ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 June ojú ìwé 7
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Wo Lò Ń Bá Ṣọ̀rẹ́ Lórí Ìkànnì?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àkóbá Wo Ni Ìkànnì Àjọlò Lè Ṣe fún Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 1
    Jí!—2012
  • Àwọn Ọmọdé àti Ìkànnì Àjọlò—Apá 1: Ṣé Ó Yẹ Kí Ọmọ Mi Lo Ìkànnì Àjọlò?
    Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 June ojú ìwé 7

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Ṣọ́ra fún Àwọn Ewu Tó Wà Nínú Ìkànnì Àjọlò

Jésù kọ̀ láti sọ òkúta di búrẹ́dì

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ: Bí ọ̀pọ̀ ohun èlò, ìkànnì àjọlò wúlò lápá kan, ó sì léwu lápá kan. Àwọn Kristẹni kan ti pinnu pé àwọn ò ní lo ìkànnì àjọlò rárá. Àwọn Kristẹni míì sì ń lò ó láti máa bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ sọ̀rọ̀. Àmọ́, Èṣù fẹ́ ká máa lo ìkànnì àjọlò ní ìlòkulò, ìyẹn sì lè ba orúkọ rere wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Bíi ti Jésù, àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ewu tó wà níbẹ̀, ká sì yẹra fún wọn.​—Lk 4:​4, 8, 12.

ÀWỌN EWU TÓ YẸ KÁ ṢỌ́RA FÚN:

  • Ṣíṣe àṣejù nídìí ìkànnì àjọlò. Tá a bá ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí lórí ìkànnì àjọlò, èyí ò ní jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí.

    Àwọn ìlànà Bíbélì: Ef 5:​15, 16; Flp 1:10

  • Wíwo àwọn nǹkan tí kò bójú mu. Téèyàn bá ń wo àwòrán àwọn tó ṣí ara sílẹ̀, tó bá yá, onítọ̀hún lè bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwọn ohun tó ń mú ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí kó tiẹ̀ ṣe ìṣekúṣe. Tá a bá ń ka ìsọfúnni táwọn apẹ̀yìndà gbé sórí ìkànnì àjọlò, ó lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.

    Àwọn ìlànà Bíbélì: Mt 5:28; Flp 4:8

  • Gbígbé ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí kò dáa sórí ìkànnì. Torí pé ọkàn máa ń tanni jẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tàbí àwòrán tí kò dáa sórí ìkànnì àjọlò. Àmọ́, èyí lè ba àwọn ẹlòmíì lórúkọ jẹ́ tàbí kó jin ìgbàgbọ́ wọn lẹ́sẹ̀.

    Àwọn ìlànà Bíbélì: Ro 14:13; Ef 4:29

WO FÍDÍÒ NÁÀ MÁA FỌGBỌ́N LO ÌKÀNNÌ ÀJỌLÒ, KÓ O SÌ RONÚ LÓRÍ BÍ WÀÁ ṢE YẸRA FÚN ÀWỌN EWU YÌÍ:

Olè kan rí ohun tẹ́nì kan gbé sórí ìkànnì àjọlò, èyí sì jẹ́ kó mọ̀ pé ẹni náà ti rìnrìn-àjò
Agbanisíṣẹ́ kan rí àwòrán tí kò dáa lórí ìkànnì àjọlò nípa ẹnì tó fẹ́ gbà síṣẹ́
Ìsọkúsọ pọ̀ gan-an lórí ìkànnì àjọlò
Kò rọrùn fún ọkùnrin kan láti dìde láàárọ̀ lẹ́yìn tó ti lo gbogbo òru lórí ìkànnì àjọlò
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́