ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwbr18 September ojú ìwé 1-6
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
  • Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2018
  • Ìsọ̀rí
  • SEPTEMBER 3-9
  • SEPTEMBER 10-16
  • SEPTEMBER 17-23
  • SEPTEMBER 24-30
Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé—2018
mwbr18 September ojú ìwé 1-6

Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka Sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni

SEPTEMBER 3-9

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 1-2

“Iṣẹ́ Ìyanu Àkọ́kọ́ Tí Jésù Ṣe”

w15 6/15 4 ¶3

Kristi—Agbára Ọlọ́run

3 Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́ níbi ìgbéyàwó kan tó wáyé ní ìlú Kánà ti Gálílì. Ó ṣeé ṣe kí iye àwọn tí wọ́n wá síbi ìgbéyàwó náà pọ̀ ju àwọn tí wọ́n pè lọ. Torí náà, wáìnì wọn tán. Màríà ìyá Jésù wà lára àwọn tí wọ́n pè síbi ìgbéyàwó náà. Láìsí àní-àní, Màríà á ti máa ronú lórí gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí ọmọ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ó mọ̀ pé ọmọ náà máa di ẹni tí à ń pè ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” (Lúùkù 1:30-32; 2:52) Ǹjẹ́ ó gbà gbọ́ pé àwọn agbára kàn ṣì wà lára Jésù tí kò tíì fara hàn? Ó dájú pé nígbà tí Jésù àti Màríà wà ní Kánà, wọ́n káàánú tọkọtaya tuntun yìí, wọn ò sì fẹ́ kí ojú tì wọ́n. Jésù mọ̀ pé ojúṣe wa ló jẹ́ láti máa ṣe aájò àlejò. Nítorí náà, ó sọ omi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àgbá méjì di “wáìnì àtàtà.” (Ka Jòhánù 2:3, 6-11.) Ṣé ọ̀ranyàn ni kí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí? Rárá o. Ńṣe ló káàánú àwọn èèyàn, tó sì fìwà ọ̀làwọ́ jọ Baba rẹ̀ ọ̀run.

jy 41 ¶6

Iṣẹ́ Ìyanu Tí Jésù Kọ́kọ́ Ṣe

Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù kọ́kọ́ ṣe nìyẹn. Nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù rí iṣẹ́ ìyanu tó ṣe yìí, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Jésù, ìyá rẹ̀, àtàwọn àbúrò rẹ̀ rìnrìn àjò lọ sí ìlú Kápánáúmù tó wà ní etíkun Òkun Gálílì.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 1:1

Ọ̀rọ̀ náà: Tàbí “Logos.” Lédè Gíríìkì, ho loʹgos ni wọ́n ń pè é. Bí wọ́n ṣe lò ó bí orúkọ oyè níbí, bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe lò ó nínú Jo 1:14 àti Iṣi 19:13. Jòhánù jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù ló ń jẹ́ orúkọ oyè yìí. Bíbélì lo orúkọ oyè yìí fún Jésù nígbà tó jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́run, nígbà tó jẹ́ èèyàn pípé lórí ilẹ̀ ayé tó sì ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti lẹ́yìn tó pa dà sí ọ̀run. Jésù ni Ọlọ́run máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rán, a tún lè pè é ní Agbọ̀rọ̀sọ, tórí ó máa ń jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an, ó sì máa ń fún àwọn ańgẹ́lì tó kù àtàwọn èèyàn ní ìtọ́ni Ọlọ́run. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti ronú pé kí Jésù tó wá sáyé ni Jèhófà ti ń lò ó láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, òun ni ańgẹ́lì tí Jèhófà ń gbẹnu ẹ̀ sọ̀rọ̀.​—Jẹ 16:7-11; 22:11; 31:11; Ẹk 3:2-5; Ond 2:1-4; 6:11, 12; 13:3.

pẹ̀lú: Ní tààràtà, ó túmọ̀ sí “ní tòsí.” Àmọ́ láyìíká ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ àpèjúwe èdè Gíríìkì náà pros túmọ̀ sí kí nǹkan sún mọ́ tàbí wà pẹ̀lú. Èyí fi hàn pé àwọn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ibí yìí ń sọ nípa rẹ̀, ìyẹn Ọ̀rọ̀ náà àti Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.

Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ ọlọ́run kan: Tàbí “Ọ̀rọ̀ náà wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run [tàbí, “ẹni bí ọlọ́run”].” Ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ yìí ṣàpèjúwe ohun tí Jésù Kristi tó jẹ́ “Ọ̀rọ̀ náà” (ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà, ho loʹgos; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Ọ̀rọ̀ náà nínú ẹsẹ yìí) máa ń ṣe. Ipò ńlá ni Ọ̀rọ̀ náà wà bó ṣe jẹ́ àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, òun sì ni Ọlọ́run lò láti dá gbogbo nǹkan tó kù, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pè é ní “ọlọ́run; ẹ̀dá bí ọlọ́run; àtọ̀runwá; ẹni tó tọ̀run wá.” Torí apá tó sọ pé “Ọ̀rọ̀ náà sì jẹ́ Ọlọ́run,” ọ̀pọ̀ àwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì gbà pé ìkan náà ni òun àti “Ọlọ́run Olódùmarè.” Àmọ́, àwọn ìdí pàtàkì wà tá a fi lè sọ pé ohun tí Jòhánù ní lọ́kàn kọ́ nìyẹn. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, gbólóhùn tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e jẹ́ kó ṣe kedere pé “Ọ̀rọ̀ náà” wà “pẹ̀lú Ọlọ́run.” Ohun míì tún ni pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà the·osʹ fara hàn lẹ́ẹ̀mẹta nínú ẹsẹ kìíní àti kejì. Níbi àkọ́kọ́ àti ibi kẹta tó ti hàn, ọ̀rọ̀ atọ́ka ló ṣáájú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà the·osʹ àmọ́ níbi kejì to ti fara hàn, kò sí ọ̀rọ̀ atọ́ka níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló gbà pé bí kò ṣe sí ọ̀rọ̀ atọ́ka ṣáájú the·osʹ kejì yìí ní ìtumọ̀ tó ṣe pàtàkì. Bí wọ́n ṣe lo ọ̀rọ̀ atọ́ka nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé the·osʹ ń tọ́ka sí Ọlọ́run Olódùmarè. Nǹkan míì ni pé, bí ọ̀rọ̀ atọ́ka kò ṣe sí níbi kejì tí the·osʹ ti fara hàn jẹ́ ká rí i pé ó kàn ń ṣàpèjúwe “Ọ̀rọ̀ náà” pé ó ní ànímọ́ Ọlọ́run. Torí náà, àwọn Bíbélì mélòó kan tí wọ́n tú sí èdè Gẹ̀ẹ́sì, Faransé àti èdè Jámánì túmọ̀ ẹsẹ yìí bó ṣe wà nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ìtumọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọ̀rọ̀ náà” jẹ́ “ọlọ́run kan; àtọ̀runwá; ẹni tó wá látọ̀run; ẹ̀dá àtọ̀runwá; ẹni bí ọlọ́run.” Ìhìn Rere Jòhánù tí wọ́n túmọ̀ láyé àtijọ́ sí èdè ìbílẹ̀ Sahidic àti Bohairic tó wá látinú èdè Coptic náà ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta sí kẹrin Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe ìwé yìí, bí wọ́n sì ṣe túmọ̀ the·osʹ tó kọ́kọ́ fara hàn nínú Jo 1:1 yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe túmọ̀ rẹ̀ níbi kejì. Gbólóhùn tí wọ́n lò nínú ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé “Ọ̀rọ̀ náà” ní ànímọ́ kan tó jọ ti Ọlọ́run, àmọ́ wọn ò sọ pé òun àti Baba rẹ̀ Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́ ìkan náà. Níbàámu pẹ̀lú ẹsẹ yìí, Kol 2:9 sọ pé Kristi ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ànímọ́ Ọlọ́run.” Kódà, 2Pe 1:4 sọ pé àwọn àjùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi máa “di alájọpín ìwà ẹ̀dá ti ọ̀run.” Láfikún síyẹn, nínú Bíbélì Septuagint, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà the·osʹ ni wọ́n sábà máa ń lò fún ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run,” ʼel àti ʼelo·himʹ, tí wọ́n gbà pé ó túmọ̀ sí “Alágbára Ńlá; Alágbára.” Wọ́n máa ń lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù yìí tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run olódùmarè, àwọn ọlọ́run míì àtàwọn èèyàn. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 10:34.) Bí wọ́n ṣe pe Ọ̀rọ̀ náà ní “ọlọ́run,” tàbí “alágbára ńlá,” bá àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ais 9:6 mu, níbi tó sọ pé Mèsáyà máa jẹ́ “Ọlọ́run Alágbára Ńlá” (kì í ṣe “Ọlọ́run Olódùmarè”) ó tún máa jẹ́ “Baba Ayérayé” fún gbogbo àwọn tó bá láǹfààní láti wà nínú Ìjọba rẹ̀. Ìtara Baba rẹ̀, ìyẹn “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,” máa ṣe èyí.​—Ais 9:7.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 1:29

Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run: Lẹ́yìn tí Jésù ṣèrìbọmi, tó sì pa dà dé lẹ́yìn tí Èṣù ti dán an wò, Jòhánù Oníbatisí pe Jésù ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run.” Inú ẹsẹ yìí àti Jo 1:36 nìkan lọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn. (Wo Àfikún 4A.) Ó bá a mu bí wọ́n ṣe fi Jésù wé ọ̀dọ́ àgùntàn. Nínú Bíbélì, wọ́n máa ń fi àgùntàn rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, kí wọ́n sì lè bá Ọlọ́run rẹ́ pa dà. Èyí jẹ́ ká rí bí Jésù ṣe máa fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé rúbọ fún gbogbo aráyé. Ọ̀rọ̀ náà “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run” lè tọ́ka sí àwọn gbólóhùn míì nínú Ìwé Mímọ́. Torí pé Jòhánù mọ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù dáadáa, ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tó sọ máa tọ́ka sí ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí: àgbò tí Ábúráhámù fi rúbọ dípò Ísákì ọmọkùnrin rẹ̀ (Jẹ 22:13), ọ̀dọ́ àgùntàn Ìrékọjá tí wọ́n pa nílẹ̀ Íjíbítì káwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè bọ́ lóko ẹrú (Ẹk 12:1-13) tàbí ẹgbọrọ àgbò tí wọ́n fi ń rúbọ lórí pẹpẹ Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù lárààárọ̀ àti ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ (Ẹk 29:38-42). Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ́ lẹ̀ wà lọ́kàn Jòhánù, níbi tí Aísáyà ti sọ pé wọ́n ń mú ẹni tí Jèhófà pè ní “ìránṣẹ́ mi,” “bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa.” (Ais 52:13; 53:​5, 7, 11) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà àkọ́kọ́ sáwọn ará nílùú Kọ́ríńtì, ó pe Jésù ní àgùntàn “ìrékọjá wa.” (1Kọ 5:7) Àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa “ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bíi ti ọ̀dọ́ àgùntàn aláìlábààwọ́n àti aláìléèérí” tí Kristi ní. (1Pe 1:19) Nínú ìwé Ìṣípayá, ó ju ìgbà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) lọ tí wọ́n pe Jésù tá a ṣe lógo ní “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.​—Àpẹẹrẹ àwọn ibi tá a ti lè rí i ni: Iṣi 5:8; 6:1; 7:9; 12:11; 13:8; 14:1; 15:3; 17:14; 19:7; 21:9; 22:1.

