Orin 76
Jèhófà, Ọlọ́run Àlàáfíà
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run
Àlàáfíà àti ìfẹ́.
Fún wa lálàáfíà, ìtura,
Késo rere lè pọ̀ síi.
A ńfẹ́ ìmọ̀ràn rẹ;
Ọmọ rẹ lo fi rà wá.
Jọ̀wọ́ fún wa lálàáfíà rẹ
Tó ta gbogbo èrò yọ.
2. Ayé ńwá àlàáfíà.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ńfa wàhálà.
Ṣùgbọ́n òjò àlàáfíà ńrọ̀
Sórí àwọn èèyàn rẹ.
Báa ṣe ńmọ ìfẹ́ rẹ
Táa sì ńmú ẹ̀jẹ́ wa ṣẹ,
Jọ̀wọ́ fìbùkún síṣẹ́ wa,
Ká lẹ́mìí àlàáfíà síi.
3. Ẹ̀mí ńlà wá lójú
B’Ọ́rọ̀ rẹ ti ńtànmọ́lẹ̀.
Wọ́n ńdáàbò bò wá, wọ́n ńtọ́ wa
Nínú òkùnkùn ayé.
Kí ìrì àlàáfíà
Máa tu ọkàn wa lára,
Kí’wọ lè mú kí ọkàn wa
Balẹ̀, ká wà láìléwu.
(Tún wo Sm. 4:8; Fílí. 4:6, 7; 1 Tẹs. 5:23.)