Ojú Ìwòye Bíbélì
Ìkún Omi Náà Òtítọ́ Tàbí Àròsọ?
‘Gbogbo àwọn ẹranko náà sì wọlé tọ Nóà lọ nínú ọkọ̀ ní méjìméjì.’—Jẹ́nẹ́sísì 7:8, 9.
TA NI kò tí ì gbọ́ nípa Ìkún Omi ọjọ́ Nóà rí? Ó ṣeé ṣe kí o ti mọ ìtàn náà láti ìgbà ọmọdé. Ní tòótọ́, bí o bá lọ sí ibi ìkówèésí àdúgbò láti wádìí nípa Ìkún Omi náà, o lè rí ìwé púpọ̀ rẹpẹtẹ tí a kọ fún àwọn ọmọdé ju ti àwọn àgbàlagbà lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, o lè pinnu láti wulẹ̀ wo àkọsílẹ̀ nípa Ìkún Omi náà gẹ́gẹ́ bí ìtàn àgbọ́sùn kan lásán. Ọ̀pọ̀ ènìyàn rò pé ìtàn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, pa pọ̀ mọ́ púpọ̀ nínú àwọn apá yòó kù nínú Bíbélì wulẹ̀ jẹ́ àròsọ lásán kan, tàbí pátápinrá rẹ̀, ó jẹ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n ìwà híhù kan tí ènìyàn rò sọ.
Ó yani lẹ́nu pé, àwọn kan tí wọ́n tilẹ̀ sọ pé àwọn gbé ìgbàgbọ́ ìsìn àwọn karí Bíbélì pàápàá ń ṣiyè méjì lórí bóyá Ìkún Omi náà ṣẹlẹ̀ ní tòótọ́. Àlùfáà Kátólíìkì náà, Edward J. McLean, sọ nígbà kan pé a kò pète láti túmọ̀ ìtàn Nóà bí ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n a pète rẹ̀ bí “ìtàn olówe tàbí oríṣi lítíréṣọ̀ kan.”
Bí ó ti wù kí ó rí, ìròyìn Ìkún Omi tí ó wà nínú Bíbélì ha jẹ́ ìtàn olówe kan tí a kò pète láti túmọ̀ ní olówuuru bí? Bíbélì fúnra rẹ̀ ha fàyè gba irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀ bí?
Kúlẹ̀kúlẹ̀ Tí Ó Ṣeé Gbà Gbọ́
Kọ́kọ́ gbé àkọsílẹ̀ tí Mósè ṣe nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì yẹ̀ wò. Níbẹ̀, a rí ọdún, oṣù, àti ọjọ́ pàtó, tí ìyalulẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀, ìgbà tí ọkọ̀ náà gúnlẹ̀, àti ìgbà tí omi gbẹ kúrò lórí ilẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 7:11; 8:4, 13, 14) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò sábà máa ń ṣe àkọsílẹ̀ àwọn déètì pàtó níbòmíràn nínú Jẹ́nẹ́sísì, àwọn déètì wọ̀nyí tẹnu mọ́ òtítọ́ náà pé Mósè rí Ìkún Omi náà bí ìṣẹ̀lẹ̀ gidi. Fi bí òtítọ́ Bíbélì ṣe dún tó wé àwọn ọ̀rọ̀ tí ń bẹ̀rẹ̀ ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àròsọ pé, “Ní ìgbà kan . . .”
Bí àpẹẹrẹ mìíràn, ṣàgbéyẹ̀wò ọkọ̀ náà fúnra rẹ̀. Bíbélì ṣàpèjúwe àpótí kan tí ó gùn ní nǹkan bíi mítà 133, tí ìṣirò ìfiwéra gígùn rẹ̀ sí gíga rẹ̀ jẹ́ ìpín 10 sí 1, tí ti gígùn rẹ̀ sí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìpín 6 sí 1. (Jẹ́nẹ́sísì 6:15) Bẹ́ẹ̀, Nóà kì í ṣe kankọ̀kankọ̀. Sì rántí pé, ó ti lé ní 4,000 ọdún sẹ́yìn báyìí! Síbẹ̀, a kan ọkọ̀ náà ní ìwọ̀n tí ó bá a mu jù lọ fún iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpótí tí ń léfòó kan. Ní ti gidi, àwọn tí ń ṣàgbékalẹ̀ ìrísí ọkọ̀ ojú omi òde òní ti rí i pé irú ìṣirò ìfiwéra yẹn bá a mu wẹ́kú fún ọ̀nà àgbékalẹ̀ títayọlọ́lá àti ìdúró-déédéé lójú agbami òkun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ bí àkókò tí ó gba Nóà láti kan ọkọ̀ náà ṣe pọ̀ tó gẹ́lẹ́, àkọsílẹ̀ náà yọ̀ǹda nǹkan bí 50 tàbí 60 ọdún fún kíkan ọkọ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 5:32; 7:6) Àwọn kókó wọ̀nyí yàtọ̀ gedegbe sí ìtàn tí a mọ̀ dunjú nínú Ìtàn Akọni Gilgamesh ti Bábílónì. Ìtàn akọni náà ṣàpèjúwe àpótí onígun mẹ́rin ńlá kan, tí ó tóbi ní nǹkan bí 60 mítà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n kàn láàárín ọjọ́ méje péré. Láìdàbí ìtàn àtẹnudẹ́nu àwọn ará Bábílónì yẹn, àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa Àkúnya náà fàyè gba níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìpépérépéré rẹ̀.