SEPTEMBER 10-16

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 3-4

“Jésù Wàásù fún Obìnrin Ará Samáríà Kan”

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:6

tí ó ti rẹ̀: Inú ẹsẹ Bíbélì yìí nìkan ni wọ́n ti sọ pé ‘ó rẹ’ Jésù, ìyẹn ní nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárọ̀ ọjọ́ yẹn ni Jésù rìnrìn àjò láti Àfonífojì Jọ́dánì ní Jùdíà lọ sí Síkárì ní Samáríà, tó wà lórí òkè to ga tó ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) mítà (3,000 ft) tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.​—Jo 4:3-5; Wo Àfikún 4A.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 3:29

ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó: Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ẹni kan tó sún mọ́ ọkọ tó máa ń ṣojú fún ọkùnrin tó bá fẹ́ ṣègbéyàwó lórí ọ̀rọ̀ òfin, tó sì máa ń kópa pàtàkì nínú ìpalẹ̀mọ́ fún ètò ìgbéyàwó náà. Òun làwọn èèyàn mọ̀ sí ẹni tó so ọkọ àtìyàwó pọ̀. Lọ́jọ́ ìgbéyàwó, àwọn tó máa fẹsẹ̀ rajó níwájú tọkọtìyàwó máa ti dé sílé ọkọ ìyàwó tàbí sílé bàbá rẹ̀, níbi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Lásìkò tí ayẹyẹ yìí bá ń lọ lọ́wọ́, inú ọ̀rẹ́ ọkọ máa ń dùn tó bá ń gbọ́ ohùn ọkọ ìyàwó bó ṣe ń bá ìyàwó rẹ̀ sọ̀rọ̀, torí èyí máa fọkàn ọ̀rẹ́ náà balẹ̀ pé gbogbo ètò tí òun ṣe ló yọrí sí rere. Jòhánù Oníbatisí fi ara rẹ̀ wé “ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó.” Jésù ni ọkọ ìyàwó, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lápapọ̀ sì ni ìyàwó rẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Láti ṣètò sílẹ̀ fún Mèsáyà, Jòhánù Oníbatisí ló mú kí ẹgbẹ́ àkọ́kọ́ lára “ìyàwó” náà mọ Jésù Kristi. (Jo 1:29, 35; 2Kọ 11:2; Ef 5:22-27; Iṣi 21:2, 9) Tí “ọ̀rẹ́ ọkọ ìyàwó” bá parí iṣẹ́ rẹ̀ dáadáa, tí tọkọtìyàwó ti mọra wọn tán, kò ní sójú lára ọ̀rẹ́ ọkọ mọ́. Ìdí nìyẹn tí Jòhánù fi sọ nípa ara rẹ̀ nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù pé: “Ẹni yẹn yóò máa bá a lọ ní pípọ̀ sí i, ṣùgbọ́n èmi yóò máa bá a lọ ní pípẹ̀dín.”​—Jo 3:30.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:10

omi ààyè: Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí ni wọ́n máa ń lò fún odò tó ń ṣàn, omi tó ń sun tàbí omi tó mọ́ tó sun sínú kànga. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí omi tí kì í ṣàn tó wà nínú àmù ńlá. Nínú Le 14:5, “omi ààyè” ni ìtumọ̀ tààràtà fún ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “omi tí ó ṣeé mu.” Nínú Jer 2:13 àti 17:13, Jèhófà ni wọ́n fi wé “orísun [tàbí, “odò”] omi ààyè,” ìyẹn ni, omi tó ń fúnni ní ìyè lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “omi ààyè” lọ́nà àpèjúwe nígbà tó ń bá obìnrin ará Samáríà náà sọ̀rọ̀, àmọ́ ńṣe ni obìnrin náà kọ́kọ́ ronú pé omi gidi ni Jésù ń sọ.​—Jo 4:11; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:14.

SEPTEMBER 17-23

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 5-6

“Ní Èrò Tó Tọ́ Bó O Ṣe Ń Tẹ̀lé Jésù”

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:10

àwọn ènìyàn náà rọ̀gbọ̀kú, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún ní iye: Àkọsílẹ̀ Mátíù nìkan ló fi kún un pé “àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké” wà lára àwọn tí Jésù bọ́ lọ́nà ìyanu. (Mt 14:21) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpapọ̀ iye àwọn tí Jésù bọ́ lọ́nà ìyanu ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) lọ.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:14

