Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn
1. Kí ni ọ̀nà kan pàtàkì lára ohun tó ń mú kí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ṣe kedere, kó sì gbéṣẹ́?
1 Kíkọ́ni lọ́nà tó rọrùn jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó ń mú kí ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ gbéṣẹ́. Ríronú lórí ọ̀nà tí Olùkọ́ Ńlá náà, Jésù, gbà kọ́ni lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” wa sunwọ̀n sí i.—2 Tím. 4:2; Jòh. 13:13.
2. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kọ́ni lọ́nà tó rọrùn, kí ló sì máa ń jẹ́ àbájáde rẹ̀?
2 Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ta Kókó: Ìwàásù Orí Òkè ní nínú àwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀ gan-an tí èèyàn tíì sọ rí, síbẹ̀ kò sí èyí tó ta kókó nínú ẹ̀. (Mát., orí 5-7) “Háà . . . ṣe” ogunlọ́gọ̀ tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù sí “ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n rán láti lọ mú Jésù pàápàá sọ pé: “Ènìyàn mìíràn kò tíì sọ̀rọ̀ báyìí rí.” (Mát. 7:28, 29; Jòh. 7:46) Kò dìgbà tá a bá lo ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà, àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣòro lóye tàbí àpèjúwe tó gùn jànràn-janran ká tó lè mú kí òtítọ́ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn. A lè lo àwọn ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ láti ṣàlàyé òtítọ́ fún wọn.
3. Kí ló lè mú káwọn kan máa rọ́ ìsọfúnni sáwọn èèyàn lórí, báwo la sì ṣe lè yàgò fún èyí?
3 Pinnu Ohun Tó O Máa Sọ: Jésù máa ń ro tàwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa pípinnu bí ìsọfúnni tó máa fún wọn lẹ́ẹ̀kan ṣe máa pọ̀ tó. (Jòh. 16:12) Lórí kókó yìí, a gbọ́dọ̀ máa lo ìfòyemọ̀, ká sì mọ bá a ṣe ń yíwọ́ pa dà, ní pàtàkì tá a bá ń wàásù fún àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn olùfìfẹ́hàn tàbí àwọn ọmọdé. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má kàn máa rọ́ ìsọfúnni sí wọn lórí, kódà nígbà tó bá jọ pé wọ́n ń tẹ́tí sílẹ̀. Àwọn tó mọyì òtítọ́ kò ní yéé gba ìmọ̀ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà sínú.—Jòh. 17:3; 1 Kọ́r. 3:6.
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká gbájú mọ́ kókó ọ̀rọ̀ dípò ṣíṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé?
4 Kókó Ọ̀rọ̀ Ni Kó O Gbájú Mọ́: Jésù ò mú kí ọ̀rọ̀ tó ń sọ lọ́jú pọ̀ nípa ṣíṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé. Nígbà tó sọ pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò . . . jáde wá,” kì í ṣe àsìkò yẹn lá wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa nǹkan méjì tí Ọlọ́run ti pinnu pé ó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó jíǹde. (Jòh. 5:28, 29) Nígbà tá a bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kókó ọ̀rọ̀ gan-an ni ká gbájú mọ́, ká ṣọ́ra fún mímú àwọn ọ̀rọ̀ tí kò sí nínú ibi tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ wọnú ìjíròrò náà.
5. Ìbùkún wo ló lè tìdí ẹ̀ yọ tá a bá ń kọ́ni lọ́nà tó rọrùn?
5 A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ti kọ́ wa ní gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ lọ́nà tó rọrùn! (Mát. 11:25) Ǹjẹ́ kí àwa náà sọ ọ́ dàṣà láti máa kọ́ni lọ́nà tó rọrùn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ rí ayọ̀ tó ń wá látinú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń méso jáde.