ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 20 ojú ìwé 147-ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 2
  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Àwùjọ Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 20 ojú ìwé 147-ojú ìwé 149 ìpínrọ̀ 2

Ẹ̀KỌ́ 20

Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o kọ́kọ́ múra ọkàn àwọn olùgbọ́ rẹ sílẹ̀ fún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o fẹ́ kà.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Nínasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́ lè jẹ́ kí àwùjọ lóye ìjẹ́pàtàkì ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yẹn gan-an.

ÌWÉ MÍMỌ́ là ń gbé àwọn ìtọ́ni tá à ń fúnni ní àwọn ìpàdé ìjọ wa kà. Ẹsẹ Bíbélì la sì máa ń pe àfiyèsí sí nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ lóde ẹ̀rí. Ṣùgbọ́n o, ipa tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ń kó nínú àlàyé ọ̀rọ̀ wa sinmi lórí bí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ṣe wọni lọ́kàn tó.

Kì í ṣọ̀ràn wíwulẹ̀ pe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, kí o sì sọ pé ẹ jẹ́ ká jọ kà á. Nígbà tó o bá ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́, gbìyànjú láti ṣe nǹkan méjì wọ̀nyí: (1) Fojú àwùjọ sọ́nà, kí o sì (2) pe àfiyèsí sí ìdí tó o fi fẹ́ ka ẹsẹ náà. Onírúurú ọ̀nà la lè gbà ṣe nǹkan wọ̀nyí.

Béèrè Ìbéèrè. Èyí máa ń gbéṣẹ́ gan-an bí kì í báá ṣe ìbéèrè tó jẹ́ pé kó o tó sọ ọ́ tán làwùjọ á ti mọ ìdáhùn rẹ̀. Rí i dájú pé o gbé ìbéèrè náà kalẹ̀ lọ́nà tó máa mú káwọn èèyàn ronú. Jésù ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà táwọn Farisí lọ bá Jésù nínú tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì fẹ́ dán an wò ní gbangba láti mọ bí òye Ìwé Mímọ́ ṣe yé e tó, Jésù bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀yin rò nípa Kristi? Ọmọkùnrin ta ni ó jẹ́?” Wọ́n fèsì pé: “Ti Dáfídì.” Jésù wá bi wọ́n pé: “Báwo wá ni ó ṣe jẹ́ tí Dáfídì nípasẹ̀ ìmísí fi pè é ní ‘Olúwa’?” Ẹ̀yìn ìyẹn ló wá fa ọ̀rọ̀ Sáàmù 110:1 yọ. Ńṣe lẹnu àwọn Farisí wọhò. Àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ni ogunlọ́gọ̀ náà fi ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù.—Mát. 22:41-46.

Ní òde ẹ̀rí, o lè lo àwọn ìbéèrè tá a fi ń nasẹ̀ ọ̀rọ̀, bíi: “O lórúkọ tìẹ, èmi náà sì ní tèmi. Kí lorúkọ Ọlọ́run? A lè rí ìdáhùn nínú Sáàmù 83:18.” “Ǹjẹ́ gbogbo aráyé lè wà lábẹ́ ìjọba kan ṣoṣo títí gbére? Ṣàkíyèsí bá a ṣe dáhùn èyí nínú Dáníẹ́lì 2:44.” “Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ sọ nǹkan kan nípa bí ọ̀ràn ilé ayé ṣe dà lóde òní? Fi ohun tó wà nínú 2 Tímótì 3:1-5 wé àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká rẹ.” “Ǹjẹ́ ìjìyà àti ikú lè dópin láé bí? A lè rí ohun tí Bíbélì fi dáhùn nínú Ìṣípayá 21:4, 5.”

Nígbà tó o bá ń sọ àsọyé, fífi ọgbọ́n lo ìbéèrè láti fi nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ lè mú kí àwùjọ tún fojú ṣùnnùkùn wo àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn, àní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n tiẹ̀ ti mọ̀ bí ẹni mowó. Ṣùgbọ́n, ṣé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀? Èyí sinmi lórí bóyá àwọn ìbéèrè tó o béèrè jẹ mọ́ ohun tó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Kódà bí kókó ọ̀rọ̀ rẹ bá wù wọ́n pàápàá, ọkàn wọn lè ṣí lọ sórí àwọn nǹkan mìíràn nígbà tó o bá ń ka àwọn ẹsẹ tí wọ́n ti gbọ́ ní àìmọye ìgbà. Tí o kò bá fẹ́ kí ọkàn wọn ṣí kúrò lórí ọ̀rọ̀ rẹ, ńṣe ni kó o ti ronú jinlẹ̀ lórí kókó náà tẹ́lẹ̀ kí ọ̀rọ̀ rẹ bàa lè wọ̀ wọ́n lọ́kàn.

Gbé Ọ̀rọ̀ Kan Tó Ta Kókó Kalẹ̀. O lè gbé ọ̀rọ̀ kan tó ta kókó kalẹ̀, kí o wá darí àfiyèsí àwùjọ sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè jẹ́ ká rí ojútùú sí ọ̀rọ̀ náà. Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ sún àwùjọ láti retí ju ohun tí wọn yóò bá nínú ẹsẹ yẹn lọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, ẹsẹ kan ṣoṣo kì í yanjú ọ̀rọ̀ náà délẹ̀. Àmọ́, o lè sọ fún àwùjọ pé nígbà tó o bá ń ka ẹsẹ náà, kí wọ́n kíyè sí ìtọ́sọ́nà tó fún wa nípa bí a ṣe lè yanjú ọ̀rọ̀ náà.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, o lè sọ ìlànà kan tó dá lórí ìwà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, kí o sì wá fi ìtàn kan nínú Bíbélì ṣàlàyé ìdí tó fi bọ́gbọ́n mu láti tẹ̀ lé ìlànà ọ̀hún. Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bá ní tó kókó pàtàkì méjì (tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ) tó tan mọ́ ohun tí à ń sọ̀rọ̀ lé lórí, àwọn olùbánisọ̀rọ̀ kan máa ń sọ fún àwùjọ pé kí wọ́n máa wò ó bóyá wọ́n á rí kókó wọ̀nyí. Bí ọ̀rọ̀ kan bá díjú fún àwùjọ kan, o lè mú kí wọ́n ronú nípa gbígbé ọ̀nà àbájáde mélòó kan kalẹ̀, kí o sì wá jẹ́ kí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà àti bó o ṣe lò ó pèsè ojútùú.

Fi Bíbélì Ti Ọ̀rọ̀ Rẹ Lẹ́yìn. Bí ọ̀rọ̀ rẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí wọ àwùjọ lára, tó o sì ti ṣàlàyé kókó kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ nípa ọ̀rọ̀ náà, o kàn lè nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ nípa sísọ pé: “Ẹ kíyè sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ lórí kókó yìí.” Èyí á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ohun tó o fẹ́ kà kò ṣeé já ní koro.

Jèhófà lo àwọn èèyàn bíi Jòhánù, Lúùkù, Pọ́ọ̀lù, àti Pétérù láti kọ lára ìwé inú Bíbélì. Ṣùgbọ́n òǹkọ̀wé lásán ni wọ́n; Jèhófà ló ni ìwé. Nígbà tá a bá ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́, wíwulẹ̀ sọ pé “Pétérù kọ̀wé pé” tàbí “Pọ́ọ̀lù sọ pé,” àgàgà nígbà tá a bá ń bá àwọn èèyàn tí kì í ṣe àwọn tó ń ka Bíbélì sọ̀rọ̀, kò lè gbéṣẹ́ àyàfi bí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà bá sọ pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú ẹsẹ náà. Ó yẹ kí a fiyè sí i pé nínú àwọn ọ̀ràn kan, Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé kó nasẹ̀ àwọn ìkéde kan pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Jer. 7:2; 17:20; 19:3; 22:2) Yálà a lo orúkọ Jèhófà nígbà tá a bá ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ tàbí a kò lò ó, ká tó kásẹ̀ ọ̀rọ̀ wa ńlẹ̀, ó yẹ ká gbìyànjú láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló wà nínú ẹsẹ Bíbélì náà.

