ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • rq ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 16-17
  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí
  • Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdílé Rẹ Lè Láyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Táá Mú Kí Ìdílé Rẹ Láyọ̀
    Jí!—2021
  • Ohun Tó O Lè Ṣe Kí Ìdílé Rẹ Lè Jẹ́ Aláyọ̀
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Ní Ayọ̀?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
Àwọn Míì
Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
rq ẹ̀kọ́ 8 ojú ìwé 16-17

Ẹ̀kọ́ 8

Ìgbésí Ayé Ìdílé Tí Inú Ọlọrun Dùn Sí

Kí ni ipò ọkọ nínú ìdílé? (1)

Báwo ni ó ṣe yẹ kí ọkọ bá aya rẹ̀ lò? (2)

Kí ni ẹrù iṣẹ́ bàbá? (3)

Kí ni ojúṣe aya nínú ìdílé? (4)

Kí ni Ọlọrun ń béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ? (5)

Kí ni ojú ìwòye Bibeli nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀? (6, 7)

1. Bibeli sọ pé ọkọ ni olórí ìdílé rẹ̀. (1 Korinti 11:⁠3) Aya kan péré ni ọkọ kan gbọ́dọ̀ ní. Wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó bí ó ti tọ́ ní ìbámu pẹ̀lú òfin.​—⁠1 Timoteu 3:⁠2; Titu 3:⁠1.

2. Ọkọ́ ní láti nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀, gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí ó ti nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀. Ó ní láti bá a lò ní ọ̀nà tí Jesu gbà bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò. (Efesu 5:​25, 28, 29) Kò gbọdọ̀ lu aya rẹ̀ tàbí ṣìkà sí i lọ́nàkọnà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fi ọlá àti ọ̀wọ̀ hàn sí i.​—⁠Kolosse 3:19; 1 Peteru 3:⁠7.

3. Bàbá ní láti ṣiṣẹ́ kára láti bójú tó ìdílé rẹ̀. Ó gbọ́dọ̀ pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé fún aya àti àwọn ọmọ rẹ̀. Bàbá tún gbọ́dọ̀ pèsè àwọn àìní tẹ̀mí fún ìdílé rẹ̀. (1 Timoteu 5:⁠8) Ó ń mú ipò iwájú nínú ríran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọrun àti àwọn ète Rẹ̀.​—⁠Deuteronomi 6:​4-⁠9; Efesu 6:⁠4.

4. Aya gbọ́dọ̀ jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rere fún ọkọ rẹ̀. (Genesisi 2:18) Ó ní láti ran ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ nínú kíkọ́ àti títọ́ àwọn ọmọ wọn. (Owe 1:⁠8) Jehofa ń béèrè pé kí aya bójú tó ìdílé rẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. (Owe 31:​10, 15, 26, 27; Titu 2:​4, 5) Ó gbọ́dọ̀ ní ọ̀wọ̀ ­jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.​—⁠Efesu 5:​22, 23, 33.

5. Ọlọrun ń béèrè pé kí àwọn ọmọ gbọ́ràn sí àwọn òbí wọn lẹ́nu. (Efesu 6:​1-⁠3) Ó retí pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ lo àkókò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pẹ̀lú wọn, ní bíbójú tó àwọn àìní wọn tẹ̀mí àti ti èrò ìmọ̀lára. (Deuteronomi 11:​18, 19; Owe 22:​6, 15) Àwọn òbí kò gbọdọ̀ bá àwọn ọmọ wọn wí ní ọ̀nà líle koko tàbí rírorò láé.​—⁠Kolosse 3:⁠21.

6. Nígbà tí tọkọtaya bá ní ìṣòro gbígbé pọ̀ ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n ní láti gbìyànjú láti lo ìmọ̀ràn Bibeli. Bibeli rọ̀ wá láti fi ìfẹ́ hàn, kí á sì máa dárí jini. (Kolosse 3:​12-⁠14) Ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò fún ìpínyà níṣìírí, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan láti yanjú àwọn ìṣòro pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́. Ṣùgbọ́n, aya lè yàn láti fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ bí (1) ọkọ rẹ̀ bá kọ̀ jálẹ̀jálẹ̀ láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé rẹ̀, bí (2) ọkọ rẹ̀ bá jẹ́ oníwà ipá, tí ìwàláàyè aya àti ìlera rẹ̀ sì wà nínú ewu, tàbí bí (3) àtakò àṣerégèé ọkọ rẹ̀ kò bá jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún aya láti jọ́sìn Jehofa.​—⁠1 Korinti 7:​12, 13.

7. Àwọn tọkọtaya gbọ́dọ̀ jẹ́ olùṣòtítọ́ sí ara wọn. Panṣágà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun àti sí ẹnì kejì ẹni. (Heberu 13:⁠4) Ìbálòpọ̀ lẹ́yìn òde ìgbéyàwó nìkan ni ìpìlẹ̀ kan ṣoṣo tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún ìkọ̀sílẹ̀, tí ó yọ̀ǹda fún fífẹ́ ẹlòmíràn. (Matteu 19:​6-⁠9; Romu 7:​2, 3) Jehofa kórìíra rẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá kọ ara wọn sílẹ̀ láìsí ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, tí wọ́n sì fẹ́ ẹlòmíràn.​—⁠Malaki 2:​14-⁠16.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Bàbá onífẹ̀ẹ́ máa ń pèsè fún ìdílé rẹ̀ nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ọlọrun retí pé kí àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn ní ìtọ́ni, kí wọ́n sì tọ́ wọn sọ́nà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́