Orin 40
Ẹ Máa Wá Ìjọba Náà Lákọ̀ọ́kọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Iyebíye fún Jèhófà,
Àní ayọ̀ ọkàn rẹ̀,
Ni Ìjọba Kristi Jésù,
Tí yóò tún gbogbo nǹkan ṣe.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Kéde ìyìn rẹ̀ fáyé gbọ́,
Kóo máa fìṣòtítọ́ sìnín.
2. Ẹ má ṣe ṣàníyàn ọ̀la
Kí ni aó jẹ kí laó mu?
Ọlọ́run wa yóò máa pèsè
Báa kọ́kọ́ ńwá ’jọba rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Kéde ìyìn rẹ̀ fáyé gbọ́,
Kóo máa fìṣòtítọ́ sìnín.
3. Ká kéde ìhìn Ìjọba.
Káwọn olùfẹ́ òótọ́
Mọ̀ pé Ìjọba Jèhófà
Nìkan ni ìrètí wọn.
(ÈGBÈ)
Ẹ kọ́kọ́ wá Ìjọba náà
Àtòdodo Jèhófà.
Kéde ìyìn rẹ̀ fáyé gbọ́,
Kóo máa fìṣòtítọ́ sìnín.
(Tún wo Sm. 27:14; Mát. 6:34; 10:11, 13; 1 Pét. 1:21.)