Orin 93
“Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jésù pàṣẹ pé kí
Ìmọ́lẹ̀ wa tàn,
Bí oòrùn tí ńtàn fún
Gbogbo aráyé.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńtan
Ìmọ́lẹ̀ ọgbọ́n.
Ká fìwà àtàtà gbé
Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yọ.
2. Ọ̀rọ̀ Ìjọba Jáà
Ńtànmọ́lẹ̀ sọ́kàn,
Ó ńmú ìtùnú wá,
Fáwọn tó ńṣọ̀fọ̀.
Ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀
Ńjẹ́ ká ṣèfẹ́ rẹ̀;
Ọ̀rọ̀ olóore ọ̀fẹ́,
Ńmú kó mọ́lẹ̀ síi.
3. Iṣẹ́ àtàtà ńtan
Ìmọ́lẹ̀ sáyé,
Ó ńmú kọ́rọ̀ wa máa
Tàn bíi péálì.
Kí’mọ́lẹ̀ wa máa tàn
Báa ti ń ṣo’un tó tọ́,
Yóò sì mú kí iṣẹ́ wa
Máa wu Ọlọ́run.
(Tún wo Sm. 119:130; Mát. 5:14, 15, 45; Kól. 4:6.)