Àárò Rẹ Sọni!
1 Láti ìgbà dé ìgbà, a lè pa àwọn ìpàdé ìjọ jẹ lẹ́ẹ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí a sì rò pé ‘kò sí ẹnì kankan tí yóò sàárò mi; wọn kò tilẹ̀ ní mọ̀ pé n kò sí níbẹ̀.’ Ìyẹn kì í ṣe òótọ́! Gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà ara ìyára wa èyíkéyìí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń kó ipa pàtàkì nínú ìṣiṣẹ́ ìjọ. (1 Kọ́r. 12:12) Àìwá wa sí ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ lè nípa lórí ìlera tẹ̀mí àwọn mìíràn tí ó wá. Bí o kò bá sí níbẹ̀, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé—àárò rẹ sọni!
2 Ipa Pàtàkì Tí Ìwọ Ń Kó: Pọ́ọ̀lù ń yán hànhàn láti bá àwọn arákùnrin rẹ̀ kẹ́gbẹ́. Róòmù 1:11, 12 ṣàlàyé ìdí rẹ̀ pé: “Kí n lè fi ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀ fún yín . . . kí pàṣípààrọ̀ ìṣírí lè wà láàárín yín, láti ọ̀dọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹnì kejì, tiyín àti tèmi.” Bákan náà, nípa àwọn ìdáhùn wa, apá tiwa ní ìpàdé, àti wíwà níbẹ̀ wa gan-an, a ń ṣe púpọ̀ láti gbé ara wa ró lẹ́nì kíní kejì láti máa bá a nìṣó nínú ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́.—1 Tẹs. 5:11.
3 Ìwọ kì í ha ń fojú sọ́nà láti rí àwọn ẹlòmíràn ní àwọn ìpàdé ìjọ bí? O ń fetí sílẹ̀ dáadáa sí àwọn ìdáhùn wọn, o sì mọrírì ìgbàgbọ́ tí wọ́n ń fi hàn. Àwọn ẹ̀bùn wọn nípa tẹ̀mí ń gbé ọ ró. Bí wọn kò bá wá sí ìpàdé, ìwọ yóò ní ìmọ̀lára pé nǹkan pàtàkì kan kò sí níbẹ̀. Bákan náà ni ìmọ̀lára àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ rí nípa rẹ bí o kò bá wá.
4 Ipa Pàtàkì Tí Àwọn Ìpàdé Ń Kó: Ilé Ìṣọ́ ṣàlàyé nígbà kan lórí bí àwọn ìpàdé ti ṣe pàtàkì tó fún lílàájá wa nípa tẹ̀mí, ó sọ pé: “Ninu ayé oniwapalapala, ti o kun fun ija yii, ijọ Kristian jẹ́ ibi-isadi tẹmi toootọ . . . , èbúté alaafia ati ifẹ. Nitori naa, jẹ́ ẹni ti ń wà ní gbogbo ipade rẹ̀ deedee.” (w93-YR 8/15 11) Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, a ń dojú kọ àwọn ìṣòro tí ń tán wa lókun nípa tẹ̀mí. Bí a kò bá ṣọ́ra, a lè jẹ́ kí àwọn àníyàn tiwa gbà wá lọ́kàn pátápátá tí a fi lè gbàgbé àwọn ohun tẹ̀mí tí ó ṣe pàtàkì jù. Gbogbo wa ni a gbára lé ara wa lẹ́nì kíní kejì fún ìṣírí tí a nílò kí a lè wà ní ìṣọ̀kan, kí a sì jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Héb. 10:24, 25.
5 Wíwá tí a ń wá sí àwọn ìpàdé ṣe pàtàkì. Àìsàn tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ lè máà jẹ́ kí a wá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Yàtọ̀ sí èyí, ẹ jẹ́ kí a pinnu láti fìgbà gbogbo wà lára àwọn àpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń jùmọ̀ fi ìyìn fún Jèhófà!—Orin Dá. 26:12.