣẹ kára pẹlu Baba rẹ̀ ninu iṣẹ iṣẹda, ó ju “oniṣẹ” lasan kan lọ. Ó layọ ninu ohun ti ó ṣe. Ó ‘ń yọ̀ nigba gbogbo niwaju [Jehofa]; ó ń yọ̀ nibi itẹdo ayé rẹ̀; didun-inu [rẹ̀] sì wà sipa awọn ọmọ eniyan.’ Owe 8:30, 31.
A fẹ lati fi iru iwapẹlẹ, inudidun, ati ikundun kan-naa hàn fun awọn eniyan ninu ohun gbogbo ti a bá ṣe. Lẹẹkọọkan, bi o ti wu ki o ri, ninu isapa fun ijafafa, a lè gbàgbé pe ‘rírìn letoleto nipa ti ẹmi [Ọlọrun]’ ni ninu mimu awọn eso ẹmi ti Ọlọrun jade. (Galatia 5:22-25) Nitori naa a ṣe daradara lati beere lọwọ araawa pe, Bawo ni a ṣe lè jẹ ẹni ti o wa letoleto ati alayọ ninu igbokegbodo tiwa funraawa ati ninu didari iṣẹ awọn ẹlomiran pẹlu?
Maṣe Rorò Mọ́ Araarẹ
Gbe imọran rere ti a kọsilẹ ninu Owe 11:17 yẹwo. Lakọọkọ onkọwe ti a mísí naa sọ fun wa pe “alaaanu eniyan ṣe rere fun araarẹ.” Lẹhin naa ó sọ ni ifiwera pe: “Ṣugbọn ìkà eniyan ń yọ ẹran-ara rẹ̀ ni ẹnu.” Bibeli New International Version sọ ọ́ ni ọ̀nà yi pe: “Ẹni pẹlẹ ń ṣanfaani fun araarẹ, ṣugbọn onroro eniyan ń mú ipalara wa fun araarẹ.”
Bawo ni a ṣe lè rorò mọ́ araawa laimọọmọ? Ọ̀nà kan jẹ́ nipa jíjẹ́ ẹni ti o ni ọkàn rere ṣugbọn ti o jẹ́ alaiwa letoleto patapata. Pẹlu awọn iyọrisi wo sì ni? Ọjọgbọn kan sọ pe: “Igbagbe, awọn isọfunni ti a kó pamọ lọna ti kò tọ́, àṣẹ kan ti a kò lóye lẹkun-un-rẹrẹ, ikesini ori tẹlifoonu kan ti a kò kọsilẹ lọna ti o pé rẹ́gí—awọn wọnyi ni kìkì isọfunni kekere nipa ikuna, awọn aràn ti ń jẹ aṣọ ijafafa ti wọn sì ń pa ète ti o dara julọ run.”—Teach Yourself Personal Efficiency.
Eyi wà ni ibamu pẹlu onkọwe ti a mísí naa ti o sọ pe: “Ẹni ti o lọ́ra pẹlu ni iṣẹ rẹ̀, arakunrin jẹguduragudu eniyan ni.” (Owe 18:9) Bẹẹni, awọn eniyan alaiwa letoleto, alaijafafa lè mú ijaba ati iparun wa sori araawọn ati awọn ẹlomiran. Nitori eyi, awọn miiran sábà maa ń pa wọn tì. Gẹgẹ bi abajade ilọra wọn, wọn ń mú itanulẹgbẹ wa sori araawọn.
Ààyè Aja Tabi Òkú Kinniun?
Ṣugbọn a lè rorò mọ́ araawa pẹlu nipa gbigbe awọn ọpa idiwọn giga rekọja aala lelẹ. Onkọwe lori ijafafa ti a mẹnukan loke yii sọ pe, a lè fojusun “ọpa-idiwọn ijẹpipe ti kò ṣeeṣe lati rí ni kikun.” Ó sọ pe, iyọrisi naa yoo jẹ́ “lati ni iriri irora ọkàn ati ariṣa amunirẹwẹsi nigbẹhin-gbẹhin.” Ẹnikan ti ń rinkinkin mọ́ ijẹpipe lè wà letoleto ki ó sì jafafa, ṣugbọn ohun kì yoo jẹ́ alayọ nitootọ lae. Laipẹ laijinna oun yoo ní kìkì irora ọkàn nikanṣoṣo.
