Ohun Mẹ́ta Tó Lè Mú Kó O Túbọ̀ Jẹ́ Olùkọ́ Tó Já Fáfá
1. Kí nìdí tó fi yẹ ká wá bá a ṣe lè túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá?
1 Gbogbo Kristẹni òjíṣẹ́ ni olùkọ́. Yálà ìgbà àkọ́kọ́ tá a lọ wàásù fún ẹnì kan ni o, tàbí ìgbà tá a lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò tàbí ìgbà tá à ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ohun tó wà lọ́kàn wa ni pé kí àwọn èèyàn lóye ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ wọn. Ẹ̀kọ́ tá a sì ń kọ́ni jẹ́ èyí tó ṣàrà ọ̀tọ̀. À ń mú kí àwọn èèyàn lóye “ìwé mímọ́,” èyí tó máa jẹ́ kí wọ́n “di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tím. 3:15) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà lèyí jẹ́ o! Ní báyìí, a máa jíròrò àwọn ohun mẹ́ta táá mú ká túbọ̀ jẹ́ olùkọ́ tó já fáfá.
2. Báwo la ṣe lè kọ́ni lọ́nà tó rọrùn?
2 Kọ́ni Lọ́nà Tó Rọrùn: Tí ẹ̀kọ́ kan bá yé àwa dáadáa, ó rọrùn láti gbójú fò ó pé ẹ̀kọ́ náà lè ta kókó fún ẹni tí kò mọ ohunkóhun nípa ẹ̀kọ́ náà. Torí náà, tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, má ṣe máa ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí kò pọn dandan. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn kókó tó ṣe pàtàkì ni kó o tẹnu mọ́. Kò dìgbà téèyàn bá ń da ọ̀rọ̀ sílẹ̀ wuuruwu ká tó sọ pé ó mọ èèyàn kọ́. (Òwe 10:19) Ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé kéèyàn ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣe kókó. Lẹ́yìn tó o bá ti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, apá tó kan ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò ni kó o gbájú mọ́. Ìwàásù Orí Òkè tó wà ní àkọọ́lẹ̀ nínú Mátíù orí 5 sí 7 ní àwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀ gan-an nínú, síbẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù lò kò pọ̀ jù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí èyí tó ta kókó nínú ẹ̀.
3. Àǹfààní wo ló wà nínú àpèjúwe, irú àpèjúwe wo ló sì wúlò jù?
3 Àpèjúwe: Àpèjúwe máa ń mú kéèyàn ronú jinlẹ̀, ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìmọ̀lára tó yẹ, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn rántí ọ̀rọ̀. Kò pọn dandan kó o jẹ́ òpìtàn kó o tó lè lo àpèjúwe tó kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Mát. 7:3-5; 18:2-4) Àwọn àwòrán kéékèèké téèyàn yà sórí bébà náà ṣeé lò láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Tó o bá ronú nípa ohun tó o fẹ́ kọ́ ẹnì kan kó o tó lọ, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn àpèjúwe tó múná dóko tí wàá lò.
4. Báwo la ṣe lè lo ìbéèrè lọ́nà tó jáfáfá?
4 Ìbéèrè: Tó o ba bi ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìbéèrè, ó di dandan kó ronú kó tó fèsì. Torí náà, máa mú sùúrù lẹ́yìn tó o bá ti béèrè ìbéèrè. Tó bá jẹ́ pé ìwọ alára náà lo ń yára dáhùn ìbéèrè rẹ, kò ní ṣeé ṣe fún ọ láti mọ ohun tó wà lọ́kàn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ. Tí ìdáhùn rẹ̀ kò bá tọ̀nà, dípò tí wàá fi sọ ohun tó jẹ́ ìdáhùn, ó máa dára kó o lo àwọn ìbéèrè míì táá jẹ́ kó lè mọ ìdáhùn tó tọ́. (Mát. 17:24-27) Òótọ́ ni pé kò sí èyíkéyìí nínú wa tó jẹ́ olùkọ́ tó gbọ́n tán tó sì mọ̀ tán. Torí bẹ́ẹ̀, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa fiyè sí ẹ̀kọ́ wa nígbà gbogbo. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àǹfààní ayérayé ni àwa àti àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ máa rí.—1 Tím. 4:16.