Orin 62
Ti Ta Ni Àwa Jẹ́?
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ti ta ni ìwọ jẹ́?
Ti ọlọ́run wo lo ńgbọ́?
Ẹni t’ò ńwárí fún lọ̀gá rẹ.
Ó di ọlọ́run tí o ńsìn.
O kò lè sin méjì;
Ọ̀gá méjèèjì kò lè
Rí gbogbo ìfẹ́ ọkàn rẹ gbà tán.
O kò lè tẹ́ wọn lọ́rùn.
2. Ti ta ni ìwọ jẹ́?
Ti ọlọ́run wo loó gbọ́?
Ọ̀kan jékèé ọ̀kan sì jóòótọ́
Èwo lo yàn? Ó dọwọ́ rẹ.
Ṣé Késárì ayé
Yìí nìwọ yóò ṣì máa sìn?
Àbí wàá gbọ́ ti Ọlọ́run tòótọ́
Kóo sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
3. Ti ta ni èmi jẹ́?
Ti Jèhófà ni màá gbọ́.
Baba mi ọ̀run ni nó máa sìn;
Màá san ẹ̀jẹ́ mi fúnun pátá.
Iye ńlá ló rà mí;
Òun ni màá sìn títí láé.
Ikú Ọmọ rẹ̀ ló rà mí pa dà;
Nó máa gbé oókọ Rẹ̀ ga.
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 116:14, 18; 2 Tím. 2:19.)