ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 12/15 ojú ìwé 12-17
  • Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Orísun Ìrànwọ́ Tí Kì Í Kùnà
  • Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Áńgẹ́lì
  • Ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
  • Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́
  • Ǹjẹ́ o Mọrírì Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run
    Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ọ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Bí Àwọn Áńgẹ́lì Ṣe Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 12/15 ojú ìwé 12-17

Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Wa

“Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.”—SÁÀMÙ 121:2.

1, 2. (a) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé gbogbo wa la máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan? (b) Irú Olùrànlọ́wọ́ wo ni Jèhófà jẹ́?

ǸJẸ́ a rẹ́ni tó lè sọ pé òun ò nílò ìrànlọ́wọ́ rí? Ní ti tòótọ́, gbogbo wa la máa ń nílò ìrànlọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè jẹ́ ìrànlọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro líle koko, tàbí láti mọ́kàn nígbà tá a bá pàdánù ohun kan tó ṣeyebíye tàbí láti ní ìforítì lábẹ́ àdánwò líle. Nígbà táwọn èèyàn bá nílò ìrànlọ́wọ́, ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ wọn tí wọ́n mọ̀ pé ó lójú àánú ni wọ́n sábà máa ń lọ. Sísọ ìṣòro wọn fún irú ọ̀rẹ́ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ kí ìṣòro náà fúyẹ́ lọ́kàn wọn kó sì rọrùn láti fara dà. Àmọ́ ìwọ̀nba ni ìrànlọ́wọ́ táwa èèyàn ẹlẹ́ran ara lè ṣe fúnra wa. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn kan tiẹ̀ lè máà lè ṣèrànwọ́ rárá nígbà tá a bá nílò ìrànlọ́wọ́.

2 Àmọ́ ṣá o, Olùrànlọ́wọ́ kan wà, tí agbára rẹ̀ ò láàlà tó sì ní àìmọye nǹkan tó lè fi ṣèrànwọ́ fúnni. Kódà, ó mú un dá wa lójú pé òun ò ní fi wá sílẹ̀ láé. Olùrànlọ́wọ́ yìí ni onísáàmù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tó fi ìdánilójú sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.” (Sáàmù 121:2) Kí ló mú kó dá onísáàmù yìí lójú pé Jèhófà yóò ràn òun lọ́wọ́? Ká tó lè dáhùn ìbéèrè yẹn, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ yẹ Sáàmù kọkànlélọ́gọ́fà wò. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ ká rídìí táwa náà fi lè ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa.

Orísun Ìrànwọ́ Tí Kì Í Kùnà

3. Òkè ńlá wo ló ṣeé ṣe kí onísáàmù náà máa wò, kí sì nìdí?

3 Onísáàmù náà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa jíjẹ́ ká mọ̀ pé dídá tí Jèhófà dá ohun gbogbo la fi ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, ó ní: “Èmi yóò gbé ojú mi sókè sí àwọn òkè ńlá. Ibo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 121:1, 2) Kì í ṣe pé òkè ńlá kan ṣá ni onísáàmù yìí ń wò o. Nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, Jerúsálẹ́mù ni tẹ́ńpìlì Jèhófà wà. Ìlú yìí wà ní orí àwọn òkè ńlá Júdà, ibẹ̀ sì ni Jèhófà ń gbé lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Sáàmù 135:21) Ó ní láti jẹ́ pé àwọn òkè Jerúsálẹ́mù níbi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà sí ni onísáàmù náà ń wò, ó ń fi ìgbọ́kànlé retí Jèhófà pé á ran òun lọ́wọ́. Kí ló mú kó dá onísáàmù náà lójú pé Jèhófà yóò ran òun lọ́wọ́? Ohun tó mú kó dá a lójú ni pé Jèhófà ni “Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” Lẹ́nu kan, ohun tí onísáàmù náà ń sọ ni pé, ‘Dájúdájú kò sóhun tó lè dá Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára gbogbo dúró tí kò fi ní ràn mí lọ́wọ́!’—Aísáyà 40:26.