Wòlíì: Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ló gbà pé Mèsáyà tí àwọn ń retí ni wòlíì tó máa dà bíi Mósè, bó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Di 18:​15, 18. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn náà bọ̀ wá sí ayé máa tọ́ka sí Mèsáyà tí wọ́n ń retí. Jòhánù nìkan ló ṣe àkọsílẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú ẹsẹ yìí.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:27, 54

oúnjẹ tí ń ṣègbé . . . oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun: Jésù mọ̀ pé nítorí ohun tí wọ́n máa rí gbà ni àwọn kan ṣe ń tẹ̀ lé òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn òun kiri. Bó ṣe jẹ́ pé oúnjẹ tara máa ń gbé ẹ̀mí ró lójoojúmọ́, “oúnjẹ” látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti wà láàyè títí láé. Jésù rọ àwọn èrò náà pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ . . . fún “oúnjẹ tí ó wà títí ìyè àìnípẹ̀kun,” ìyẹn ni pé, kí wọ́n túbọ̀ sapá láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì nígbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n ń kọ́.​—Mt 4:4; 5:3; Jo 6:28-39.

fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi: Àyíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. (Jo 6:35, 40) Ọdún 32 Sànmánì Kristẹni ni Jésù sọ̀rọ̀ yìí, torí náà kì í ṣe ọ̀rọ̀ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ló ń sọ, torí ó ṣì di ẹ̀yìn ọdún kan kó tó gbé ètò yẹn kalẹ̀. Ó sọ ọ̀rọ̀ yẹn ṣáájú “Ìrékọjá, àjọyọ̀ àwọn Júù” (Jo 6:4), kó lè fi rán àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ létí àjọyọ̀ tó ń máa tó wáyé, kí wọ́n sì mọ ìjẹ́pàtàkì bí ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn náà ṣe gba ẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì là lálẹ́ ọjọ́ tí wọ́n kúrò nílẹ̀ Íjíbítì (Ẹk 12:24-27). Lọ́nà kan náà, ṣe ni Jésù ń tẹnu mọ́ ipa pàtàkì tí ẹ̀jẹ̀ òun máa kó, nípa bó ṣe máa mú kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí ìyè àìnípẹ̀kun.

w05 9/1 21 ¶13-14

A ó Máa Rìn Ní Orúkọ Jèhófà Ọlọ́run Wa

13 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn èèyàn náà pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ wá Jésù rí. Ìwé Jòhánù sì sọ pé wọ́n rí i ní “òdì-kejì òkun.” Kí nìdí tí wọ́n fi ń wá Jésù kiri nígbà tó jẹ́ pé kò fẹ́ kí wọ́n fi òun jọba? Ohun tó ń da ọ̀pọ̀ wọn láàmú ni pé ojú ẹ̀dá èèyàn ni wọ́n fi ń wo ọ̀ràn náà, wọ́n ń tẹnu mọ́ àwọn nǹkan tara tí Jèhófà pèsè nínú aginjù nígbà ayé Mósè. Ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé kí Jésù ṣáà máa pèsè oúnjẹ fáwọn ní gbogbo ìgbà. Jésù mọ ohun tí kò tọ́ tó wà lọ́kàn wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní àwọn ohun tó jẹ́ òtítọ́ tẹ̀mí tó lè mú kí wọ́n tún inú wọn rò. (Jòhánù 6:17, 24, 25, 30, 31, 35-40) Àmọ́, ńṣe làwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí i, pàápàá nígbà tó sọ àkàwé kan pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín. Ẹni tí ó bá ń fi ẹran ara mi ṣe oúnjẹ jẹ, tí ó sì ń mu ẹ̀jẹ̀ mi ní ìyè àìnípẹ̀kun, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”​—Jòhánù 6:53, 54.

