Ẹ̀KỌ́ 24
Lílo Èdè Tó Dára
Ọ̀RỌ̀ jẹ́ ohun èlò alágbára tí a fi ń gbé èrò ọkàn ẹni jáde fáyé gbọ́. Ṣùgbọ́n kí a tó lè fi ọ̀rọ̀ wa ṣe ohun pàtó kan, a óò ní láti fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tí a ó lò. Ọ̀rọ̀ kan tó yẹ gẹ́lẹ́ lákòókò kan lè má wọ̀ rárá nínú ipò mìíràn tó yàtọ̀. Gbólóhùn ọ̀rọ̀ kan tó dùn mọ̀ràn-ìn mọran-in lè lọ di “ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora” béèyàn bá lò ó lọ́nà tí kò tọ́. Ó lè jẹ́ pé ẹni tó ṣi irú gbólóhùn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lò kò kàn ronú dáadáa kó tó lò ó ni, tó fi hàn pé kò gba tẹlòmíràn rò. Àwọn ọ̀rọ̀ kan ní ìtumọ̀ oríṣi méjì, ọ̀kan nínú rẹ̀ lè jẹ́ èébú tàbí ọ̀rọ̀ àbùkù. (Òwe 12:18; 15:1) Àmọ́, “ọ̀rọ̀ rere,” ìyẹn ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí, máa ń mú ọ̀kan ẹni tí a sọ ọ́ sí yọ̀ ni. (Òwe 12:25) Ó gba ìsapá kí èèyàn tó lè rí ọ̀rọ̀ yíyẹ lò, àní béèyàn bá tiẹ̀ jẹ́ ọlọgbọ́n pàápàá. Bíbélì sọ fún wa pé Sólómọ́nì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì láti ṣàwárí “àwọn ọ̀rọ̀ dídùn” àti “àwọn ọ̀rọ̀ títọ̀nà tí ó jẹ́ òtítọ́.”—Oníw. 12:10.
Ní àwọn èdè kan, àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́nlé wà tí a máa ń lò fún àwọn àgbà tàbí ẹni tó bá wà nípò àṣẹ, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn sì wà fún àwọn tó bá jẹ́ ojúgbà ẹni tàbí àwọn tí a jù lọ. Ìwà láìfí ni àwọn elédè bẹ́ẹ̀ máa ń ka àìlo èdè àpọ́nlé yìí sí. Kò sì bójú mu tó láti máa fi èdè ọ̀wọ̀ tí àṣà ìbílẹ̀ kan gbà pé a máa ń lò fún àwọn ẹlòmíràn pe ara ẹni. Ní ti ká bọ̀wọ̀ fúnni, Bíbélì fún wa ni ìlànà tó ga ju èyí tí òfin tàbí àṣà ìbílẹ̀ là kalẹ̀ lọ. Ó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo.” (1 Pét. 2:17) Àwọn tó bá ń ṣe èyí látọkànwá yóò máa bá tọmọdé tàgbà sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀.
A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni tòótọ́ ló máa ń lo èdè aṣa tí wọ́n sì máa ń sọ àsé ọ̀rọ̀. Wọ́n lè máa rò pé lílo irú èdè aṣa àti sísọ àsé ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa túbọ̀ gbé ohun tí wọ́n fẹ́ sọ yọ dáadáa. Lílò tí wọ́n ń lò ó sì lè jẹ́ àmì tó ń fi hàn pé wọn kò ní àkójọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀ tó lágbárí. Bí ìlò irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ bá ti mọ́ ẹnì kan lára kó tó di pé ó kọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà, ó lè ṣòro fún un láti jáwọ́ nínú àṣà yẹn. Síbẹ̀ ó ṣì lè jáwọ́ ńbẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọ́run lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti yí ọ̀nà ìgbàsọ̀rọ̀ rẹ̀ padà. Àmọ́, onítọ̀hún ní láti fúnra rẹ̀ fẹ́ láti wá àwọn ọ̀rọ̀ tó dára sínú àkójọ ọ̀rọ̀ tó mọ̀ ságbárí, ìyẹn àwọn ọ̀rọ̀ tó ń ṣeni lóore, tó dára fún gbígbéniró, kí ó sì máa lò wọ́n déédéé.—Róòmù 12:2; Éfé. 4:29; Kól. 3:8.