4. Báwo ni onísáàmù ṣe fi hàn pé Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ ṣeré rárá, kí sì nìdí tíyẹn fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?

4 Onísáàmù náà tún ṣàlàyé pé Jèhófà kì í fọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣeré rárá, ó ní: “Kò ṣeé ṣe kí òun jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. Kò ṣeé ṣe kí Ẹni tí ń ṣọ́ ọ tòògbé. Wò ó! Kì yóò tòògbé, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sùn, Ẹni tí ń ṣọ́ Ísírẹ́lì.” (Sáàmù 121:3, 4) Ọlọ́run ò lè jẹ́ káwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé e “ta gbọ̀n-ọ́ngbọ̀n-ọ́n” kò sì lè jẹ́ kí wọ́n ṣubú débi tí wọn ò ti ní lè dìde mọ́. (Òwe 24:16) Kí nìdí? Nítorí pé ńṣe ni Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn tó wà lójúfò, tó ń ṣọ́ àwọn àgùntàn rẹ̀ lójú méjèèjì. Ǹjẹ́ ìyẹn ò tó láti fi wá lọ́kàn balẹ̀? Kò tiẹ̀ sígbà kan tí kì í wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀. Tọ̀sán-tòru ló máa ń ṣọ́ wọn lójú méjèèjì.

5. Kí nìdí tá a fi sọ pé Jèhófà wà ní “ọwọ́ ọ̀tún”?

5 Ìdánilójú tí onísáàmù náà ní pé Jèhófà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kó kọ̀wé pé: “Jèhófà ń ṣọ́ ọ. Jèhófà ni ibòji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Àní oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ọ̀sán, tàbí òṣùpá ní òru.” (Sáàmù 121:5, 6) Ní Ìlà Oòrùn ayé, táwọn tó ń fẹsẹ̀ rìnrìn àjò nínú oòrùn tó mú janjan bá rí ibi tí wọ́n lè forí pa mọ́ sí, ńṣe ni inú wọn máa ń dùn gan-an. Jèhófà dà bíi ibòji fún àwọn èèyàn rẹ̀, ó ń dáàbò bò wọ́n kúrò nínú àjálù tó dà bí ooru gbígbóná janjan. Kíyè sí i pé “ọwọ́ ọ̀tún” ló sọ pé Jèhófà wà. Nígbà táwọn èèyàn bá ń jagun láyé ìgbàanì, apata táwọn sójà sábà máa ń gbé sọ́wọ́ òsì kì í fi bẹ́ẹ̀ dáàbò bo ọwọ́ ọ̀tún wọn. Ọ̀rẹ́ kan tó bá nífẹ̀ẹ́ sójà náà dénú lè dàábò bò ó nípa dídúró sí ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún rẹ̀ kó sì máa gbèjà rẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ń dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ nìyẹn, tó sì múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà.

6, 7. (a) Báwo ni onísáàmù ṣe mú un dá wa lójú pé Jèhófà kò ní yéé ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká ní ìdánilójú bíi ti onísáàmù?

6 Ǹjẹ́ ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jèhófà máa dáwọ́ ìrànlọ́wọ́ tó ń ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ dúró? Ìyẹn ò lè ṣẹlẹ̀ láé. Onísáàmù náà wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù. Òun yóò máa ṣọ́ ọkàn rẹ. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ìjáde rẹ àti ìwọlé rẹ láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 121:7, 8) Ṣàkíyèsí pé onísáàmù yìí ti wá ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ iwájú báyìí, kò sọ̀rọ̀ nípa ìsinsìnyí nìkan mọ́. Onísáàmù náà ti kọ́kọ́ sọ ṣáájú ní ẹsẹ ìkarùn-ún pé: “Jèhófà ń ṣọ́ ọ.” Àmọ́ nínú àwọn ẹsẹ yìí, onísáàmù náà sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ.” Ìyẹn ló mú un dá àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ lójú pé ìrànlọ́wọ́ Jèhófà yóò nasẹ̀ dé ọjọ́ iwájú. Ibi yòówù ti wọn ì báà lọ, àjálù èyíkéyìí tí wọn ì báà dojú kọ, kò sígbà kan tí Jèhófà ò ní ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 12:21.

