Ẹ̀KỌ́ 41
Jẹ́ Kí Àlàyé Ọ̀rọ̀ Rẹ Yéni
NÍGBÀ tí o bá ń sọ̀rọ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ nítumọ̀. Gbìyànjú láti jẹ́ kí ohun tí ò ń sọ yé àwọn tó ń gbọ́ ọ. Èyí á jẹ́ kí o lè báni sọ̀rọ̀ lọ́nà tó múná dóko, ì báà jẹ́ ìjọ lò ń bá sọ̀rọ̀ tàbí ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.
Oríṣiríṣi nǹkan ló wé mọ́ mímú kí ọ̀rọ̀ ẹni yé àwọn èèyàn. A ṣàlàyé díẹ̀ lára wọn nínú Ẹ̀kọ́ 26, “Ṣíṣàlàyé Ọ̀rọ̀ Lẹ́sẹẹsẹ.” Àwọn àlàyé mìíràn wà nínú Ẹ̀kọ́ 30, “Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé Ire Àwọn Ẹlòmíràn Ń Jẹ Ọ́ Lógún.” Nínú àkòrí tá a wà yìí, a ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó mélòó kan sí i.
Lílo Ọ̀rọ̀ Tó Tètè Ń Yéni, Sísọ̀rọ̀ Lọ́nà Tó Rọrùn Láti Lóye. Ọ̀rọ̀ tó tètè ń yéni àti gbólóhùn kúkúrú jẹ́ ohun èlò alágbára tá a lè fi gbin ọ̀rọ̀ síni lọ́kàn. Ìwàásù Lórí Òkè tí Jésù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nípa bí ọ̀rọ̀ ṣe lè yé tọmọdé tàgbà nílé, lóko, kárí ayé. Lóòótọ́, ìlànà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lè jẹ́ ohun tuntun sí wọn. Síbẹ̀, ohun tí Jésù ń sọ yé wọn nítorí pé ọ̀ràn tó kan gbogbo wa ló dá lé lórí: ọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè láyọ̀, bí a ṣe lè mú kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn túbọ̀ dán mọ́rán, ọ̀nà tí àníyàn ṣíṣe kò fi ní borí wa, àti bí ìgbésí ayé wa yóò ṣe dára. Ó sì ṣàlàyé èrò ọkàn rẹ̀ lọ́nà tó tètè yé tọmọdé tàgbà. (Mátíù, orí karùn-ún sí ìkeje) Lóòótọ́, àpẹẹrẹ gbólóhùn gígùn lónírúurú ìwọ̀n àti ọ̀nà tí a ń gbà so gbólóhùn pọ̀ ló wà nínú Bíbélì. Ṣùgbọ́n ohun tó yẹ kó jẹ ọ́ lógún ni bí wàá ṣe ṣàlàyé èrò ọkàn rẹ lọ́nà tó máa yéni kedere.
Kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tó jinlẹ̀ lò ń ṣàlàyé, tí o bá sọ ọ́ lọ́nà tí kò lọ́jú pọ̀ yóò rọrùn láti lóye. Báwo ni wàá ṣe sọ ọ́ tí kò ní lọ́jú pọ̀? Má ṣe ọ̀rínkinniwín àlàyé ọ̀rọ̀ jù fún àwùjọ. To ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́sẹẹsẹ lọ́nà tí yóò túbọ̀ gbé àwọn kókó ọ̀rọ̀ rẹ yọ kedere. Fara balẹ̀ yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì tí yóò gbé àlàyé ọ̀rọ̀ rẹ yọ. Dípò tí wàá fi máa sáré láti orí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan bọ́ sórí òmíràn, àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì wọ̀nyí ni kí o kà kí o sì ṣàlàyé. Má ṣe fi àpọ̀jù àlàyé bo kókó pàtàkì mọ́lẹ̀.
Fi àwọn ìlànà yìí kan náà sọ́kàn nígbà tí o bá ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Má gbìyànjú láti sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tán. Mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lóye àwọn èrò pàtàkì inú ibi tí ò ń kọ́ ọ dáadáa. Nígbà tó bá yá, yóò máa lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó bá kù nígbà tó bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti ní àwọn ìpàdé ìjọ.
Kéèyàn tó lè ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ lọ́nà tó tètè ń yéni, ó gba kéèyàn múra sílẹ̀ dáadáa. Kókó ọ̀rọ̀ rẹ ní láti yé ìwọ fúnra rẹ kedere kí ó tó di pé wàá lè ṣàlàyé rẹ̀ yé àwọn ẹlòmíràn. Bí nǹkan bá yé ọ dáadáa, wàá lè ṣàlàyé ìdí tó fi rí bó o ṣe sọ ọ́. Wàá sì tún lè fi ọ̀rọ̀ ara rẹ ṣàlàyé rẹ̀.
