ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/08 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 9
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 16
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 23
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 30
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 6/08 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 9

Orin 121

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ June 1 àti Jí! April-June. (Lo abá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! April-June.)

20 min: Bá A Ṣe Lè Múra Sílẹ̀ Láti Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àsọyé tá a gbé ka Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù August 2004, ojú ìwé 1. Ní ìparí àsọyé yìí, ṣàṣefihàn bí akéde kan ṣe ń fìkánjú múra ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́ lọ darí. Lẹ́yìn èyí, ṣàṣefihàn bí akéde míì ṣe fara balẹ̀ múra sílẹ̀ nípa ṣíṣàyẹ̀wò bó ṣe máa lo àwọn àbá tó wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Máa Wàásù Láìdábọ̀.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Orin 201

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 16

Orin 90

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù June sílẹ̀. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n mú Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! April-June wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu.

15 min: Jẹ́ Kí Wọ́n Mọ Bí Ìhìn Rere Ṣe Wúlò Tó. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 159. Ní káwọn ará sọ ohun tó gba àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín lọ́kàn jù báyìí, kí wọ́n sì sọ bá a ṣe lè mú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ wa bá ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn mu.

20 min: “Ṣé Ìdílé Rẹ Ń Múra Sílẹ̀ Láti Là Á Já?”b Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Orin 54

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 23

Orin 140

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Sọ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa lò lóṣù July, kó o sì ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ọ̀kan nínú wọn.

20 min: Wọ́n Yan Ohun Tó Sàn Jù Nípa Ṣíṣe Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé. Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ January 15, 2008, ojú ìwé 17 sí 19. Bẹ́ ẹ bá láwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé nínú ìjọ yín, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn méjì, ọ̀kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ àti èyí tó ti ń sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ní kí wọ́n sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí gbà nítorí pé wọ́n yan iṣẹ́ ìsìn tó ṣeyebíye yìí.

15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fàwọn Ìwé Ìròyìn Tó Bá Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Lọni. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí Ilé Ìṣọ́ July 1 àti Jí! April-June, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tàbí ọ̀kan tí àwùjọ dámọ̀ràn láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan lọni. (O lè lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! April-June.)

Orin 82

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní June 30

Orin 97

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù June sílẹ̀. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n mú “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí” tá a fi ṣe àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2008 wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀.

20 min: Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 62, ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 64 ìpínrọ̀ 5. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Ní ṣókí, fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó mọ bá a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn nígbà tó bá ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí láìjẹ́-bí-àṣà.

15 min: Ǹjẹ́ O Rántí? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 15, 2008, ojú ìwé 29.

Orin 179

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 7

Orin 125

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Lo Ìwé Ọdọọdún Wa, Ìyẹn 2008 Yearbook, Lọ́nà Tó Dáa. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jíròrò “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí,” tá a fi ṣe àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù March 2008. Ní kẹ́ni méjì tàbí mẹ́ta sọ ìrírí tó fún wọn níṣìírí látinú ìwé ọdọọdún wa. Ṣètò pé kí ẹnì kan tàbí méjì tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ sọ bí wọ́n ṣe ṣètò láti máa ka ìwé ọdọọdún wa. Mú ọ̀rọ̀ rẹ wá sí ìparí nípa gbígba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n ka ìwé yìí láti páálí dé páálí.

20 min: “Bí Onílé Bá Ń Sọ Èdè Tó Yàtọ̀.”c Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó o. Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 2, jẹ́ káwọn ará mọ àwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè míì tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan náà. Sọ àwọn ètò tó wà nílẹ̀ tó máa jẹ́ káwọn àwùjọ tàbí ìjọ tó ń sọ èdè míì tẹ́ ẹ jọ ń wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan náà lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú yín.

Orin 188

[Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́