7 Láìṣe àní-àní, ó dá ẹni tó kọ Sáàmù kọkànlélọ́gọ́fà yìí lójú pé, Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ alágbára ńlá gbogbo ń ṣọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn tó bìkítà àti bí ẹ̀ṣọ́ tó wà lójúfò ṣe ń ṣọ́nà lójú méjèèjì. Kò sídìí tí ò fi yẹ káwa náà ní ìdánilójú bíi ti onísáàmù yìí, nítorí pé Jèhófà kò yí padà. (Málákì 3:6) Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé nǹkan kan ò ní ṣẹlẹ̀ sí wa ni? Rárá o, àmọ́ tá a bá gbà pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa, Jèhófà yóò dáàbò bò wá lọ́wọ́ gbogbo ohun tó bá lè pa wá lára nípa tẹ̀mí. A lè béèrè pé, ‘Báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?’ Ẹ jẹ́ ká yẹ ọ̀nà mẹ́rin tó gbà ń ràn wá lọ́wọ́ wò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a óò jíròrò bó ṣe ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Inú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e la óò ti jíròrò ọ̀nà tó gbà ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ lóde òní.

Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Áńgẹ́lì

8. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu pé ire àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ àwọn áńgẹ́lì lógún gan-an?

8 Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn áńgẹ́lì ni Jèhófà ń darí. (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wọ̀nyí ń fi ìṣòtítọ́ pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Sáàmù 103:20) Wọ́n mọ̀ dájú pé Jèhófà ní ìfẹ́ tó ga fún àwọn èèyàn tó jẹ́ olùjọ́sìn rẹ̀ ó sì múra tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Abájọ tí ire àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó wà lórí ilẹ̀ ayé fi jẹ àwọn áńgẹ́lì lógún. (Lúùkù 15:10) Ó sì dájú pé inú àwọn áńgẹ́lì ń dùn bí Jèhófà ṣe ń lò wọ́n láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà lo àwọn áńgẹ́lì láti ran àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láyé ìgbàanì?

9. Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ kan nípa bí Ọlọ́run ṣe fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ lágbára láti dáàbò bo àwọn olóòótọ́ èèyàn.

9 Ọlọ́run fún àwọn áńgẹ́lì lágbára láti dáàbò bo àwọn olóòótọ́ èèyàn àti láti dá wọn nídè. Àwọn áńgẹ́lì méjì ló ran Lọ́ọ̀tì àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì lọ́wọ́ tí wọ́n fi bọ́ lọ́wọ́ ìparun Sódómù àti Gòmórà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:1, 15-17) Áńgẹ́lì kan ṣoṣo ló pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà tí wọ́n gbógun ti Jerúsálẹ́mù. (2 Àwọn Ọba 19:35) Nígbà tí wọ́n ju Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún, Jèhófà “rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà.” (Dáníẹ́lì 6:21, 22) Áńgẹ́lì kan yọ àpọ́sítélì Pétérù kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. (Ìṣe 12:6-11) Bíbélì mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ mìíràn nípa bí àwọn áńgẹ́lì ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn, tó fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí Sáàmù 34:7 sọ pé: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”

