Ẹ̀KỌ́ 46
Àpèjúwe Tí A Gbé Ka Ohun Táwọn Èèyàn Mọ̀
LÓÒÓTỌ́, ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àpèjúwe rẹ bá ohun tí ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu. Àmọ́, kí àpèjúwe tó lè múná dóko, ó ní láti bá àwùjọ létí mu.
Báwo ni irú àwùjọ tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ ṣe lè nípa lórí irú àpèjúwe tí wàá lò níwájú wọn? Kí ni Jésù Kristi ṣe? Yálà àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò tàbí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ló ń bá sọ̀rọ̀, Jésù kì í lo àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀nà jíjìn sí ilẹ̀ Ísírẹ́lì láti fi ṣe àpèjúwe. Irú àpẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ á ṣàjèjì létí àwùjọ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kò lọ bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé irú ayé táwọn ọba ń jẹ láàfin ní Íjíbítì tàbí onírúurú ẹ̀sìn ilẹ̀ Íńdíà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn àpèjúwe rẹ̀ dá lórí ìgbòkègbodò tó wọ́pọ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè. Ó sọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe àbùlẹ̀ aṣọ, ṣíṣòwò, pípàdánù ohun iyebíye àti lílọ síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó. Ó mọ ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn nípa oríṣiríṣi nǹkan, èyí sì hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Máàkù 2:21; Lúùkù 14:7-11; 15:8, 9; 19:15-23) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni iṣẹ́ ìwàásù Jésù wà fún ní pàtàkì, àwọn àpèjúwe rẹ̀ sábà máa ń jẹ mọ́ ìgbòkègbodò wọn àtàwọn nǹkan tí wọ́n ń rí lójoojúmọ́. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan bí iṣẹ́ àgbẹ̀, bí àwọn àgùntàn ṣe ń gbóhùn olùṣọ́ àgùntàn àti títọ́jú wáìnì sínú awọ ẹran. (Máàkù 2:22; 4:2-9; Jòh. 10:1-5) Ó tún mẹ́nu kan àwọn ìtàn kan tí wọ́n mọ̀ dunjú, ìtàn nípa bí a ṣe ṣẹ̀dá tọkọtaya àkọ́kọ́, Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, ìparun Sódómù àti Gòmórà, ikú tó pa aya Lọ́ọ̀tì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. (Mát. 10:15; 19:4-6; 24:37-39; Lúùkù 17:32) Ṣé ìwọ náà ń fara balẹ̀ kíyè sí ìgbòkègbodò tó wọ́pọ̀ ládùúgbò àwọn olùgbọ́ rẹ àti àṣà ìbílẹ̀ wọn nígbà tó o bá ń ronú nípa àpèjúwe tó o fẹ́ lò?
Bó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo tàbí àwọn èèyàn díẹ̀ lò ń bá sọ̀rọ̀, tí kì í ṣe àwùjọ ńlá ńkọ́? Gbìyànjú láti lo àpèjúwe tó máa tètè yé àwùjọ kékeré náà. Nígbà tí Jésù jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà kan nídìí kànga kan nítòsí Síkárì, Jésù sọ̀rọ̀ nípa “omi ààyè,” àti pé ‘òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ láé.’ Ó sì tún sọ̀rọ̀ nípa “ìsun omi . . . tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” Wàá rí i pé gbogbo èyí jẹ́ àkànlò èdè tó jẹ mọ́ ohun tí obìnrin yẹn wá ṣe. (Jòh. 4:7-15) Nígbà tí Jésù bá àwọn tí ń fọ àwọ̀n tí wọ́n fi ń pẹja sọ̀rọ̀, àkànlò èdè tó lò wé mọ́ iṣẹ́ ẹja pípa. (Lúùkù 5:2-11) Nínú àpẹẹrẹ méjèèjì yìí ni Jésù ti lè sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àgbẹ̀, torí pé iṣẹ́ àgbẹ̀ niṣẹ́ wọn níbẹ̀. Àmọ́, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe túbọ̀ múná dóko nígbà tó pe àfiyèsí sí iṣẹ́ táwọn èèyàn yìí ń ṣe gan-an, tó wá fìyẹn gbin èrò pàtàkì sí wọn lọ́kàn! Ǹjẹ́ o máa ń gbìyànjú láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” ni Jésù ń jíṣẹ́ fún, kì í ṣe Ísírẹ́lì nìkan la rán àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sí ni tirẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí. (Mát. 15:24; Ìṣe 9:15) Ǹjẹ́ èyí hàn nínú ọ̀nà tí Pọ́ọ̀lù gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Nínú ìwé tó kọ sáwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì, ó mẹ́nu kan eré sísá, àṣà jíjẹun nínú tẹ́ńpìlì òrìṣà, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun. Nǹkan wọ̀nyí kò sì ṣàjèjì sáwọn Kèfèrí wọ̀nyẹn.—1 Kọ́r. 8:1-10; 9:24, 25; 2 Kọ́r. 2:14-16.
Ǹjẹ́ bí Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣe fara balẹ̀ ronú nípa àpèjúwe àti àpẹẹrẹ tó bá ọ̀rọ̀ mu ni ìwọ pẹ̀lú ń ṣe nígbà tó o bá ń kọ́ni? Ǹjẹ́ ò ń ronú nípa irú èèyàn tí àwọn olùgbọ́ rẹ jẹ́ àti ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́? Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ ọ́, ayé òde òní yàtọ̀ sí ayé ọ̀rúndún kìíní. Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbọ́ ìròyìn àgbáyé lórí tẹlifíṣọ̀n. Wọ́n mọ ohun tó ń lọ nílẹ̀ òkèèrè. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀ràn rí ládùúgbò rẹ, kò sóhun tó burú nínú lílo irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ fún àpèjúwe. Síbẹ̀síbẹ̀, ohun tó máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn jù lọ lohun tó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n. Àwọn nǹkan bí ilé wọn, ìdílé wọn, iṣẹ́ wọn, oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ àti bí ojú ọjọ́ ṣe rí lágbègbè wọn.
Bí àpèjúwe rẹ bá ń béèrè àlàyé rẹpẹtẹ, àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé nǹkan tó ṣàjèjì létí àwọn olùgbọ́ rẹ lo fi ń ṣe àpèjúwe. Irú àpèjúwe bẹ́ẹ̀ kì í pẹ́ dojú ọ̀rọ̀ rú. Ohun tó máa yọrí sí ni pé àwọn èèyàn lè rántí àpèjúwe rẹ, àmọ́ kí wọ́n máà rántí òtítọ́ tó o fẹ́ kọ́ wọn látinú Ìwé Mímọ́.
Dípò lílo àfiwé tó díjú, nǹkan tó rọrùn, táwọn èèyàn ń rí lójoojúmọ́ ni Jésù lò. Ó fi nǹkan kéékèèké ṣàlàyé nǹkan ńlá, ó sì fi nǹkan rírọrùn ṣàlàyé nǹkan tó le. Jésù fi nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ ṣàlàyé àwọn òtítọ́ tẹ̀mí, èyí sì jẹ́ kó rọrùn fáwọn èèyàn láti tètè lóye òtítọ́ tẹ̀mí tó ń kọ́ wọn, kí wọ́n sì rántí wọn. Àpẹẹrẹ yìí mà dára láti tẹ̀ lé o!