Bi a bá tẹ̀ siha jíjẹ́ arinkinkin mọ ijẹpipe, a o ṣe rere lati ranti pe, “ààyè aja sàn ju òkú kinniun lọ.” (Oniwasu 9:4) A lè má pa araawa niti gidi nipa lilakaka fun ijẹpipe alaigbeṣẹ, ṣugbọn a lè ṣepalara fun araawa gidi gan-an nipa idalagara. Ọla-aṣẹ kan sọ pe, eyi ni ninu “idalagara niti ara ìyára, ero-imọlara, ẹmi, ọgbọn imoye, ati laaarin ẹnikan si ẹnikeji.” (Job Stress and Burnout) Dídá araawa lagara nipa lilepa awọn gongo ti ọwọ́ kò lè tẹ̀ jẹ́ rírorò mọ ara-ẹni ti ó sì ń gba ayọ mọ́ wa lọwọ laiṣeeyẹsilẹ.
Ba Araarẹ Lò Lọna Ti Ń Mú Èrè Wá
Ranti pe: “Ọkunrin oníṣeun-ìfẹ́ ń bá ọkàn araarẹ̀ lò lọna ti ń mú èrè wá.” (Owe 11:17, NW) A ń bá araawa lò lọna ti ń mú èrè wá nigba ti a bá gbé awọn gongo ti o jẹ́ gidi ti o sì bọgbọnmu kalẹ, ni fifi sọkan pe Ọlọrun alayọ, Jehofa, mọ ibi ti agbara wa mọ. (Orin Dafidi 103:8-14) A lè layọ bi awa pẹlu bá mọ awọn ààlà wọnni ti a sì “ṣe gbogbo ohun ti a lè ṣe,” niwọn bi agbara wa bá ti ṣe pọ̀ tó, lati mú awọn iṣẹ-aigbọdọmaṣe wa ṣẹ daradara.—Heberu 4:11; 2 Timoteu 2:15; 2 Peteru 1:10.
Nitootọ, ewu ti fífì si ipẹkun miiran maa ń wà nigba gbogbo—jíjẹ́ ẹni ti ń ṣaanu araawa jù. Maṣe gbagbe èsì Jesu si amọran aposteli Peteru, “Ṣaanu araarẹ, Oluwa,” nigba ti, o nilo igbesẹ onipinnu, niti tootọ. Èrò Peteru lewu tobẹẹ debi pe Jesu sọ pe: “Kuro niwaju mi, Satani! Okuta ikọsẹ ni iwọ jẹ́ fun mi, nitori iwọ ń rò, kìí ṣe awọn ironu Ọlọrun, bikoṣe ti awọn eniyan.” (Matteu 16:22, 23, NW) Bíbá ọkàn araawa lò lọna ti o mú èrè wá kò faaye gba iṣarasihuwa onijaafara, onikẹra-ẹni-bajẹ. Iyẹn lè tun fi gbogbo ayọ dù wá. Ẹmi ilọgbọn-ninu, kìí ṣe ti ìgbawèrèmẹ́sìn, ni oun ti a nilo.—Filippi 4:5.
Bá Awọn Ẹlomiran Lò Lọna Ti Ń Mú Èrè Wá
Ó ṣeeṣe ki awọn akọwe ati awọn Farisi ni ọjọ Jesu ronu pe awọn jafafa awọn sì wà letoleto lọna ti o ga. Iwe naa, A Dictionary of the Bible sọ nipa ọ̀nà ijọsin wọn pe: “Olukuluku ofin lati inu Bibeli ni awọn ilana alasokọra pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ yipo. A kò fi ààyè kankan silẹ fun awọn ipo ayika ti ń yipada; igbọran ni kikun si Ofin naa ni gbogbo apa rẹ̀ ni a fi dandan beere lọwọ gbogbo awọn Ju lọna ti ipa rẹ̀ kò ṣeeyipada . . . Awọn kulẹkulẹ ofin ni a sọ di pupọ titi di ìgbà ti isin fi di òwò kan, ati igbesi-aye ẹrù-ìnira tí kò ṣeefarada. Awọn eniyan ni a sọ di alailedaronu iwarere. Ohùn ẹ̀rí-ọkàn ni a fúnpa; agbara ọ̀rọ̀ Atọrunwa ti o walaaye ni a sọ di asan ti a sì fi awọn àṣẹ ti kò lopin bò ó mọ́lẹ̀.”
Abajọ ti Jesu Kristi fi dẹbi fun wọn nitori eyi. “Nitori wọn a di ẹrù wuwo ti o sì ṣoro lati rù,” ni o sọ, “wọn a sì gbé e ka awọn eniyan ni ejika; ṣugbọn awọn tikaraawọn kò jẹ fi ìka wọn kan ẹrù naa.” (Matteu 23:4) Awọn alagba onifẹẹ ń fà sẹhin kuro ninu dídi ẹrù wiwuwo kari agbo pẹlu ìsọdipúpọ̀ awọn àṣẹ ati ilana pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Wọn ń bá agbo Ọlọrun lò lọna ti ń mú èrè wá nipa titẹle apẹẹrẹ alaaanu, atunilara ti Kristi Jesu.—Matteu 11:28-30; Filippi 2:1-5.
Àní nigba ti awọn ẹrù-iṣẹ́ ti eto-ajọ bá di pupọ paapaa, awọn alagba ti wọn bikita kì yoo ṣalairi otitọ naa pe awọn ń bá awọn eniyan lò—awọn eniyan ti Ọlọrun nifẹẹ. (1 Peteru 5:2, 3, 7; 1 Johannu 4:8-10) Wọn kì yoo jẹ ki ọwọ́ wọn dí tobẹẹ pẹlu awọn ọ̀ràn ti eto-ajọ tabi awọn ọ̀nà-ìgbàṣe awọn nǹkan debi pe wọn yoo gbagbe ipa pataki wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan, alágbàtọ́, ati adaabobo agbo.—Owe 3:3; 19:22; 21:21; Isaiah 32:1, 2; Jeremiah 23:3, 4.
Mímú ki ọwọ́ dí gidigidi pẹlu awọn itolẹsẹẹsẹ ati irisi awọn eniyan, fun apẹẹrẹ, lè bori aniyan fun awọn eniyan. Gbé ọ̀ràn ti awakọ bọọsi kan yẹwo ti o ronu pe iṣẹ oun pataki ni lati dirọ mọ́ itolẹsẹẹsẹ oun laika ohun yoowu ki o ṣẹlẹ si lọna jijafafa. Oun ni aniyan naa lati lọ lati ipẹkun kan loju ọ̀nà ti o ń ná dé ipẹkun keji ni akoko ti a yàn ni géérégé ti gbà lọkan patapata. Lairi bi oun ti lè lero, ni oju-iwoye rẹ̀, awọn èrò ń dí i lọna. Wọn lọra wọn sì jẹ́ alaiwa letoleto wọn sì maa ń dé si ìdíkọ̀ gẹlẹ bi oun bá ti ń fẹ́ gbera. Dipo rírántí pe gbogbo koko iṣẹ rẹ̀ ni lati kún aini awọn èrò rẹ̀, ó ń wò wọn gẹgẹ bi idena si ijafafa ó sì ń yẹra fun wọn.
Bikita fun Ẹnikọọkan
Ilepa alaininuure fun ijafafa niye ìgbà maa ń pa aini awọn eniyan tì. Awọn alailera, alaijafafa ni a lè rí gẹgẹ bi adínilọ́wọ́. Nigba ti eyi bá ṣẹlẹ, awọn abajade buburu ni o lè jẹyọ. Fun apẹẹrẹ, ni ilu-nla Sparta ti Griki igbaani, awọn ọmọ ti kò lera ati alaisan ni a ń jọwọ wọn lọwọ lati kú. Wọn kò ní di ọmọ-ogun alagbara, ti o jafafa lati daabobo ilu lilagbara, jijafafa kan. “Nigba ti a bá bí ọmọ kan,” ni ọlọgbọn-imọ-ọran naa Bertrand Russell sọ, “baba rẹ̀ yoo mú un wa siwaju awọn alagba idile rẹ̀ lati ṣayẹwo rẹ̀: bi ó bá lera, a o gbe fun baba rẹ̀ pada lati tọ́ dagba; bi bẹẹ sì kọ́, oun ni a o gbé sọ sinu koto omi jijin kan.”—History of Western Philosophy.
Ailaaanu ati ilekoko, kìí ṣe ayọ, ni o sami si iru orilẹ-ede oníkà bẹẹ. (Fiwe Oniwasu 8:9.) Abajọ ti awọn alaṣẹ Sparta fi rò pe ifẹ fun ijafafa mu awọn jàre, ṣugbọn iwa wọn kò ní ìyọ́nú tabi aanu ninu rárá. Ọ̀nà wọn kìí ṣe ọ̀nà Ọlọrun. (Orin Dafidi 41:1; Owe 14:21) Ni iyatọ gédégédé, awọn alaboojuto ninu ijọ Kristian ń ranti pe gbogbo awọn agutan Ọlọrun ṣeyebiye ni oju rẹ̀, wọn sì ń bá ọkọọkan wọn lò lọna ti ń mú èrè wá. Wọn bikita kìí ṣe fun kìkì 99 ti ara wọn dá ṣugbọn fun ọ̀kan ti o jẹ́ alailera tabi ti o ni idaamu niti ero-imọlara pẹlu.—Matteu 18:12-14; Iṣe 20:28; 1 Tessalonika 5:14, 15; 1 Peteru 5:7.