Láìka àkọsílẹ̀ ti Jẹ́nẹ́sísì mọ́ ọn, Ìwé Mímọ́ tọ́ka sí Nóà tàbí Àkúnya kárí ayé náà nígbà mẹ́wàá. Ǹjẹ́ àwọn ìtọ́kasí wọ̀nyí fi hàn pé àwọn olùṣàkọsílẹ̀ tí a mí sí náà fojú wo Ìkún Omi náà bí ojúlówó ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí bí ìtàn àròsọ bí?
A Fẹ̀rí Ìjójúlówó Rẹ̀ Múlẹ̀
Nínú Ìwé Mímọ́, Nóà fara hàn nínú ìtàn méjì nípa ìlà ìdílé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, tí èkejì sì jẹ́ nípa ìbí Jésù Kristi. (Kíróníkà Kíní 1:4; Lúùkù 3:36) Ẹ́sírà àti Lúùkù, àwọn méjèèjì tí wọ́n ṣàkójọ àwọn ìtàn ìlà ìdílé wọ̀nyí, jẹ́ òpìtàn onímọ̀ iṣẹ́, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ti gbà gbọ́ pé Nóà jẹ́ ẹni gidi kan.
Níbòmíràn nínú Bíbélì, a to Nóà mọ́ àwọn ẹ̀dá inú ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀, ní dídárúkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olódodo àti onígbàgbọ́. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 14:14, 20; Hébérù 11:7) Yóò ha bọ́gbọ́n mu fún àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láti fi orúkọ ẹni ìtàn àròsọ kan kún àpẹẹrẹ tí ó yẹ kí a tẹ̀ lé bí? Rárá, nítorí pé èyí lè fìrọ̀rùn mú kí àwọn tí ń ka Bíbélì parí èrò sí pé ìgbàgbọ́ kọjá agbára àwọn ẹ̀dá ènìyàn, àti pé, àwọn ẹ̀dá inú ìwé ìtàn nìkan ni wọ́n lè fi í hàn. A dárúkọ Nóà àti àwọn ọkùnrin àti obìnrin mìíràn nítorí pé wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn aláìlera àti onímọ̀lára bíi tiwa.—Hébérù 12:1; fi wé Jákọ́bù 5:17.
Nínú àwọn ìtọ́kasí tó kù nínú Ìwé Mímọ́, a tọ́ka sí Nóà àti Ìkún Omi náà nínú àyíká ọ̀rọ̀ nípa ìparun tí Ọlọ́run mú wá sórí ìran aláìnígbàgbọ́ tí ó yí Nóà ká. Ṣàkíyèsí bí Jésù ṣe tọ́ka sí Àkúnya náà, bí a ṣe kọ ọ́ sílẹ̀ nínú Lúùkù 17:26, 27 pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò rí pẹ̀lú ní àwọn ọjọ́ Ọmọkùnrin ènìyàn: wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ yẹn nígbà tí Nóà wọ inú ọkọ̀ áàkì, ìkún omi sì dé, ó sì pa gbogbo wọn run.”
Jésù Kristi jẹ́ ẹlẹ́rìí olùfojúrí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣàpèjúwe náà, nítorí pé ó ti wà ní ọ̀run ṣáájú kí ó tóó wáá gbé orí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 8:58) Bí Àkúnya náà bá ti jẹ́ àròsọ lásán ni, ó ní láti jẹ́ pé, bóyá Jésù ń dọ́gbọ́n sọ pé wíwàníhìn-ín òun lọ́jọ́ iwájú jẹ́ àfinúrò, tàbí kí ó jẹ́ pé irọ́ ló ń pa. Kò sí ọ̀kankan nínú èrò méjèèjì tí ó bára mu pẹ̀lú àwọn apá yòó kù nínú Ìwé Mímọ́. (Pétérù Kíní 2:22; Pétérù Kejì 3:3-7) Nítorí náà, Jésù Kristi gbà gbọ́ pé àkọsílẹ̀ inú Bíbélì nípa Ìkún Omi yí ká ayé náà jẹ́ ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, nítorí pé ó jẹ́ ohun tí òun fúnra rẹ̀ fojú rí. Fún àwọn Kristẹni tòótọ́, láìsí iyè méjì, èyí ni ẹ̀rí tí ó fòòté lé e jù lọ pé Ìkún Omi ọjọ́ Nóà jẹ́ òtítọ́, kì í ṣe àròsọ.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
L. Chapons/Illustrirte Familien-Bibel nach der deutschen Uebersetzung Dr. Martin Luthers