Èdè Tó Ń Tètè Yéni. Kókó kan tó ṣe pàtàkì fún ọ̀rọ̀ tá a sọ dáadáa ni pé kó tètè yéni. (1 Kọ́r. 14:9) Bí ọ̀rọ̀ tí o lò kò bá fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn olùgbọ́ rẹ, o lè dà bí ẹni tó ń sọ èdè àjèjì létí wọn.
Àwọn ọ̀rọ̀ kan jẹ́ èdè ìjìnlẹ̀ tí àwọn tó ń ṣe irú iṣẹ́ pàtó kan máa ń lò láàárín ara wọn. Irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lè ti di èyí tí wọ́n ń lò lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n tí o bá lo irú ọ̀rọ̀ yẹn láwùjọ tó yàtọ̀, àwọn èèyàn lè má mọ ìtumọ̀ ohun tó ò ń sọ rárá. Síwájú sí i, ká tiẹ̀ wá sọ pé o lo ọ̀rọ̀ tí gbogbo èèyàn ń lò, ṣùgbọ́n tó o bá lọ ń ṣe ọ̀rínkinniwín ìlò ọ̀rọ̀, tó ò ń ránnu mọ́ ọn, ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ lè ṣí kúrò níbi ọ̀rọ̀ rẹ, kí wọ́n máa ro nǹkan mìíràn.
Olùbánisọ̀rọ̀ tó ń gba tẹni rò máa ń lo èdè tó máa yé ọ̀mọ̀wé àti púrúǹtù. Yóò ṣe bíi ti Jèhófà nípa gbígba ti “ẹni rírẹlẹ̀” rò. (Jóòbù 34:19) Bí ó bá wá di dandan pé kí olùbánisọ̀rọ̀ ọ̀hún lo ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ kan, á dáa kó fi àwọn gbólóhùn tó rọrùn gbá a lẹ́gbẹ̀ẹ́ láti mú kí àwùjọ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.
Bí a bá ń lo ọ̀rọ̀ tó tètè yéni, ó máa ń gbé èrò tá a ní lọ́kàn yọ lọ́nà tó lágbára. Àwọn gbólóhùn kúkúrú àti àpólà ọ̀rọ̀ tí kò lọ́jú pọ̀ máa ń tètè yéni. A lè fi wọ́n há àárín àwọn gbólóhùn tó gùn kó má di pé a kàn ń gé ọ̀rọ̀ kú-kù-kú. Ṣùgbọ́n ní ti èrò tí ò ń fẹ́ kí àwùjọ rántí ní pàtàkì, ńṣe ni kí o máa fi gbólóhùn tó rọrùn tó sì ṣe ṣàkó sọ ọ́.
Lílo Oríṣiríṣi Ọ̀rọ̀ Tó Bá A Mu Rẹ́gí. Ọ̀rọ̀ tó dára pọ̀ rẹpẹtẹ. Nípa bẹ́ẹ̀, dípò tí wàá fi máa lò ọ̀rọ̀ kan náà ní onírúurú ipò, kúkú máa lo oríṣiríṣi ọ̀rọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ rẹ á lè lárinrin, á sì nítumọ̀. Báwo ni wàá ṣe mú kí ọ̀rọ̀ tí o mọ̀ pọ̀ sí i?
