ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | MÁTÍÙ 1-3
“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”
Bí Jòhánù ṣe máa ń múra àti bó ṣe rí fi hàn pé ó jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ òun lọ́rùn, ìfẹ́ Ọlọ́run ló sì fi ayé rẹ̀ ṣe
Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ ni Jòhánù ní bó ṣe palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún Jésù, èyí sì ju ohun yòówù tó yááfì lọ
Tá a bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, a máa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn sì máa fún wa láyọ̀. A lè jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn láwọn ọ̀nà yìí . . .
mọ àwọn ohun tó o nílò gangan
má ṣe ra àwọn ohun tí kò pọn dandan
gbé ìṣirò lé bó o ṣe máa ná owó rẹ
fún àwọn míì ní àwọn nǹkan tí o kò nílò mọ́ tàbí kó o tà wọ́n
san gbogbo gbèsè tó o jẹ
dín iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó ò ń ṣe kù àti àkókò tó ò ń lò
Eéṣú àti oyin ìgàn ni Jòhánù máa ń jẹ
Tí mo bá jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ mi lọ́rùn, àfojúsùn wo ni ọwọ́ mi lè tẹ̀?