Orin 44
Máa Fìdùnnú Kópa Nínú Ìkórè Náà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Àǹfààní ńlá ni pé àwa wà
Láàyè ní ìgbà ìkórè.
Àwọn áńgẹ́lì lolùkórè;
A ńkópa nínú iṣẹ́ yìí.
Jésù Kristi fàpẹẹrẹ lélẹ̀
Ó ṣáájú wa nínú pápá.
Àǹfààní wa ló jẹ́ báa ṣe ńfayọ̀
Lọ́wọ́ nínú ìkórè náà.
2. Ìfẹ́ Ọlọ́run àti tèèyàn
Ńjẹ́ ká múra sí kíkórè.
Kánjúkánjú niṣẹ́ ìwàásù,
Torí òpin ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé.
Ayọ̀ tí a ńrí gbà pọ̀ púpọ̀;
Báa ti ńbá Ọlọ́run ṣiṣẹ́.
Ká máa ṣiṣẹ́ Ìjọba náà nìṣó
Ká mọ̀ pé òun yóò bù kún wa.
(Tún wo Mát. 24:13; 1 Kọ́r. 3:9; 2 Tím. 4:2.)