ORIN 52
Ìyàsímímọ́ Kristẹni
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Jèhófà Ọlọ́run ṣẹ̀dá
Àgbáálá ayé yìí.
Tirẹ̀ layé àti ọ̀run,
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni.
Ó fún wa ní èémí ìyè,
Ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé,
Òun nìkan ló yẹ ká fìyìn fún,
Òun nìkan ló yẹ ká sìn.
2. Jésù Kristi ṣèrìbọmi
Láti módodo ṣẹ.
Ó gbàdúrà s’Ọ́lọ́run pé:
‘Mo dé wá ṣèfẹ́ rẹ.’
Bó ṣe jáde nínú omi,
Ọlọ́run fẹ̀mí yàn án.
Olóòótọ́ ni, ó gbàdúrà pé:
‘Bàbá, jẹ́ kífẹ̀ẹ́ rẹ ṣẹ.’
3. Iwájú rẹ la wà, Bàbá.
À ń yin orúkọ rẹ.
A ya ara wa sí mímọ́
Pẹ̀lú ‘rẹ̀lẹ̀ ọkàn.
O fún wa lọ́mọ bíbí rẹ;
Ó fẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.
Torí náà, ìfẹ́ Rẹ la ó máa ṣe
Jálẹ̀ ọjọ́ ayé wa.
(Tún wo Mát. 16:24; Máàkù 8:34; Lúùkù 9:23.)