Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Jan. 1
“Ṣó o gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? [Ka Jákọ́bù 3:2.] Àpilẹ̀kọ yìí fún wa ní àwọn àbá tó wúlò látinú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ bí ọ̀rọ̀ ẹnu wa ò ṣe ní máa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ará ilé wa.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ile Iṣọ Feb. 1
“Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìṣòro tá a ní nínú ayé lónìí, ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kí ọkàn èèyàn balẹ̀ lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Ríronú lórí àwọn ohun tí Bíbélì ní ká máa retí lọ́jọ́ ọ̀la ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́. [Ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí tàbí èyí tá a fa ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ yọ nínú àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ fi lọ onílé.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ibi tá a ti wá, ìdí tá a fi wà láyé, àti bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí fún wa.”
Jí! Jan.–Mar.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé ayé wọn bí wọ́n ṣe rò pé ó dáa jù lọ, wọ́n gbà pé ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn jẹ́ ẹni rere. Ṣé bí ìwọ náà ṣe rí i nìyẹn? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo ewu tó lè tìdí ẹ̀ yọ tí èrò wa nípa ohun rere bá yàtọ̀ sí ti Ọlọ́run. [Ka Òwe 14:12.] Àpilẹ̀kọ yìí sọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ẹni rere lójú Ọlọ́run.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 8 hàn án.
“Gbogbo ìgbéyàwó ló ní ìṣòro tiẹ̀. Níbo lo rò pé àwọn tọkọtaya ti lè rí ìmọ̀ràn tó wúlò? [Jẹ́ kó fèsì.] Wo àbá tó wúlò yìí. [Ka Éfésù 5:22, 25.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tó túmọ̀ sí fún aya kan láti máa tẹrí ba fún ọkọ rẹ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 16 hàn án.