Wà Pẹkipẹki Pẹlu Agbo Naa
Awọn alagba ń wà pẹkipẹki pẹlu agbo ti o wà nikaawọ wọn. Àmọ́ sáá o, iwadii ode-oni ninu awọn ọ̀nà-ìgbàṣe iṣẹ-aje, lè damọran pe nitori ijafafa ti o ga julọ oludari tabi alaboojuto kan kò nilati wà pẹkipẹki pẹlu awọn wọnni ti oun ń ṣabojuto. Oluwadii kan ṣapejuwe awọn iyọrisi ọ̀tọ̀ tí oṣiṣẹ ọmọ-ogun oju ofuurufu kan niriiri rẹ̀ nigba ti o bá sunmọ tabi jinna si awọn ọmọ-abẹ rẹ̀: “Nigba ti o bá ni ibatan timọtimọ pẹlu awọn oṣiṣẹ [rẹ̀], o jọbi pe wọn nimọlara aabo wọn kìí sìí ṣaniyan kọja ààlà nipa ijafafa ẹka wọn. Gbàrà ti o bá ti koju kuro nilẹ ti o sì ni itẹsi siha fifi ipo ajulọ rẹ̀ hàn, awọn oṣiṣẹ ológun ti o wà labẹ rẹ̀ a bẹrẹ sii ṣaniyan boya ohun kan ti dojuru . . . wọn yoo sì dari aniyan wọn si titubọ fiyesi iṣẹ wọn. Gẹgẹ bi iyọrisi, ibisi ti o farahan daadaa ninu ijafafa ibudo ológun naa a maa wà.”—Understanding Organizations.
Ijọ Kristian, bi o ti wu ki o ri, kìí ṣe eto-ajọ ológun. Awọn Kristian alagba ti wọn ń bojuto iṣẹ awọn ẹlomiran fi Jesu Kristi ṣe awokọṣe araawọn. Oun sábà maa ń wà pẹkipẹki pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (Matteu 12:49, 50; Johannu 13:34, 35) Oun kò lo aniyan wọn rí lati jèrè ijafafa sii. Ó mú isopọ alagbara ti igbọkanle ati igbẹkẹle tọtuntosi lilagbara laaarin araarẹ ati awọn ọmọlẹhin rẹ̀ dagba. Awọn isopọ pẹkipẹki ti ifẹni onijẹlẹnkẹ jẹ́ ami idanimọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. (1 Tessalonika 2:7, 8) Nigba ti iru iwapẹkipẹki bẹẹ bá wà, agbo alayọ kan, ti ifẹ Ọlọrun sún ni kikun, yoo dahunpada daradara si idari laisi ìfipámúṣiṣẹ́ wọn yoo sì ṣe gbogbo ohun ti wọn bá lè ṣe ninu iṣẹ-isin onimuuratan si i.—Fiwe Eksodu 35:21.
Ọpọ awọn iwe mimọ tẹnumọ awọn animọ Kristian bi ayọ ati ifẹ fun ẹgbẹ́-ará. (Matteu 5:3-12; 1 Korinti 13:1-13) Iwọnba diẹ ni ifiwera tẹnumọ aini naa fun ijafafa. Dajudaju, aini kan wà fun iṣeto daradara. Awọn eniyan Ọlọrun ti sábà maa ń wà letoleto. Ṣugbọn ronu, fun apẹẹrẹ, nipa bi awọn onkọwe awọn orin ṣe ń sapejuwe awọn iranṣẹ Ọlọrun gẹgẹ bi alayọ tó. Orin Dafidi 119, ti o ni ohun pupọ lati sọ nipa awọn ofin, irannileti, ati ilana Jehofa, bẹrẹ pe: “Alayọ ni awọn aláìlárìíwísí ni ọ̀nà wọn, awọn ẹni ti wọn ń rìn ninu ofin Jehofa. Alayọ ni awọn wọnni ti ń pa awọn irannileti rẹ̀ mọ́; pẹlu gbogbo ọkan-aya wọn ni wọn ń baa lọ ni wíwá a kiri.” (Orin Dafidi 119:1, 2, NW) Iwọ ha lè koju ipenija naa lati jẹ́ ẹni ti o wà letoleto ti o sì layọ bi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Òbíríkítí armillary—ohun-eelo ijimiji lati duroṣoju fun awọn òbìrí ti ọrun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Jehofa, gẹgẹ bi Oluṣọ-agutan onifẹẹ, jẹ Ọlọrun ti kìí ṣe ti eto nikan ṣugbọn ti ayọ pẹlu
[Credit Line]
Garo Nalbandian