Ṣé Ìdílé Rẹ Ń Múra Sílẹ̀ Láti Là Á Já?
1 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń nímùúṣẹ túbọ̀ ń fi ẹ̀rí tó dájú hàn pé ayé búburú yìí ò ní pẹ́ kọjá lọ. À ń gbé lákòókò tó le koko bí irú èyí tó wà ṣáájú Ìkún Omi. (Mát. 24:37-39) Nóà la ìparun tó wá sórí ayé nígbà yẹn já nítorí pé ó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Jẹ́n. 6:9) Ó dájú pé Nóà ti ní láti fi ohun tí Jèhófà ń béèrè kọ́ ìdílé rẹ̀ nítorí pé àwọn náà là á já. Báwo la ṣe lè fara wé Nóà ní mímúra sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé ká lè la òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí já?
2 Oníwàásù Òdodo: Fún nǹkan bí ogójì sí àádọ́ta ọdún ni Nóà fi forí tì í gẹ́gẹ́ bí “oníwàásù òdodo.” (2 Pét. 2:5) Ó dájú pé àwọn alájọgbáyé Nóà ti ní láti fi í ṣe yẹ̀yẹ́ nígbà tó ń wàásù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ tó gbé ara èèyàn wọ̀ ló mú kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Báwọn èèyàn ṣe ń dágunlá tí wọ́n sì ń pẹ̀gàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ tá à ń ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ti dé tán. (2 Pét. 3:3, 4) Àmọ́, òdìkejì ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Nóà ló ń ṣẹlẹ̀ báyìí, nítorí ọ̀pọ̀ ló ń dáhùn padà sí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe tí wọ́n sì ń “wọ́ tìrítìrí” wá sínú ìjọsìn Jèhófà. (Aísá. 2:2) A máa “gba ara [wa] àti àwọn tí ń fetí sí [wa] là” kìkì tá ò bá juwọ́ sílẹ̀. (1 Tím. 4:16) Ẹ ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó fáwọn òbí láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ti jẹ́ kánjúkánjú tó lákòókò tá à ń gbé yìí nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ wọn!—2 Tím. 4:2.
3 Ó Ṣe “Bẹ́ẹ̀ Gẹ́ẹ́”: Nóà àti ìdílé rẹ̀ là á já nítorí pé wọ́n fara balẹ̀ tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà. (Jẹ́n. 6:22) Ó ṣe pàtàkì káwa náà “múra tán láti ṣègbọràn” sáwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Bíbélì àtèyí tí ẹrú olóòótọ́ ń fún wa. (Ják. 3:17) Àwọn ọmọ tó ti dàgbà nínú ìdílé kan rántí bí Bàbá wọn ṣe máa ń lo àwọn àbá tí ètò Jèhófà ń fún wa. Bí àpẹẹrẹ, lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni Bàbá wọn máa ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé, ó sì máa ń jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn lópin ọ̀sẹ̀ bí ètò Ọlọ́run ti dábàá. Ó máa ń rí i pé òun bá ọ̀kan lára àwọn ọmọ náà ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Bó ṣe ń bá a nìṣó láti máa ṣe “bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́” ní ipa tó dáa lórí àwọn ọmọ rẹ̀, gbogbo àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà ló sì dàgbà di adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jèhófà.
4 Lójijì lòpin máa dé bá ètò àwọn nǹkan yìí. (Lúùkù 12:40) Bá a bá ń fara wé Nóà tá a sì gbà gbọ́ pé a máa ní ìgbàlà, ńṣe là ń fi hàn lóòótọ́ pé àwa àti ìdílé wa ti múra tán!—Héb. 11:7.