10. Báwo ni Jèhófà ṣe lo áńgẹ́lì kan láti fún wòlíì Dáníẹ́lì níṣìírí?

10 Àtìgbàdégbà ni Jèhófà máa ń lo àwọn áńgẹ́lì láti gba àwọn olóòótọ́ èèyàn níyànjú àti láti fún wọn lókun. Àpẹẹrẹ kan tó jọni lójú gan-an wà nínú Dáníẹ́lì orí kẹwàá. Dáníẹ́lì ti ń lọ sí nǹkan bí ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún lákòókò yẹn. Ìbànújẹ́ sì dórí wòlíì náà kodò, bóyá tìtorí pé Jerúsálẹ́mù ti dahoro àti bí wọ́n ṣe ń fi iṣẹ́ títún tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́ falẹ̀ ni. Ọkàn rẹ̀ ò sì tún balẹ̀ lẹ́yìn tó rí ìran kan tó dẹ́rù bà á. (Dáníẹ́lì 10:2, 3, 8) Ọlọ́run fi ìfẹ́ rán áńgẹ́lì kan pé kó lọ fún un níṣìírí. Kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀méjì ni áńgẹ́lì náà sọ fún Dáníẹ́lì pé ó jẹ́ “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi” lójú Ọlọ́run. Kí ni àbájáde rẹ̀? Wòlíì tó ti darúgbó yìí sọ fún áńgẹ́lì náà pé: “Ìwọ̀ ti fún mi lókun.”—Dáníẹ́lì 10:11, 19.

11. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Ọlọ́run ń lo àwọn áńgẹ́lì láti darí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà?

11 Jèhófà tún ń lo àwọn áńgẹ́lì láti darí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà. Áńgẹ́lì kan ló darí Fílípì láti lọ wàásù nípa Kristi fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan tó fi ṣèrìbọmi lẹ́yìn náà. (Ìṣe 8:26, 27, 36, 38) Kété lẹ́yìn ìyẹn, Ọlọ́run tún fẹ́ kí wọ́n wàásù ìhìn rere náà fún àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ pẹ̀lú. Nínú ìran kan, áńgẹ́lì kan fara han Kọ̀nílíù, ìyẹn Kèfèrí kan tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì sọ pé kó ránṣẹ́ sí àpọ́sítélì Pétérù. Nígbà táwọn tí Kọ̀nílíù rán níṣẹ́ dé ọ̀dọ́ Pétérù, wọ́n sọ fún un pé: “Kọ̀nílíù . . . ni áńgẹ́lì mímọ́ kan fún ní àwọn ìtọ́ni àtọ̀runwá pé kí ó ránṣẹ́ pè ọ́ láti wá sí ilé òun, kí òun sì gbọ́ àwọn ohun tí o ní láti sọ.” Pétérù jẹ́ ìpè rẹ̀, bí Kọ̀nílíù àti ìdílé rẹ̀ ṣe di Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tó kọ́kọ́ di ara ìjọ Kristẹni nìyẹn. (Ìṣe 10:22, 44-48) Ó dájú pé inú rẹ máa dùn gan-an tó o bá mọ̀ pé áńgẹ́lì kan ló ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ẹnì kan tó jẹ́ ọlọ́kàn rere wàásù fún!

Ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́

12, 13. (a) Kí ló mú káwọn àpọ́sítélì Jésù gbà gbọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ lè ran àwọn lọ́wọ́? (b) Ọ̀nà wo ni ẹ̀mí mímọ́ gbà fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lágbára?

12 Kí Jésù tó kú, ó mú un dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lójú pé òun ò ní fi wọ́n sílẹ̀ láìsí olùrànlọ́wọ́. Baba yóò fún wọn ní “olùrànlọ́wọ́,” èyí tí í ṣe “ẹ̀mí mímọ́.” (Jòhánù 14:26) Kò sídìí tí ò fi yẹ káwọn àpọ́sítélì gbà gbọ́ pé ẹ̀mí mímọ́ lè ran àwọn lọ́wọ́. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn bí Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí mímọ́, ìyẹn ipá tó lágbára jù lọ, láti ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́.

