‘Ẹ Jẹ́ Kí Àsọjáde Yín Máa Fìgbà Gbogbo Jẹ́ Èyí tí A Fi Iyọ̀ Dùn’
1. Kí ló túmọ̀ sí láti máa ‘fi iyọ̀ dun’ àwọn “àsọjáde” wa?
1 “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kól. 4:6) Fífi iyọ̀ dun ọ̀rọ̀ wa túmọ̀ sí pé ká máa lo ọ̀rọ̀ tó yẹ, ká sì máa sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa dùn-ún gbọ́ létí. Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.
2. Kí ló jẹ́ kí Jésù lè wàásù fún obìnrin ará Samáríà kan?
2 Àwòkọ́ṣe Jésù: Nígbà tó ń sinmi lẹ́gbẹ̀ẹ́ kànga, Jésù lo ìdánúṣe láti bá obìnrin ará Samáríà kan tó wá pọnmi sọ̀rọ̀. Nígbà tí ìjíròrò náà ń lọ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ìgbà lobìnrin yẹn ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ awuyewuye tó ti wà tipẹ́tipẹ́ láàárín àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà. Ó tún sọ ohun tó gbà gbọ́ pé Jákọ́bù ni baba ńlá àwọn ará Samáríà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù nígbàgbọ́ tó lágbára pé ọmọ ilẹ̀ òkèèrè làwọn ará Samáríà. Dípò kí Jésù máa tako àwọn ọ̀rọ̀ obìnrin yẹn, ńṣe ló fèsì lọ́nà tó gbéni ró. Ìyẹn jẹ́ kí ìwàásù Jésù ran obìnrin yẹn àtàwọn aráàlú náà lọ́wọ́.—Jòh. 4:7-15, 39.
3. Báwo la ṣe lè fara wé Jésù tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
3 Bá a ti ń wàásù, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ohun tá a fojú sùn, ìyẹn ni láti “polongo ìhìn rere àwọn ohun rere.” (Róòmù 10:15) Àwọn nǹkan tó ń gbéni ró tó sì fani lọ́kàn mọ́ra látinú Bíbélì la fẹ́ máa sọ fẹ́ni tá a bá ń wàásù fún, a ò fẹ́ kó máa rò pé ńṣe la wá ta ko àwọn ohun tó gbà gbọ́. Bó bá sọ ohun kan tí kò tọ̀nà, a ò ní láti ta kò ó. Ṣé ohun kan wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a lè fara mọ́, tàbí tá a lè fi gbóríyìn fún un látọkànwá? A tiẹ̀ lè tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ nípa sísọ pé, “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ rò pé ohun tó wà níbí yìí ṣeé ṣe?”
4. Kí ló yẹ ká ṣe bí onílé bá ya ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú?
4 Bí onílé yẹn bá wá ya ẹlẹ́ẹ̀kẹ́ èébú ńkọ́, tàbí tá a rí i kedere pé ńṣe ló fẹ́ máa ṣàtakò? A gbọ́dọ̀ máa báa nìṣó láti ní sùúrù ká sì tún jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa. (2 Tím. 2:24, 25) Bí ẹnì kan ò bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà, ohun tó máa dáa ni pé ká dọ́gbọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀.—Mát. 7:6; 10:11-14.
5. Báwo ni ìrírí arábìnrin kan ṣe fi hàn pé èsì ọmọlúwàbí sábà máa ń mú àbájáde rere wá?
5 Àbájáde Rere: Nígbà tí arábìnrin kan fẹ́ wàásù fún aládùúgbò rẹ̀ kan, ńṣe lobìnrin náà gbaná jẹ, ó dà á sáriwo, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣépè. Arábìnrin wa fi pẹ̀lẹ́tù fèsì pé: “Jọ̀ọ́, má bínú, mi ò mọ̀ pé bó ṣe máa rí lára ẹ nìyẹn. A óò máa ríra nígbà míì.” Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn ìgbà náà lobìnrin yẹn wá sọ́dọ̀ arábìnrin wa láti tọrọ àforíjì tó sì sọ pé òún fẹ́ gbọ́ ohun tí arábìnrin náà ní í sọ báyìí. Ẹ ò rí i pé èsì ọmọlúwàbí sábà máa ń mú àbájáde rere wá!—Òwe 15:1; 25:15.
6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa dùn-ún gbọ́ létí tá a bá wà lóde ẹ̀rí?
6 Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ máa dùn-ún gbọ́ létí nígbà tó o bá ń wàásù ìhìn rere náà. Bí onílé ò bá tiẹ̀ fẹ́ tẹ́tí sí wa lọ́jọ́ yẹn, ìyẹn lè mú kó fetí sílẹ̀ nígbà míì táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀.