Orin 96
Ẹ Wá Àwọn Ẹni Yíyẹ Kàn
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Olúwa wa kọ́ wa níṣẹ́ ìwàásù,
Ohun tó sọ fún wa ni pé:
‘Níbikíbi tẹ́ẹ bá lọ, ẹ wá àwọn
Táìní wọn tẹ̀mí ńjẹ lọ́kàn rí.
Bẹ́ẹ ṣe ńkí ońlé pé àlàáfíà fún wọn,
Àlàáfíà yóò bá ẹni yíyẹ.
Táwọn kan bá láwọn ò fẹ́ gbọ́, ẹ gbọn
Ekuru ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ ńbẹ̀.’
2. Àwọn tó bá gbà yín ti gba òun pẹ̀lú.
Ọlọ́run yóò là wọ́n lóye.
Ìfẹ́ tí wọ́n ní síyè àìnípẹ̀kun
Yóò mú kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ yín.
Ẹ má sì ṣàníyàn ohun tẹ́ó sọ láé.
Jèhófà yóò gbẹnu yín sọ̀rọ̀.
Tí ìdáhùn yín bá níyọ̀ tó sì dáa,
Yóò wọ àwọn ońrẹ̀lẹ̀ lọ́kàn.
(Tún wo Ìṣe 13:48; 16:14; Kól. 4:6.)