13 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run ti lo ẹ̀mí mímọ́ láti fún àwọn èèyàn lágbára tí wọ́n á fi ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn Onídàájọ́ lágbára láti dá Ísírẹ́lì nídè. (Àwọn Onídàájọ́ 3:9, 10; 6:34) Ẹ̀mí mímọ́ kan náà yìí ló fún àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lágbára láti máa fi ìgboyà bá iṣẹ́ ìwàásù wọn lọ láìfi gbogbo àtakò táwọn èèyàn ṣe sí wọn pè. (Ìṣe 1:8; 4:31) Bí wọ́n ṣe kẹ́sẹ járí nínú ìṣẹ́ ìwàásù wọn fi ẹ̀rí hàn kedere pé ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́. Àbí kí la tún fẹ́ sọ pé ó jẹ́ káwọn èèyàn ‘tí kò mọ̀wé tí wọ́n sì tún jẹ́ gbáàtúù’ tan ìhìn Ìjọba náà kálẹ̀ jákèjádò gbogbo ibi tí ayé mọ nígbà yẹn lọ́hùn-ún?—Ìṣe 4:13; Kólósè 1:23.

14. Báwo ni Jèhófà ṣe lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti la àwọn èèyàn rẹ̀ lóye?

14 Jèhófà tún lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti la àwọn èèyàn rẹ̀ lóye. Ẹ̀mí Ọlọ́run tó ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ ló fi ṣeé ṣe fún un láti túmọ̀ àlá alásọtẹ́lẹ̀ tí Fáráò lá. (Jẹ́nẹ́sísì 41:16, 38, 39) Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣí àwọn ohun tó fẹ́ ṣe payá fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ àmọ́ ó fi wọ́n pa mọ́ fún àwọn agbéraga. (Mátíù 11:25) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi sọ nípa àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún “àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀” pé: “àwa ni Ọlọ́run ti ṣí wọn payá fún nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 2:7-10) Ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ nìkan ló lè mú kéèyàn lóye ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́.

Ìrànlọ́wọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

15, 16. Kí ni Ọlọ́run sọ pé kí Jóṣúà ṣe kó tó lè hùwà ọgbọ́n?

15 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni,” ó sì mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láti di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọsílẹ̀ ṣe ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láyé ọjọ́un.

16 Ìwé Mímọ́ ń pèsè ìtọ́sọ́nà tó yè kooro fáwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run. Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Jóṣúà pé kó máa ṣe aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Ìwé òfin yìí [tí Mósè kọ sílẹ̀] kò gbọ́dọ̀ kúrò ní ẹnu rẹ, kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí o lè kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, nígbà náà ni ìwọ yóò sì hùwà ọgbọ́n.” Ṣàkíyèsí pé Ọlọ́run kò ṣèlérí fún Jóṣúà pé ọgbọ́n á kó sí i lágbárí lọ́nà ìyanu. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tí Jóṣúà bá ka “ìwé òfin” náà tó sì ṣe àṣàrò lé e lórí ló máa tó hùwà ọgbọ́n.—Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3.

17. Báwo ni àwọn ìwé kékeré tó jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ṣe ran Dáníẹ́lì àti Jòsáyà Ọba lọ́wọ́?

17 Jèhófà tún lo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà lákọsílẹ̀ láti ṣí ìfẹ́ rẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe payá. Bí àpẹẹrẹ, inú àwọn ohun tí Jeremáyà kọ sílẹ̀ ni Dáníẹ́lì ti fòye mọ bí àkókò tí Jerúsálẹ́mù fi máa wà ní ahoro ṣe máa gùn tó. (Jeremáyà 25:11; Dáníẹ́lì 9:2) Tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìṣàkóso Jòsáyà Ọba Júdà. Ní àkókò yẹn, orílẹ̀-èdè náà ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì hàn gbangba pé àwọn ọba tó jẹ látẹ̀yìnwá ò kọ ẹ̀dà Òfin náà fún ara wọn, wọ́n ò sì tẹ̀ lé e. (Diutarónómì 17:18-20) Àmọ́ nígbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì kọ́ lọ́wọ́, wọ́n wá rí “ìwé òfin” náà tó ṣeé ṣe kó jẹ́ èyí tí Mósè fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ gan-an. Ó ṣeé ṣe kí ìwé òfin tí wọ́n rí yìí jẹ́ ẹ̀dà ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti kọ tán láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún [800] ṣáájú àkókò yẹn. Lẹ́yìn tí wọ́n ka ohun tó wà nínú rẹ̀ sétígbọ̀ọ́ Jòsáyà, ó wá rí i pé orílẹ̀-èdè náà ò ṣe ìfẹ́ Jèhófà mọ́ rárá, ọba náà wá sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ṣe ohun tó wà nínú ìwé náà. (2 Àwọn Ọba 22:8; 23:1-7) Ǹjẹ́ kò hàn kedere pé àwọn ìwé kékeré tó jẹ́ ara Ìwé Mímọ́ tó wà nígbà yẹn lọ́hùn-ún ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ gan-an?

Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́

18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ló mú kí olùjọsìn tòótọ́ kan ran olùjọsìn mìíràn lọ́wọ́?

18 Ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń ṣe fúnni sábà máa ń wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ìgbàkigbà tí olùjọsìn tòótọ́ kan bá ran ẹnì kejì rẹ̀ lọ́wọ́, Ọlọ́run ló mú kó ṣeé ṣe. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀ pé méjì. Ìdí àkọ́kọ́ ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run. Ẹ̀mí yẹn máa ń mú káwọn tó fẹ́ kí ẹ̀mí náà máa darí wọn ní àwọn ànímọ́ tó dára, irú bí ìfẹ́ àti ìwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá ran ẹlòmíràn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, ó hàn gbangba pé ẹ̀mí Jèhófà ló ń ṣiṣẹ́ yẹn. Ìdí kejì ni pé Ọlọ́run dá wa ni àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Èyí túmọ̀ sí pé àwa náà lè ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, títí kan inú rere àti ìyọ́nú rẹ̀. Nítorí náà, ìgbàkigbà tí ìránṣẹ́ Jèhófà kan bá ran òmíràn lọ́wọ́, ẹni tí a dá wa ní àwòrán rẹ̀ gan-an ni Orísun irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀.

19. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì sọ, báwo ni Jèhófà ṣe pèsè ìrànwọ́ nípasẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni?

19 Ní àkókó tí wọ́n ń kọ Bíbélì, báwo ni Jèhófà ṣe ń lo onígbàgbọ́ kan láti ran àwọn onígbàgbọ́ mìíràn lọ́wọ́? Jèhófà máa ń jẹ́ kí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fún òmíràn ní ìmọ̀ràn, bí ìgbà tí Jeremáyà fún Bárúkù ní ìmọ̀ràn tó gba ẹ̀mí rẹ̀ là. (Jeremáyà 45:1-5) Látìgbàdégbà, àwọn olùjọsìn tòótọ́ máa ń fi àwọn nǹkan tara ṣèrànwọ́ fáwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn, àpẹẹrẹ kan ni ìgbà táwọn Kristẹni tó wà ní Makedóníà àti Ákáyà hára gàgà láti ran àwọn arákùnrin tó jẹ́ aláìní lọ́wọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé irú ìwà ọ̀làwọ́ bẹ́ẹ̀ ń mú “ìfọpẹ́hàn wá fún Ọlọ́run.”—2 Kọ́ríńtì 9:11.

20, 21. Ipò wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nígbà táwọn ará tó wá láti Róòmù fún un lókun?

20 Èyí tó wúni lórí jù lọ ni àwọn àkọsílẹ̀ nípa bí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe sa gbogbo ipá wọn láti fún àwọn onígbàgbọ́ bíi tiwọn ní okun àti ìṣírí. Gbé àpẹẹrẹ kan tó kan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Róòmù gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́wọ̀n, ó gba òpópónà àwọn ará Róòmù kan tí wọ́n ń pè ní Ọ̀nà Ápíà kọjá. Ibi tí wọ́n máa dé kẹ́yìn nínú ìrìn àjò náà ò dáa rárá, nítorí pé àwọn arìnrìn-àjò ní láti gba inú ẹrọ̀fọ̀ kọjá, ìyẹn ní àgbègbè kan tó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀.a Àwọn ará ìjọ tó wà ní Róòmù mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀. Kí ni kí wọ́n ṣe? Ṣé kí wọ́n jókòó gẹlẹtẹ sínú ilé wọn títí dìgbà tí Pọ́ọ̀lù fi máa dé kí wọ́n sì lọ kí i nígbà tó bá dé ni?

