ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/97 ojú ìwé 1
  • Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà Lójoojúmọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà Lójoojúmọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Máa Yin Jèhófà Lójoojúmọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ẹ Máa Yin Jehofa Nígbà Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Baba Wa Gan-an!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 12/97 ojú ìwé 1

Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà Lójoojúmọ́

1 Àwọn ènìyàn máa ń gbádùn sísọ̀rọ̀ nípa ohun yòó wù tí wọ́n bá ṣìkẹ́ nínú ọkàn àyà wọn, nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu ohun tí ń bẹ nínú ọkàn àyà ni ẹnu má a ń sọ. (Lúùkù 6:45b) Kí ni ó ṣe iyebíye nínú ọkàn àyà wa? Onísáàmù kọ̀wé pé: “Ahọ́n mi yóò sì máa sọ̀rọ̀ òdodo rẹ, àti ti ìyìn rẹ ní gbogbo ọjọ́.” (Orin Dá. 35:28) Ó ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún Jèhófà, ó sì kà á sí àǹfààní gidi kan láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run kí ó sì má a yìn ín ní gbogbo ìgbà. Níwọ̀n bí òun ti di ojúlùmọ̀ Jèhófà tímọ́tímọ́, onísáàmù náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan láti yọ̀ nípa rẹ̀. (Orin Dá. 35:9) Báwo ni a ṣe lè fara wé àpẹẹrẹ rere rẹ̀?

2 Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà Nínú Ilé Rẹ: Ó yẹ kí Jèhófà jẹ́ kókó ìjíròrò ojoojúmọ́ nínú agbo ìdílé. Bí ó ṣe máa ń rí, àwọn òbí tí wọ́n ní ìfẹ́ tí ó lágbára fún Jèhófà yóò máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú gbogbo ìgbòkègbodò wọn. (Diu. 6:5-7) Bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ yóò kíyè sí i pé bàbá àti ìyá wọn ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n sì ń ṣìkẹ́ òfin Ọlọ́run. Nígbà náà, àwọn ọmọ yóò wo ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí àwọn òbí wọn gbà ń fi ìfọkànsìn Ọlọ́run hàn lọ́nà tí ó jẹ́ ojúlówó.—2 Pét. 3:11.

3 Bá Àwọn Ará Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà: Nínú ìgbòkègbodò ti ìṣàkóso Ọlọ́run tí a ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ èrò inú àti ọkàn àyà wa. A kò ṣaláìní ohun rere tí a lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rí. (Lúùkù 6:45a) Kókó kan ha wà tí o kọ́ láti inú ìdákẹ́kọ̀ọ́ tàbí láti inú Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ rẹ tí o gbádùn ní pàtàkì bí? Ṣàjọpín rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará, ní títipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ wọn fún Jèhófà pọ̀ sí i.—Orin Dá. 35:18; Héb. 10:24.

4 Bá Àwọn Ẹlòmíràn Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà: Nínú ìbálò wa ojoojúmọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn—níbi iṣẹ́, ní ilé ẹ̀kọ́, àti pẹ̀lú àwọn mẹ́ńbà ìdílé tí ó jẹ́ aláìgbàgbọ́—ó yẹ kí ó tètè hàn gbangba pé ohun pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa jẹ́ jíjẹ́rìí nípa Jèhófà. Dípò kí a di ẹni tí ọ̀rọ̀ rírùn àti ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ ayé yìí kó èérí bá, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ wa máa gbé Ọlọ́run ga. Lójoojúmọ́, ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀, bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìhìn rere tí òun ti pàṣẹ fún wa láti wàásù.—Ìṣe 5:42; Kól. 4:6.

5 Gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ olùjọ́sìn Jèhófà, ǹjẹ́ kí a máa wá àǹfààní lójoojúmọ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, Ọlọ́run wa aláìláfiwé.—Orin Dá. 106:47.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́