Nígbà tí o bá ń kàwé, sàmì sí ọ̀rọ̀ tí o bá sáà ti rí pé kò fi bẹ́ẹ̀ yé ọ, kí o sì wò ó nínú ìwé atúmọ̀ èdè, tó bá wà ní èdè rẹ. Wá mú díẹ̀ lára ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, kí o sì dìídì gbìyànjú láti máa lò wọ́n nígbà tó bá yẹ. Rí i dájú pé ò ń pè wọ́n bó ṣe tọ́, àti pé o lò wọ́n níbi tí wọ́n ti bá àlàyé ọ̀rọ̀ mu, tí yóò sì lè tètè yéni láìjẹ́ pé ó kàn gbàfiyèsí lásán. Bí o bá mú kí ọ̀rọ̀ tí o mọ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, wàá lè máa gbé ọ̀rọ̀ rẹ jókòó lóríṣiríṣi ọ̀nà. Ṣùgbọ́n ó gba kéèyàn ṣọ́ra o, nítorí pé, bí èèyàn bá ń ṣi ọ̀rọ̀ pè tàbí tí ó ń ṣi ọ̀rọ̀ lò, àwọn èèyàn lè gbà pè ohun tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí ni kò fí bẹ́ẹ̀ yé e.
Ìdí tí a fi ń mú kí ọ̀rọ̀ tí a mọ̀ pọ̀ sí i ni pé ká fi lè máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yéni, kì í ṣe láti máa fi ṣe fọ́rífọ́rí fún àwọn tó ń gbọ́ wa. Bí olùbánisọ̀rọ̀ bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó lọ́jú pọ̀, tàbí tí ó ń lo gbólóhùn gígùn, òun alára lọ̀rọ̀ náà sábà máa ń pàfiyèsí sí. Ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún ni pé ká sọ ohun tá a mọ̀, tó lè ṣaráyé láǹfààní, kí a sì sọ ọ́ lọ́nà tí yóò fi dùn mọ́ àwọn tó bá gbọ́ ọ. Rántí òwe Bíbélì pé: “Ahọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń lo ìmọ̀ lọ́nà rere.” (Òwe 15:2) Lílo ọ̀rọ̀ rere, ọ̀rọ̀ yíyẹ tó sì ń tètè yéni, máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ tí a sọ tuni lára kó sì tani jí, kì í sì í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ falẹ̀ kí ó sì súni.
Bí o ṣe ń mú kí ọ̀rọ̀ tó o mọ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, kíyè sára pé ọ̀rọ̀ tó yẹ kí o lò ni o ń lò. Ọ̀rọ̀ méjì lè ní ìtumọ̀ tó jọra wọn ṣùgbọ́n kí ìtumọ̀ wọ́n fi díẹ̀ yàtọ̀ síra tí a bá lò wọ́n nínú oríṣiríṣi gbólóhùn. Bí o bá mọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀, wàá lè túbọ̀ mú kí ọ̀rọ̀ rẹ yéni kedere, kò sì ní gbòdì létí àwọn olùgbọ́ rẹ. Máa tẹ́tí sí àwọn tó jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀. Àwọn ìwé atúmọ̀ èdè kan máa ń kọ ọ̀rọ̀, wọ́n á wá to àwọn ọ̀rọ̀ tí a tún lè lò dípò rẹ̀ sábẹ́ rẹ̀ (ìyẹn àwọn tí ìtumọ̀ wọ́n jọra bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè máà bára dọ́gba) wọ́n á sì tún to àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ ìdà kejì rẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú. Wàá tipa bẹ́ẹ̀ lè rí onírúurú ìtumọ̀ tí ọ̀rọ̀ kan ní àti oríṣiríṣi ọ̀nà tó o lè gbà sọ ọ̀rọ̀ náà. Èyí máa ń wúlò gan-an nígbà tí o bá ń wá ọ̀rọ̀ tó tọ́ láti lò fún àsìkò kan pàtó. Kí o tó fi ọ̀rọ̀ kan kún àwọn ọ̀rọ̀ tó o mọ̀, rí i dájú pé o mọ ìtumọ̀ rẹ̀, kí o mọ bí wọ́n ṣe ń pè é, àti ìgbà tí ó tọ́ láti lò ó.