Ṣàlàyé Àwọn Ọ̀rọ̀ Tí Kò Bá Yé Àwùjọ. Nígbà mìíràn, líla nǹkan yéni lè gba pé kí o ṣe àlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ṣàjèjì sí àwọn olùgbọ́ rẹ. Má kàn gbà pé àwọn olùgbọ́ rẹ á ti mọ ohun tí ò ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì kà wọ́n sí aláìmọ̀kan. Nítorí pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣeé ṣe kí o lo àwọn èdè kan tó máa ṣàjèjì sí àwọn èèyàn. Láìjẹ́ pé o sọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bí “àṣẹ́kù,” “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” “àgùntàn mìíràn” àti “ogunlọ́gọ̀ ńlá” fún àwọn tí kò rìn sún mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò ní lè yé wọn pé àwùjọ àwọn èèyàn kan ní pàtó làwọn ọ̀rọ̀ yẹn dúró fún. (Róòmù 11:5; Mát. 24:45; Jòh. 10:16; Ìṣí. 7:9) Bákan náà, àyàfi bí ẹnì kan bá mọ̀ nípa ètò àjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa ló tó lè mọ ohun tí àwọn ọ̀rọ̀ bí “akéde,” “aṣáájú ọ̀nà,” “alábòójútó àyíká” àti “Ìṣe Ìrántí” túmọ̀ sí.
Kódà àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò fàlàlà pàápàá ṣì lè nílò àlàyé. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ohun tí “Amágẹ́dọ́nì” túmọ̀ sí ni ogun átọ́míìkì ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Bí wọ́n bá gbọ́ “Ìjọba Ọlọ́run,” wọ́n lè ní in lọ́kàn pé inú ọkàn ẹni ni Ìjọba náà wà, tàbí kí wọ́n máa ronú nípa lílọ sí ọ̀run, ọkàn wọn kò ní lọ sí ọ̀ràn pé ìjọba gidi lò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀mí,” wọ́n lè máa ronú nípa ohun tí àwọn kan sọ pé ó jẹ́ apá tí kò ṣeé fojú rí lára èèyàn, tí wọ́n ní kì í kú bí agọ̀ ara bá tiẹ̀ kú. Ohun tí wọ́n ti fi kọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni pé “ẹ̀mí mímọ́” jẹ́ ẹni gidi kan, tó jẹ́ ara Mẹ́talọ́kan. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti kẹ̀yìn sí ìwà rere tí Bíbélì fi ń kọ́ni, ó lè gba àlàyé pàápàá kí wọ́n tó lóye ohun tí Bíbélì ń sọ nígbà tó ní: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.”—1 Kọ́r. 6:18.
Tẹ́nì kan kò bá jẹ́ ẹni tó ń ka Bíbélì déédéé, tó o bá kàn sọ pé “Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé . . . ,” tàbí “Lúùkù sọ pé . . . ,” wọ́n lè ṣi ọ̀rọ̀ rẹ lóye, nítorí pé ọ̀rẹ́ wọn kan tàbí aládùúgbò wọn kan lè máa jẹ́ orúkọ yẹn. Ó lè jẹ́ pé wàá fi àlàyé kan há ọ̀rọ̀ rẹ láti fi hàn pé ẹni tó o dárúkọ yẹn jẹ́ Kristẹni kan tó jẹ́ àpọ́sítélì tàbí pé ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ni.
Àwọn olùgbọ́ wa lóde òní sábà máa ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ kí wọ́n tó lè lóye àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a ti lo òṣùwọ̀n tá a fi ń díwọ̀n nǹkan láyé àtijọ́ tàbí ibi tí a ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn àṣà ayé àtijọ́. Bí àpẹẹrẹ, àkọsílẹ̀ tó sọ pé áàkì tí Nóà kàn gùn tó ọ̀ọ́dúnrún ìgbọ̀nwọ́, pé ó fẹ̀ tó àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́, pé ó ga tó ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ lè máà jẹ́ nǹkan bàbàrà lójú wọn. (Jẹ́n. 6:15) Ṣùgbọ́n tó o bá lo ohun kan tí àwọn olùgbọ́ rẹ mọ̀ láyìíká yín láti fi ṣàpèjúwe gígùn, fífẹ̀ àti gíga áàkì yẹn, kíá lonítọ̀hún á ti fojú inú wo bí áàkì yẹn ṣe tóbi tó.