Gbé Ìdí Tí Ọ̀rọ̀ Yẹn Fi Wáyé Yẹ̀ Wò. Ó yẹ kó o mọ ìdí tí ọ̀rọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fi wáyé kó o tó pinnu bó o ṣe fẹ́ nasẹ̀ rẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, o lè sọ̀rọ̀ ní tààràtà nípa ìdí tí ọ̀rọ̀ ẹsẹ náà fi wáyé; ṣùgbọ́n, ìdí tí ọ̀rọ̀ ẹsẹ yẹn gbà wáyé tún lè pinnu ohun tó o máa sọ o. Bí àpẹẹrẹ, ṣé bó o ṣe nasẹ̀ ọ̀rọ̀ Jóòbù olùbẹ̀rù Ọlọ́run lo ṣe máa nasẹ̀ gbólóhùn tó jáde lẹ́nu ọ̀kan lára àwọn olùtùnú èké tí wọ́n ní àwọn wá tù ú nínú? Lúùkù ló kọ ìwé Ìṣe, àmọ́ ó lo ọ̀rọ̀ Jákọ́bù, Pétérù, Pọ́ọ̀lù, Fílípì, Sítéfánù, ti àwọn áńgẹ́lì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ nínú ìwé yẹn, ó sì tún fa ọ̀rọ̀ Gàmálíẹ́lì yọ, àti tàwọn Júù míì tí kì í ṣe Kristẹni. Ta lo máa sọ pé ó sọ ọ̀rọ̀ tó o fà yọ? Bí àpẹẹrẹ, rántí pé kì í ṣe Dáfídì ló kọ gbogbo sáàmù, má sì gbàgbé pé Sólómọ́nì kọ́ ló kọ gbogbo ìwé Òwe. Ó tún ṣàǹfààní láti mọ ẹni tí òǹkọ̀wé Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti kókó tó ń sọ̀rọ̀ lé lórí lápapọ̀.

Lo Ìtàn Ohun Tó Fa Ọ̀rọ̀ Yẹn. Èyí máa ń gbéṣẹ́ gan-an ní pàtàkì bó o bá lè fi hàn pé ipò àwọn nǹkan nígbà tí wọ́n ń kọ ìtàn Bíbélì náà kò yàtọ̀ sí àwọn ipò tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí. Nínú àwọn ọ̀ràn mìíràn, ó yẹ láti mẹ́nu kan ìtàn ohun tó fa ọ̀rọ̀ kan káwọn èèyàn lè lóye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o fẹ́ lo Hébérù 9:12, 24 nínú àsọyé kan nípa ìràpadà, kó o tó ka àwọn ẹsẹ wọ̀nyí, o lè rí i pé ó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣàlàyé ráńpẹ́ lórí yàrá inú pátápátá nínú ibùjọsìn, èyí tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn fi hàn pé ó dúró fún ibi tí Jésù wọ̀ lọ nígbà tó gòkè re ọ̀run. Àmọ́, má ṣe pa ìtàn ohun tó fa ọ̀rọ̀ ọ̀hún lọ bí ilẹ̀ bí ẹni, tí a ò fi ní wá mọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o ń nasẹ̀ rẹ̀ mọ́.

Láti lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń nasẹ̀ Ìwé Mímọ́, gbé ohun tí àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dá-ń-tọ́ ń ṣe yẹ̀ wò. Ṣàkíyèsí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń lò. Gbé bí ọ̀nà wọ̀nyí ṣe gbéṣẹ́ tó yẹ̀ wò. Nígbà tó o bá ń múra àsọyé tìrẹ, mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì-pàtàkì, kí o sì ronú jinlẹ̀ lórí iṣẹ́ tó yẹ kí ẹsẹ kọ̀ọ̀kan ṣe. Fara balẹ̀ múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o máa lò fún gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí, kó bàa lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn ṣinṣin. Lẹ́yìn náà, múra sílẹ̀ bákan náà fún gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yòókù tó o fẹ́ kà. Bí apá yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ń sunwọ̀n sí i, ńṣe ni wàá túbọ̀ máa pe àfiyèsí sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Nígbà tó o bá fẹ́ yan ọ̀nà tí yóò mú kí ọkàn àwọn èèyàn fà sí ọ̀rọ̀ rẹ, ronú nípa ohun tí àwùjọ ti mọ̀ tẹ́lẹ̀, àti bí kókó náà ṣe rí lára wọn.

  • Rí i dájú pé o mọ iṣẹ́ tó yẹ kí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe, sì mẹ́nu lọ síbẹ̀ nínú ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ.

ÌDÁNRAWÒ: Yan ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o mọ̀ pé o lè lò lọ́nà tó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ rẹ. Ronú nípa (1) ìbéèrè tàbí ọ̀rọ̀ kan tó o máa gbé kalẹ̀ láti fọkàn onílé sọ́nà, àti (2) bó o ṣe máa pe àfiyèsí sí ìdí tó o fi fẹ́ ka ẹsẹ náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́