Àwọn gbólóhùn tó ṣe pàtó máa ń mú ọ̀rọ̀ ṣe kedere ju ká kàn kó ọ̀rọ̀ pọ̀ ní gbogbo gbòò lọ. Olùbánisọ̀rọ̀ kan lè sọ pé: “Ní ìgbà yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ṣàìsàn.” Ó sì tún lè sọ pé: “Láàárín oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, nǹkan bíi mílíọ̀nù mọ́kànlélógún èèyàn ni àrùn gágá pa.” Ẹ ò ri bí òye ọ̀rọ̀ yẹn ṣe kún rẹ́rẹ́ tó sì túbọ̀ yéni nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ yìí ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn tí ó fi lo gbólóhùn náà, “ní ìgbà yẹn,” “ọ̀pọ̀ èèyàn,” àti “ṣàìsàn”! Láti lè ṣàlàyé ara rẹ lọ́nà yìí á gba pé kí o mọ àwọn nǹkan pàtàkì tó rọ̀ mọ́ kókó ọ̀rọ̀ tí ò ń sọ, kí o sì tún fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tó yẹ láti fi gbé e yọ.
Lílo ọ̀rọ̀ tí ó tọ́ sì tún lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọjú abẹ níkòó láìsọ̀rọ̀ lọ jàn-àn-ràn. Àpọ̀jù ọ̀rọ̀ máa ń bo èrò mọ́lẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tó mọ níwọ̀n a máa jẹ́ kí kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ tètè yéèyàn kí èèyàn má sì gbàgbé. Ó máa ń mú kí á lè kọ́ni ní ìmọ̀ pípéye. Èdè rírọrùn tí Jésù Kristi lò láti fi kọ́ni mú kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ta yọ lọ́lá. Fi tirẹ̀ ṣe àwòkọ́ṣe. (Wo àwọn àpẹẹrẹ tó wà lákọsílẹ̀ nínú Mátíù 5:3-12 àti Máàkù 10:17-21.) Kọ́ bí a ṣe ń lo ọ̀rọ̀ tí ń gbé ìtumọ̀ yọ láti fi ṣàlàyé ara rẹ lọ́nà tó ṣe ṣàkó.
Lílo Ọ̀rọ̀ Tó Ń Tani Jí, Ọ̀rọ̀ Tó Ń Fi Bí Nǹkan Ṣe Rí Lára Hàn, àti Ọ̀rọ̀ Àpọ́nlé. Bí o ṣe ń mú kí ọ̀rọ̀ tí o mọ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i, má kàn máa ronú nípa ọ̀rọ̀ tuntun nìkan, tún máa ronú nípa ọ̀rọ̀ tó máa ń ṣe iṣẹ́ kan pàtó nínú gbólóhùn. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ ìṣe tó máa ń tani jí; àwọn ọ̀rọ̀ aṣàpèjúwe tí a fi ń pọ́n nǹkan lé; àti àwọn gbólóhùn tó ń fi ọ̀yàyà, ọ̀rọ̀ onínúure, tàbí ìtara ọkàn hàn.