Ṣe Àlàyé Tó Bá Yẹ. Ó lè jẹ́ pé wàá ṣàlàyé ní àfikún sí sísọ ohun tó jẹ́ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan ní pàtó tó o bá fẹ́ kí àwùjọ lóye nǹkan ọ̀hún ní kedere. Ní Jerúsálẹ́mù nígbà ayé Ẹ́sírà, lẹ́yìn tí wọ́n bá ka Òfin, wọ́n á tún ṣàlàyé rẹ̀ pẹ̀lú. Láti mú kí òye rẹ̀ lè yé àwọn èèyàn, àwọn ọmọ Léfì máa ń fi ìtumọ̀ sí i, wọ́n á sì tún sọ bí àwọn èèyàn ṣe lè fi í sílò nínú ipò tí wọ́n wà lásìkò ìgbà yẹn. (Neh. 8:8, 12) Lọ́nà kan náà, fara balẹ̀ ṣàlàyé kí o sì sọ ìlò ẹsẹ Bíbélì tí o bá kà.
Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, ó ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́. Ó tún tẹ ojúṣe wọn mọ́ wọn létí bí wọ́n ṣe jẹ́ ẹlẹ́rìí àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. (Lúùkù 24:44-48) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn èèyàn máa ń tètè lóye ohun tí o kọ́ wọn bó o bá mú kí wọ́n rí bó ṣe yẹ kó nípa lórí ìgbésí ayé àwọn fúnra wọn.
Ipò Ọ̀kan Onítọ̀hún Ṣe Pàtàkì. Lóòótọ́ o, bí àlàyé rẹ bá tiẹ̀ ṣe kedere, àwọn nǹkan mìíràn lè wà tí yóò fi hàn bóyá àlàyé ọ̀hún máa yé onítọ̀hún tàbí kò ní yé e. Bí ọkàn èèyàn bá yigbì, ó lè máà jẹ́ kí onítọ̀hún lóye ohun tó gbọ́. (Mát. 13:13-15) Ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni àwọn nǹkan tẹ̀mí jẹ́ lójú àwọn tó ti pinnu láti máa fojú ti ara nìkan ṣoṣo wo gbogbo ọ̀ràn. (1 Kọ́r. 2:14) Bí ẹnì kan bá ń fi irú ìṣarasíhùwà bẹ́ẹ̀ hàn, ó lè dára pé kí á dáwọ́ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yẹn dúró, ó kéré tán, fúngbà díẹ̀ ná.
Àmọ́ ṣá o, nígbà míì, ó lè jẹ́ pé èèmọ̀ tójú ẹnì kan ti rí láyé ló mú kí ọkàn rẹ̀ yigbì. Bí onítọ̀hún bá láǹfààní láti gbọ́ òtítọ́ inú Bíbélì fún ìgbà díẹ̀, ọkàn rẹ̀ lè yí padà kó sì tẹ́wọ́ gbà á. Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àwọn èèyàn máa na òun lọ́rẹ́, wọ́n á sì pa òun, ohun tó ń wí kò yé wọn rárá. Kí nìdí tí kò fi yé wọn? Ìdí ni pé ìyẹn kọ́ ni wọ́n ń retí pé kó ṣẹlẹ̀, ó sì dájú pé wọn kò tiẹ̀ fẹ́ kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ rárá ni! (Lúùkù 18:31-34) Àmọ́, bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́ òye rẹ̀ padà wá yé àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá, wọ́n sì fi hàn pé ó yé wọn nítorí pé wọ́n ṣe ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe.
Ipa Tí Àpẹẹrẹ Rere Ń Kó. Ọ̀rọ̀ tí a sọ nìkan kọ́ ni a fi lè mú kí òye nǹkan yé àwọn èèyàn, ìwà wa tún lè là wọ́n lóye pẹ̀lú. Nígbà tí àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, kì í ṣe ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn ni wọ́n ń rántí bí kò ṣe ìfẹ́ tó hàn pé ó wà láàárín àwọn ará. Bákan náà, ìdùnnú tó ń hàn lójú wa ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tí a bá sọ̀rọ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì. Rírí tí àwọn èèyàn kan rí inú rere onífẹ̀ẹ́ tí àwa èèyàn Jèhófà ní sí ara wa àti bí a ṣe ń ṣaájò ẹni tí ìṣòro dé bá, mú kí wọ́n gbà pé àwa Ẹlẹ́rìí ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Nítorí náà, bí o ṣe ń gbìyànjú láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ Bíbélì, ronú dáadáa nípa ọ̀nà tó ò ń gbà ṣàlàyé rẹ̀ àti nípa àpẹẹrẹ ìwà tìrẹ fúnra rẹ.