ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/15 ojú ìwé 2
  • “Ẹ Máa Ní Ìfẹ́ fún Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ Máa Ní Ìfẹ́ fún Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Fún Wa Ní Ìgbàgbọ́ Sí I”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Máa Rìn Nípa Ìgbàgbọ́, Má Ṣe Rìn Nípa Ohun Tó O Lè Fojú Rí!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máa Lo Ìgbàgbọ́ Nínú Àwọn Ìlérí Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 12/15 ojú ìwé 2

“Ẹ Máa Ní Ìfẹ́ fún Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yìí ti wà ní àkọsílẹ̀ ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn. (1 Pét. 2:17) Àmọ́, àkókò yìí la nílò rẹ̀ jù lọ! Báwo la ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ ará tó wà káàkiri ayé? Kí la sì lè ṣe tí ìfẹ́ wa ò fi ní dín kù nínú ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí? (Mát. 24:12) Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí tó o bá ń wo fídíò tá a pe àkọlé rẹ̀ ní ‘Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa.’

(1) Ìgbà wo la di ara ẹgbẹ́ àwọn ará wa tó kárí ayé? (2) Àwọn nǹkan mẹ́ta wo ni ẹgbẹ́ ará wa ń ṣe kárí ayé? (3) Báwo làwọn ará wa ṣe ń fi hàn pé wọ́n múra tán láti wàásù (a) ní aginjù Alaskan, (b) ní àwọn èbúté ilẹ̀ Yúróòpù tó fẹ̀ gan-an (d) àti ní igbó orílẹ̀-èdè Peru? (4) Kí nìdí tí kò fi yẹ ká rò pé ohun tí kò tó nǹkan ni iṣẹ́ ìwàásù? (5) Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó fi hàn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ará wa tá a sì tù wọ́n nínú (a) lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ kan wáyé, (b) lẹ́yìn tí ìjì líle kan wáyé (d) àti nígbà ogun abẹ́lé? (6) Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti fi hàn pé a ní ohun pàtàkì tó ń jẹ́ kí àwọn èèyàn dá ẹgbẹ́ ará wa mọ̀? (John 13:35) (7) Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa? (8) Báwo làwọn ará wa ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù àti Rọ́ṣíà ṣe ń rí oúnjẹ tẹ̀mí nígbà tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa níbẹ̀? (9) Ìsapá àrà ọ̀tọ̀ wo ni ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ń ṣe kí wọ́n lè lọ sí àpéjọ àgbègbè, kí sì nìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? (10) Báwo ni fídíò yìí ṣe mú kó o pinnu pé (a) wàá máa jọ́sìn Jèhófà níṣọ̀kan pẹ̀lú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin rẹ láwọn ìpàdé (b) wàá máa ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ nígbà ìṣòro (d) wàá máa fi ìṣòtítọ́ wàásù nígbà gbogbo àti lọ́nà gbogbo? (11) Báwo ni wàá ṣe lo fídíò yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, ìgbà wo lo sì lè lò ó?

Ìdí pàtàkì tá a fi jẹ́ ara ẹgbẹ́ ará wa tó kárí ayé ni pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, a fẹ́ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ká sì máa kọ́ àwọn èèyàn nípa rẹ̀. A sì tún nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́. Tí a bá ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n níṣòro, a kò retí pé kí Ọlọ́run dúpẹ́ lọ́wọ́ wa. Àwa là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí pé ẹ̀bùn tó ṣeyebíye gan-an ni ẹgbẹ́ ará tó fi jíǹkí wa yìí jẹ́. Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé tí ò nífẹ̀ẹ́ yìí ṣe ń lọ sópin, ǹjẹ́ ká túbọ̀ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará wa!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́