Orin 126
Òpò Tá A Fi Ìfẹ́ Ṣe
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà ọjọ́ ti pé;
A ńgbàdúrà látọkàn wá.
O kà wá yẹ, a rojúure rẹ,
Ó kọjá sísọ.
O ti rọ̀jò ìbùkún
Sórí òpò táa fìfẹ́ ṣe.
Ẹ̀rí èyí ni ilé rẹ yìí,
Tóo tọwọ́ wa kọ́.
(ÈGBÈ)
Jèhófà, àǹfààní wa ló jẹ́
Láti kọ́ ibí yìí fún ọ.
Jọ̀wọ́ jẹ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ sìn títí ayé
Kí ìṣe wa sì máa yìn ọ́.
2. Ayọ̀ sì ńhàn lójú wa,
A wá di ọ̀rẹ́ àtàtà.
Aò ní gbàgbé èyí títí láé,
Àìnípẹ̀kun!
Jáà, a ríṣẹ́ ẹ̀mí rẹ,
Báa ṣe ńṣiṣẹ́ pọ̀ níṣọ̀kan.
Táà ńbuyì kún orúkọ ńlá rẹ;
Èrè ńlá mà ni!
(ÈGBÈ)
Jèhófà, àǹfààní wa ló jẹ́
Láti kọ́ ibí yìí fún ọ.
Jọ̀wọ́ jẹ́ ká lè máa ṣiṣẹ́ sìn títí ayé
Kí ìṣe wa sì máa yìn ọ́.
(Tún wo Sm. 116:1; 147:1; Róòmù 15:6.)