ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 1
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 8
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 15
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 22
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 29
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 12/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún December

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 1

Orin 57

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà Lójoojúmọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tí o bá ń kárí ìpínrọ̀ 4, fi àwọn àlàyé láti inú Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ 16, ìpínrọ̀ 14 sí 16 kún un.

20 min: “Fífi Ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lọni.” Fi ìtara dámọ̀ràn fífi ìwé Ìmọ̀ lọni, pàápàá jù lọ fún àwọn tí wọ́n ti fi ọkàn ìfẹ́ hàn tẹ́lẹ̀. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dámọ̀ràn. Ṣàṣefihàn ọ̀kan nínú wọn fún ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò tí ó bá a mu.

Orin 165 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 8

Orin 58

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

20 min: “Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Kí O Fẹjọ́ Ẹni Tí Ó Hùwà Ibi Sùn?” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, August 15, 1997, ojú ìwé 26 sí 30.

15 min: “Àárò Rẹ Sọni!” Ìjíròrò tí alàgbà darí pẹ̀lú àwùjọ. Mẹ́nu kan ìpíndọ́gba iye àwọn tí ń wá sí ìpàdé ìjọ. Ké sí àwọn mélòó kan láti sọ ìdí tí wíwà pa pọ̀ ní àwọn ìpàdé fi ń tù wọ́n lára.

Orin 172 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 15

Orin 63

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Fúnni ní àwọn àbá lórí bí a ṣe lè fi ọgbọ́n dáhùn àwọn ìkíni ọdún ti ayé. Sọ àwọn ìṣètò tí a ṣe fún àkànṣe iṣẹ́ ìsìn pápá fún December 25 àti January 1.

8 min: Ṣàyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká.”

25 min: “Ó Yẹ Kí A Jẹ́ Olùkọ́, Kì Í Ṣe Oníwàásù Nìkan.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Nígbà tí o bá ń kárí ìpínrọ̀ 11, ka Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ 15, ìpínrọ̀ 11.

Orin 174 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 22

Orin 138

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

17 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1998.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó ilé ẹ̀kọ́. Ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tí gbogbo ìjọ fi lè túbọ̀ jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láti inú ilé ẹ̀kọ́ ní ọdún tí ń bọ̀. Fún wọn níṣìírí láti máa ka “Àfikún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì Kíkà” lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

20 min: Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo. Ìjíròrò ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 92 sí 97 pẹ̀lú àwùjọ, kí o lo àwọn ìbéèrè yí: (1) Èé ṣe tí lílò tí a ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa fi gbéṣẹ́ ní títan ìhìn rere náà kálẹ̀? Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀? (2) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ìjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà jẹ wá lọ́kàn? Kí ni díẹ̀ nínú àwọn ọ̀nà tí a lè gbà jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà? (Ké sí àwọn mélòó kan láti sọ ìrírí nípa jíjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà.) (3) Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ìjọ sakun láti kárí ìpínlẹ̀ tí a yàn fún un dáadáa? Níbi tí ìpínlẹ̀ ti pọ̀, kí ni àǹfààní tí ó wà nínú níní ìpínlẹ̀ tẹni? (4) Báwo ni a ṣe ń jàǹfààní láti inú àwọn ìṣètò fún ìjẹ́rìí àjẹ́pọ̀? Báwo ni a ṣe lè wéwèé ìgbòkègbodò ìjẹ́rìí wa láti rí i dájú pé a ń lo àkókò wa lọ́nà tí ó dára jù lọ?

Orin 222 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní December 29

Orin 181

8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán gbogbo ìjọ létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀. Bí a óò bá yí àkókò ìpàdé ìjọ yín pa dà ní ọdún tuntun yìí, fún gbogbo àwùjọ níṣìírí onínúure láti máa bá a lọ láti pésẹ̀ déédéé pẹ̀lú ìjọ ní àwọn àkókò tuntun náà.

12 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní January. Fi àwọn ìwé ògbólógbòó tí ìjọ ní púpọ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ hàn, kí o sì mẹ́nu kan àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ fífani lọ́kàn mọ́ra tí yóò ṣèrànwọ́ ní mímúra àwọn ìgbékalẹ̀ sílẹ̀. Fi àṣefihàn kan kún un. Ó yẹ kí a máa bá ìsapá wa láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ yálà nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí nínú ìwé Ìmọ̀ nìṣó.

25 min: “Dènà Àwọn Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Tí Kò Wu Ọlọrun!” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, August 15, 1995, ojú ìwé 28 sí 30.

Orin 215 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́