Àpẹẹrẹ irú àwọn ọ̀rọ̀ tí ń gbé ìtumọ̀ yọ bẹ́ẹ̀ pọ̀ nínú Bíbélì. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Ámósì rọ àwọn èèyàn pé: “Ẹ máa wá ohun rere, kì í sì í ṣe ohun búburú . . . Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere.” (Ámósì 5:14, 15) Wòlíì Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù Ọba pé: “Jèhófà ti fa ìṣàkóso ọba Ísírẹ́lì ya kúrò lọ́wọ́ rẹ lónìí.” (1 Sám. 15:28) Nígbà tí Jèhófà ń bá Ìsíkíẹ́lì sọ̀rọ̀, ó lo èdè tí kò ṣeé gbàgbé bọ̀rọ̀, ó ní: “Gbogbo ilé Ísírẹ́lì jẹ́ kìígbọ́-kìígbà àti ọlọ́kàn-líle.” (Ìsík. 3:7) Láti tẹnu mọ́ bí ìwà àìtọ́ tí Ísírẹ́lì hù ṣe burú tó, Jèhófà béèrè pé: “Ará ayé yóò ha ja Ọlọ́run lólè bí? Ṣùgbọ́n ẹ ń jà mí lólè.” (Mál. 3:8) Nígbà tí Dáníẹ́lì ń ṣàpèjúwe ìdánwò ìgbàgbọ́ tó bá wọn ní Bábílónì, ó lo ọ̀rọ̀ tó gbé e yọ kedere pé, “Nebukadinésárì kún fún ìbínú kíkan” nítorí pé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò kò sin ère rẹ̀, ó wá pàṣẹ pé kí àwọn abarapá ọkùnrin rẹ̀ dè wọ́n kí wọ́n sì sọ wọ́n sínú “ìléru oníná tí ń jó.” Láti jẹ́ kí á mọ bí ó ṣe gbóná janjan tó, Dáníẹ́lì sọ pé ọba ní kí àwọn èèyàn rẹ̀ “mú ìléru náà gbóná ní ìgbà méje ju bí a ti sábà máa ń mú un gbóná,” tó fi gbóná débí pé ìléru yẹn pa àwọn ọkùnrin ọba nígbà tí wọ́n sún mọ́ ọn. (Dán. 3:19-22) Nígbà tí Jésù ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ ní Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀, ó sọ bí ọ̀ràn kan ṣe ká a lára gidigidi tó, ó ní: “Iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀! Ṣùgbọ́n ẹ kò fẹ́ ẹ. Wò ó! A pa ilé yín tì fún yín.”—Mát. 23:37, 38.
Tí o bá fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ tó yẹ láti lò, yóò mú kí àwọn olùgbọ́ rẹ lè fojú inú rí ohun tí ò ń sọ. Bí o bá lo ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwòrán nǹkan wá síni lọ́pọlọ, àwọn olùgbọ́ rẹ yóò “rí” àwọn nǹkan tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí, wọ́n á sì “fọwọ́ kàn án,” wọ́n á “tọ́” oúnjẹ tí o sọ wò, wọ́n á sì “gbóòórùn” rẹ̀, wọ́n á “gbọ́” àwọn ìró tí ò ń ṣàpèjúwe àti ohùn àwọn èèyàn tí o fa ọ̀rọ̀ wọn yọ. Tọkàn tara làwùjọ yóò máa fi gbọ́ ohun tí ò ń sọ nítorí pé o sọ ọ́ lọ́nà tó fi dà bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ lọ́kàn tàwọn náà.
Ọ̀rọ̀ tó bá fi bí nǹkan ṣe rí gan-an hàn kedere lè mú kí àwọn èèyàn rẹ́rìn-ín tàbí kí wọ́n sunkún. Ó lè múni nírètí, kí ó mú kí ìgbésí ayé tún wu ẹni tí ayé ti sú tẹ́lẹ̀, kí ó sì mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Jákèjádò ayé ni a ti rí àwọn èèyàn tí ìgbésí ayé wọn ti yí padà gidigidi nítorí ìrètí tí ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Bíbélì bíi Sáàmù 37:10, 11, 34; Jòhánù 3:16; àti Ìṣípayá 21:4, 5, gbìn sí wọn lọ́kàn.
Bí o ṣe ń ka Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” wàá máa rí oríṣiríṣi ìlò ọ̀rọ̀ àti àpólà ọ̀rọ̀ tó pọ̀. (Mát. 24:45) Má kàn kà wọ́n kí o sì mọ́kàn kúrò lára wọn. Mú àwọn ọ̀rọ̀ tó wù ọ́ níbẹ̀, kí o sì fi wọ́n kún àkójọ ọ̀rọ̀ tí ò ń lò lójoojúmọ́.
Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Bá Òfin Gírámà Èdè Mu. Àwọn kan rí i pé lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀nà tí àwọn ń gbà sọ̀rọ̀ lè máà bá òfin gírámà èdè tí wọ́n ń sọ mu. Kí wá ni irú wọn lè ṣe nípa rẹ̀?
