Orin 64
Sọ Òtítọ́ Di Tìrẹ
1. Ọ̀nà òtítọ́ ló dára jù láyé yìí,
Ìwọ ni yóò pinnu láti tọ̀ọ́.
Torí náà, máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà;
Gba gbogbo ohun tó sọ gbọ́.
(ÈGBÈ)
Sòótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ìṣe rẹ.
Wàá sì rí ayọ̀
Tí Jáà yóò fún ọ
Tóo bá sòótọ́ di tìrẹ.
2. Ìsapá pẹ̀lú àkókò rẹ tí ò ńlò
Fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Máa mú èrè wá pẹ̀lú ìyè àìlópin,
Láyé tuntun tí ó dé tán.
(ÈGBÈ)
Sòótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ìṣe rẹ.
Wàá sì rí ayọ̀
Tí Jáà yóò fún ọ
Tóo bá sòótọ́ di tìrẹ.
3. Ọmọdé ni wá láfiwé sí Ọlọ́run.
Ó yẹ ká máa gba ìmọ̀ràn rẹ̀.
Máa bá Baba wa ọ̀run rìn lójoojúmọ́;
Yóò sì bù kún ọ púpọ̀ gan-an.
(ÈGBÈ)
Sòótọ́ di tìrẹ.
Kó hàn nínú ìṣe rẹ.
Wàá sì rí ayọ̀
Tí Jáà yóò fún ọ
Tóo bá sòótọ́ di tìrẹ.
(Tún wo Sm. 26:3; Òwe 8:35; 15:31; Jòh. 8:31, 32.)