Orin 45
Ẹ Máa Tẹ̀ Síwájú!
1. Ẹ máa tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́!
Ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká di alágbára.
Túbọ̀ múra sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ,
Jáà yóò bù kún iṣẹ́ rẹ.
Iṣẹ́ gbogbo wa ni iṣẹ́ yìí.
Rántí pé Jésù náà ṣiṣẹ́ yìí.
Gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kóo má bàa ṣubú,
Dúró lórí òdodo.
2. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, fìgboyà jẹ́rìí!
Mú’hìn rere àìnípẹ̀kun tọ gbogbo èèyàn.
Jẹ́ ká jọ máa fìwàásù ilé-délé
Yin Jèhófà Ọba wa.
Àwọn ọ̀tá fẹ́ dẹ́rù bà wá.
Má bẹ̀rù, sọ ìhìn ayọ̀ fún
Gbogbo èèyàn pé Ìjọba Jáà bẹ̀rẹ̀.
Máa fòótọ́ kọ́ni nìṣó.
3. Ẹ máa tẹ̀ síwájú, tẹra mọ́ṣẹ́ náà.
Túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ torí iṣẹ́ pọ̀ láti ṣe.
Jẹ́ kẹ́mìí Ọlọ́run máa mú ọ ṣiṣẹ́.
Wàá rí ayọ̀ Ọlọ́run.
Fẹ́ràn àwọn tóo jàjà rí yìí.
Máa bẹ̀ wọ́n wò kóòtọ́ lè yé wọn.
Ṣèrànwọ́ kí wọ́n lè máa tẹ̀ síwájú,
Kímọ̀ọ́lẹ̀ òótọ́ lè tàn.
(Tún wo Fílí. 1:27; 3:16; Héb. 10:39.)