Orin 147
Àkànṣe Dúkìá
Bíi Ti Orí Ìwé
Ọlọ́run l’ẹ́dàá tuntun,
Àwọn ’mọ tó f’ẹ̀mí yàn.
Ó rà wọ́n nínú ayé;
Wọ́n ti r’ójúure rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe dúkìá,
Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n.
Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́.
Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé.
Orílẹ̀èdè mímọ́ ni,
Wọ́n mọyì òtítọ́ gan-an.
Ó pè wọ́n nínú òòkùn
Wá sínú ìmọ́lẹ̀.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe dúkìá,
Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n.
Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́.
Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé.
Wọ́n ńbá’ṣẹ́ ìsìn wọn lọ,
Wọ́n ńk’ágùntàn mìíràn jọ.
Adúróṣinṣin ni wọ́n.
Wọ́n ńpàṣẹ Jésù mọ́.
(ÈGBÈ)
Àkànṣe dúkìá,
Èèyàn f’óókọ rẹ ni wọ́n.
Wọ́n fẹ́ ọ. Wọ́n ńyìn ọ́.
Wọ́n ńkéde orúkọ rẹ f’áyé.
(Tún wo Aísá. 43:20b, 21; Mál. 3:17; Kól. 1:13.)