Bí o bá ṣì wà ní ilé ẹ̀kọ́, lo àǹfààní yẹn nísinsìnyí láti fi kọ́ bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó bá òfin gírámà èdè mu àti bí a ṣe ń fara balẹ̀ yan ọ̀rọ̀ láti fi gbé èrò ọkàn ẹni jáde. Bí ìdí tí òfin gírámà èdè kan fi wà bí ó ṣe wà kò bá yé ọ, bi olùkọ́ rẹ̀ léèrè nípa rẹ̀. Má kàn kọ́ ìwọ̀nba tó di dandan pé kí o sáà mọ̀ nìkan. O ní ètè pàtó tí o fẹ́ lò ó fún, èyí tó jẹ́ pé àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ rẹ yòókù lè máà ní. Ńṣe ni ìwọ fẹ́ jẹ́ òjíṣẹ́ tí ń polongo ìhìn rere lọ́nà tó múná dóko.
Ká wá ní o ti dàgbà kọjá ẹni tó ń lọ ilé ẹ̀kọ́, bẹ́ẹ̀ sì rèé, èdè tí o sọ dàgbà yàtọ̀ sí èyí tí o wá ń sọ nísinsìnyí ńkọ́? Tàbí bóyá o kò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ láǹfààní láti kọ́ nípa èdè rẹ ní ilé ẹ̀kọ́. Má rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí o máa sapá lójú méjèèjì láti tẹ̀ síwájú sí i, kí o ṣe ìsapá yìí nítorí ìhìn rere. Ọ̀pọ̀ jù lọ ohun tí a máa ń mọ̀ nípa ọ̀nà tí ó tọ́ láti gbà sọ̀rọ̀ ní èdè kan ló jẹ́ pé nípa fífetí sí bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ la fi ń mọ̀ ọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́ bá ń sọ̀rọ̀. Nígbà tí o bá ń ka Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, máa fojú sí bí a ṣe gbé àwọn gbólóhùn inú rẹ̀ kalẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò pa pọ̀, àti inú àlàyé ọ̀rọ̀ tí a ti lò wọ́n. Máa fara wé àwọn àpẹẹrẹ dáadáa wọ̀nyí nígbà tí o bá ń sọ̀rọ̀.
Àwọn gbajúgbajà eléré àtàwọn olórin lè lo àwọn gbólóhùn kan tàbí kí wọ́n sọ̀rọ̀ lọ́nà kan tó lòdì sí ìlò tí ó bá gírámà èdè yẹn mu. Àwọn èèyàn sì sábà máa ń gba àṣà irú àwọn ẹni yẹn. Àwọn tó ń ta oògùn olóró àtàwọn mìíràn tó jẹ́ pé ìgbésí ayé ọ̀daràn tàbí ti oníṣekúṣe ni wọ́n ń gbé sábà máa ń ní àwọn àkànlò ọ̀rọ̀ tiwọn, tí wọ́n á sì fún àwọn ọ̀rọ̀ ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ pátápátá sí ìtumọ̀ tí gbogbo gbòò mọ̀. Kò bọ́gbọ́n mú pé kí Kristẹni fara wé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìyẹn á mú kí á jẹ́ ọ̀rẹ́ irú àwọn ẹni ayé bẹ́ẹ̀ kí á sì fìwà jọ wọ́n.—Jòh. 17:16.
Fi kọ́ra láti máa lo èdè tó dára nínú ọ̀rọ̀ sísọ rẹ lójoojúmọ́. Tí o kì í báá lo èdè tó dára lójoojúmọ́, má ṣe retí pé wàá lè máa sọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́ ní àwọn ibi pàtàkì. Ṣùgbọ́n tí o bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára nígbà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ ojoojúmọ́, ńṣe lọ̀rọ̀ á kàn máa wá sí ọ lẹ́nu wẹ́rẹ́ bó ṣe yẹ nígbà tí o bá gorí pèpéle tàbí tí o bá ń wàásù fún àwọn èèyàn nípa òtítọ́.