ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/96 ojú ìwé 1
  • Ẹ Jẹ́ Olùṣe—Kì Í Ṣe Olùgbọ́ Lásán

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Olùṣe—Kì Í Ṣe Olùgbọ́ Lásán
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Onídùnnú-ayọ̀ “Olùṣe Ọ̀rọ̀ Naa”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àwọn Olùṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Wí Jẹ́ Aláyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Ẹ Máa Ṣe Ohun Tí Ọ̀rọ̀ Náà Sọ”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 1/96 ojú ìwé 1

Ẹ Jẹ́ Olùṣe—Kì Í Ṣe Olùgbọ́ Lásán

1 Lónìí, àwọn Kristian tòótọ́ ń fi ìṣítí Bibeli láti jẹ́ olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í ṣe olùgbọ́ lásán, sọ́kàn. (Jak. 1:22) Èyí mú kí wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí ń fi ẹnu lásán sin Ọlọrun, bí wọ́n tilẹ̀ ń pe ara wọn ní Kristian. (Isa. 29:13) Jesu sọ kedere pé kìkì àwọn tí ń ṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun ni a óò gbà là.—Matt. 7:21.

2 Ìjọsìn láìsí àwọn ìṣe ìwà-bí-Ọlọrun kò nítumọ̀. (Jak. 2:26) Nítorí náà, ó yẹ kí a bi ara wa léèrè pé, ‘Báwo ni àwọn iṣẹ́ mi ṣe fẹ̀rí hàn pé ìgbàgbọ́ mi jẹ́ ojúlówó? Kí ní ń fi hàn pé ní tòótọ́ ni mo ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí mo gbà gbọ́? Báwo ni mo ṣe lè fara wé Jesu lọ́nà kíkún rẹ́rẹ́ sí i?’ Ìdáhùn aláìlábòsí sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìtẹ̀síwájú tí a ti ṣe tàbí tí a ṣì ní láti ṣe nínú ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun.

3 Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jesu, góńgó wa àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé gbọ́dọ̀ rí bákan náà gẹ́gẹ́ bí onipsalmu ṣe sọ: “Ní ti Ọlọrun ni àwa ń kọrin ìyìn ní ọjọ́ gbogbo, àwá sì ń yin orúkọ rẹ láéláé.” (Orin Da. 44:8) Ìsìn Kristian jẹ́ ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń fara rẹ̀ hàn lójoojúmọ́ àti nínú gbogbo ohun tí a ń ṣe. Ẹ wo irú ìtẹ́lọ́rùn tí a ń rí bí a ti ń fi ìfẹ́ àtọkànwá wa láti yin Jehofa hàn gbangba nínú gbogbo ìgbòkègbodò wa!—Filip. 1:11.

4 Yíyin Jehofa Ní Nínú Ju Gbígbé Ìgbésí Ayé Adúróṣánṣán Lọ: Bí ó bá jẹ́ ìwà àtàtà nìkan ni Ọlọrun ń béèrè fún, ó ṣeé ṣe fún wa láti wulẹ̀ pọkàn pọ̀ sórí títún ìwà wa ṣe. Àmọ́ ṣáá o, ìjọsìn wa tún ní pípolongo àwọn ìtayọlọ́lá Jehofa káàkiri àti ṣíṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀ nínú!—Heb. 13:15; 1 Pet. 2:9.

5 Wíwàásù ìhìn rere ní gbangba jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ pàtàkì jù lọ tí a ń ṣe. Jesu fi gbogbo ara rẹ̀ fún iṣẹ́ yìí nítorí tí ó mọ̀ pé ó túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tí yóò tẹ́tí sílẹ̀, (Joh. 17:3) Lónìí, “iṣẹ́-òjíṣẹ́ ọ̀rọ̀ naa” ṣe pàtàkì lọ́nà kan náà; ó jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè fi gba àwọn ènìyàn là. (Ìṣe 6:4; Romu 10:13) Ní mímọ àwọn àǹfààní gbígbòòrò tí ó ní, a lè túbọ̀ lóye ìdí tí Paulu fi ṣí wa létí láti “wàásù ọ̀rọ̀ naa,” kí a sì “wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.”—2 Tim. 4:2.

6 Ìwọ̀n wo ni yíyin Jehofa yẹ kí ó gbà nínú ìgbésí ayé wa? Onipsalmu náà sọ pé, ó wà ní ọkàn òun ní ọjọ́ gbogbo. Àwa kò ha nímọ̀lára lọ́nà kan náà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, a óò sì ka gbogbo ìgbà tí a bá pàdé pẹ̀lú ẹlòmíràn sí àkókò ṣíṣeé ṣe kan láti sọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jehofa. A óò wá àkókò tí ó bọ́ sí i láti darí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wa sórí ohun tẹ̀mí. A óò tún làkàkà láti ṣàjọpín déédéé nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá tí ìjọ ṣètò. Àwọn tí ipò wọn yọ̀ọ̀da fún lè ronú jinlẹ̀ lórí iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà, nítorí èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi iṣẹ́ ìwàásù sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa lójoojúmọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun mú un dá wa lójú pé, nípa bíbá a nìṣó láti jẹ́ olùṣe ìfẹ́ inú Ọlọrun, a óò láyọ̀.—Jak. 1:25.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́