Orin 116
Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
(Òwe 4:18)
1. Àwọn wòlíì ìgbàanì ńfẹ́ mọ Kristi,
Ìrètí ẹ̀dà tó ńkérora.
Ẹ̀mí Ọlọ́run sọ pé Mèsáyà ńbọ̀,
Kí aráyé lè rí ìgbàlà.
Àkókò ti tó, Mèsáyà ti ńjọba,
Ẹ̀rí hàn pó ti wà níhìn-ín.
Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti mọ èyí;
Àwọn áńgẹ́lì gan-an ńbẹjú wòó!
(ÈGBÈ)
Ipa ọ̀nà wa ńmọ́lẹ̀ síi ni;
Ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gan-gan ni.
Wo nǹkan tí Ọlọ́run ńṣí payá;
Ó ńṣamọ̀nà wa lọ́nà rẹ̀.
2. Olúwa ti yan ẹrú olóòótọ́ kan,
Tó ńfún wa lóúnjẹ lákòókò gan-an.
Ìmọ́lẹ̀ òótọ́ ti túbọ̀ mọ́lẹ̀ síi.
Ó ńwọni lọ́kàn, ó bọ́gbọ́n mu.
Òye ńyé wa síi, ẹsẹ̀ wa ńmúlẹ̀ gbọn-in,
Ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán la fi ńrìn.
Ọpẹ́ ni fún Jáà, Orísun òtítọ́,
A ńfìmọrírì rìn lọ́nà rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ipa ọ̀nà wa ńmọ́lẹ̀ síi ni;
Ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gan-gan ni.
Wo nǹkan tí Ọlọ́run ńṣí payá;
Ó ńṣamọ̀nà wa lọ́nà rẹ̀.
(Tún wo Róòmù 8:22; 1 Kọ́r. 2:10; 1 Pét. 1:12.)