21 Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì, ìyẹn Lúùkù tó wà lára àwọn tó tẹ̀ lé Pọ́ọ̀lù nígbà ìrìn àjò náà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa, ó ní: “Nígbà tí àwọn ará sì gbọ́ ìròyìn nípa wa, wọ́n wá láti ibẹ̀ [ìyẹn Róòmù] láti wá pàdé wa ní ibi tí ó jìnnà dé Ibi Ọjà Ápíọ́sì àti Ilé Èrò Mẹ́ta.” Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ohun tí wọ́n ṣe yìí? Bí wọ́n ṣe mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ń bọ̀, àwọn arákùnrin tí wọ́n yàn gbéra láti Róòmù lọ pàdé rẹ̀. Lára àwọn aṣojú náà dúró sí Ibi Ọjà Ápíọ́sì, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí ibi táwọn arìnrìn-àjò ti máa ń dúró sinmi, ó sì wà ní nǹkan bí kìlómítà mẹ́rìnléláàádọ́rin sí Róòmù. Àwọn arákùnrin tó kù dúró sí Ilé Èrò Mẹ́ta, ìyẹn ibi tí wọ́n ti máa ń dúró sinmi, ó sì wà ní nǹkan bíi kìlómítà méjìdínlọ́gọ́ta sí ìlú. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó rí wọn? Lúùkù ròyìn pé: “Bí Pọ́ọ̀lù sì ti tajú kán rí wọn, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì mọ́kànle.” (Ìṣe 28:15) Àbí ẹ ò rí nǹkan, rírí tí Pọ́ọ̀lù rí àwọn arákùnrin tí wọ́n ti sa gbogbo ipá wọn láti rin ìrìn tó jìn tó yẹn jẹ́ orísun okun àti ìtùnú fún un! Tá ni Pọ́ọ̀lù sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí gbogbo ìrànlọ́wọ́ táwọn ará ṣe yìí? Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹni tó mú kó ṣeé ṣe, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run.

22. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún wa ní 2005, kí la óò sì gbé yè wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?

22 Ní kedere, àwọn ohun tí àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ṣe fi hàn pé olùrànlọ́wọ́ ni lóòótọ́. Olùrànlọ́wọ́ tí kò láfiwé ni. Lọ́nà tó bá a mu wẹ́kú, ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 121:2, tó kà pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá” ni yóò jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọdún 2005. Àmọ́, báwo ni Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí? Èyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Akéwì ọmọ ilẹ̀ Róòmù nì tórúkọ rẹ̀ ń Horace (tó gbé ayé ní ọdún 65 sí 68 ṣáájú Sànmánì Tiwa), to sì rin ìrìn àjò kan náà yìí sọ̀rọ̀ nípa bí kò ṣe rọrùn tó láti gba apá ibi tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ yẹn. Horace ṣàpèjúwe ibi ọjà Ápíọ́sì gẹ́gẹ́ bí “ibi tí àwọn tó ń wakọ̀ ojú omi àtàwọn olùtọ́jú ilé èrò tí wọ́n láròró pọ̀ sí gan-an.” Ó tún ráhùn nípa “àwọn kòkòrò kantíkantí àtàwọn ọ̀pọ̀lọ́” tó wà níbẹ̀ àti omi ibẹ̀ “tí kò dára lẹ́nu rárá.”

Ǹjẹ́ O Rántí?

Lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà pèsè ìrànlọ́wọ́—

• nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì?

• nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?

• nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí?

• nípasẹ̀ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́?

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2005 yóò jẹ́: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Pọ́ọ̀lù dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ìrànlọ́wọ́ tó rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará ní Róòmù

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́