14 Àwọn àkàwé Jésù sábà máa ń mú káwọn èèyàn fi hàn bóyá wọ́n fẹ́ láti bá Ọlọ́run rìn lóòótọ́ tàbí wọn ò fẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni àkàwé rẹ̀ tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ yìí ṣe rí. Ó mú káwọn èèyàn fi bí wọ́n ṣe jẹ́ hàn. A kà á pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, wí pé: ‘Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?’ ” Ni Jésù bá ṣàlàyé pé ó yẹ kí ìtumọ̀ tẹ̀mí tí ọ̀rọ̀ òun ní yé wọn. Ó ní: “Ẹ̀mí ni ó ń fúnni ní ìyè; ẹran ara kò wúlò rárá. Àwọn àsọjáde tí mo ti sọ fún yín, ẹ̀mí ni wọ́n, ìyè sì ni wọ́n.” Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ò fẹ́ gbọ́yẹn rárá. Ìtàn náà sọ pé: “Ní tìtorí èyí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, wọn kò sì jẹ́ bá a rìn mọ́.”​—Jòhánù 6:60, 63, 66.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:44

fà á: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà “fà” máa ń tọ́ka sí bí èèyàn ṣe ń fa àwọ̀n ẹja (Jo 21:6, 11), àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run máa ń fi tipátipá fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ìṣe yìí tún lè túmọ̀ sí “fa ojú nǹkan mọ́ra,” ohun tí Jésù sọ náà sì fara jọ ohun tó wà nínu Jer 31:3, níbi tí Jèhófà ti sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ pé: ‘Mo fi inú-rere-onífẹ̀ẹ́ fà ọ́.’ (Bíbélì Septuagint náà lo ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì kan náà níbí.) Jo 12:32 fi hàn pé bí Jésù ṣe máa ń fa onírúurú èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ nìyẹn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ti fún wa lómìnira láti yan ohun tó wù wá. Tó bá dọ̀rọ̀ ká sin Ọlọ́run, olúkúlùkù ló máa pinnu ohun tó fẹ́ ṣe. (Di 30:19, 20) Ọlọ́run máa ń rọra fa àwọn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (Sm 11:5; Owe 21:2; Iṣe 13:48) Jèhófà máa ń lo Bíbélì àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn tí Baba fà sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ais 54:13 ń tọ́ka sí, inú ẹsẹ yẹn ni ọ̀rọ̀ inú Jo 6:45 ti wá.​—Fi wé Jo 6:65.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:64

Jésù mọ . . . ẹni tí yóò dà á: Júdásì Ísíkáríótù ni Jésù ń tọ́ka sí. Gbogbo òru ni Jésù fi gbàdúrà sí Baba rẹ̀ kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá. (Lk 6:12-16) Torí náà, Júdásì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run níbẹ̀rẹ̀. Àmọ́, Jésù mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹni tó sún mọ́ òun ló máa da òun. (Sm 41:9; 109:8; Jo 13:18, 19) Gbàrà tí Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí í ní èrò búburú ni Jésù ti mọ̀, torí Jésù lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni àti ohun téèyàn ń rò. (Mt 9:4) Torí pé Ọlọ́run lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, ìdí nìyẹn tó fi mọ̀ pé ẹnìkan tí Jésù fọkàn tán gan-an máa di ọ̀dàlẹ̀. Àmọ́, àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti bó ṣe bá àwọn èèyàn lò láyé àtijọ́ jẹ́ ká mọ̀ pẹ́, Ọlọ́run ò kádàrá pé Júdásì ni ẹni tó gbọ́dọ̀ dalẹ̀ Jésù.

láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀: Gbólóhùn yìí kò túmọ̀ sí ìgbà tí wọ́n bí Júdásì tàbí ìgbà tí Jésù yàn án bí àpọ́sítélì, ìyẹn lẹ́yìn tí Jésù fi gbogbo òru gbàdúrà. (Lk 6:12-16) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń tọ́ka sí ìgbà tí Júdásì bẹ̀rẹ̀ sí í gbèrò nǹkan burúkú, tí Jésù sì mọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. (Jo 2:24, 25; Iṣi 1:1; 2:23; wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 6:70; 13:11.) Èyí tún fi hàn pé Júdásì ti ronú nípa nǹkan tó fẹ́ ṣe, ó sì tún ṣètò bó ṣe máa ṣe é, kì í ṣe pé ọkàn rẹ̀ kàn ṣàdédé yí pa dà. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” (lédè Gíríìkì, ar·kheʹ) sinmi lórí àyíká ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ti lò ó. Bí àpẹẹrẹ, nínú 2Pe 3:4, “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” tọ́ka sí ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá. Ṣùgbọ́n lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n tún máa ń lò ó fún ìbẹ̀rẹ̀ nǹkan míì. Bí àpẹẹrẹ, Pétérù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn Kèfèrí “gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti bà lé wa ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.” (Iṣe 11:15) Kì í ṣe ìgbà tí wọ́n bí Pétérù ló ń sọ níbí tàbí ìgbà tó di àpọ́sítélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ìgbà yẹn ni “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” bá a ṣe tú ẹ̀mí mímọ́ jáde fún ìdí pàtàkì kan. (Iṣe 2:1-4) A lè rí àwọn àpẹẹrẹ míì nípa bí àyíká ọ̀rọ̀ ṣe yí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀” pa dà nínú Lk 1:2; Jo 15:27; àti 1Jo 2:7.

SEPTEMBER 24-30

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÒHÁNÙ 7-8

“Jésù Yin Baba Rẹ̀ Lógo”

cf 100-101 ¶5-6

“A Ti Kọ Ọ́ Pé”

5 Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ ibi tóun ti ń rí ọ̀rọ̀ tóun ń sọ. Ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Lákòókò míì, ó ní: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòhánù 8:28) Ìgbà kan tún wà tó sọ pé: “Àwọn nǹkan tí mo ń sọ fún yín ni èmi kò sọ láti inú àpilẹ̀ṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n Baba tí ó dúró ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 14:10) Ọ̀nà kan tí Jésù gbà fi hàn pé òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn ni bó ṣe máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó wà lákọọ́lẹ̀ lemọ́lemọ́.

6 Nígbà tá a fara balẹ̀ wo àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tó wà nínú Bíbélì, a rí i pé ó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú èyí tó ju ìdajì lọ lára àwọn ìwé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó fa àwọn kan yọ ní tààràtà, ó sì tọ́ka sáwọn míì. O lè máa rò pé ìyẹn kì í ṣe nǹkan bàbàrà. O lè máa ronú nípa ìdí tí kì í fi í ṣe inú gbogbo ìwé tó para pọ̀ di Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló ti fa ọ̀rọ̀ yọ ní gbogbo ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tó fi wàásù tó sì kọ́ àwọn èèyàn ní gbàngba. Àmọ́ tá a bá wò ó dáadáa, àfàìmọ̀ ni kì í ṣe pé látinú gbogbo ìwé náà ló ti fa ọ̀rọ̀ yọ. Má gbàgbé pé díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àtohun tó ṣe ni wọ́n kọ sílẹ̀. (Jòhánù 21:25) Ká sòótọ́, tó o bá ka gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n kọ sílẹ̀, ó lè má gbà ọ́ ju wákàtí mélòó kan lọ. Kó o fi lè mọ̀ pé ibi tí Jésù fà yọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò kéré, jẹ́ ká gbà pé ò ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀ fún ìwọ̀nba wákàtí bíi mélòó kan, tó o sì wá gbìyànjú láti tọ́ka sí iye tó ju ìdajì lọ lára Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù lẹ́nu ìwọ̀nba àkókò kéréje yẹn, ṣéyẹn ò pọ̀ tó? Ohun tó mú kí ohun tí Jésù ṣe túbọ̀ wúni lórí ni pé kò ní àkájọ ìwé wọ̀nyẹn lọ́wọ́. Ìgbà tó ń ṣe ìwàásù tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè, àìmọye ìtọ́ka ló ṣe sínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, yálà ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà. Gbogbo rẹ̀ sì jẹ́ láti orí wá!

w11 3/15 11 ¶19

Ẹ̀mí Ọlọ́run Ni Kó O Gbà, Má Ṣe Gba Ẹ̀mí Ayé

19 Máa ṣègbọràn sí Jèhófà nínú ohun gbogbo. Ìgbà gbogbo ni Jésù máa ń ṣe àwọn nǹkan tó dùn mọ́ Bàbá rẹ̀ nínú. Ó kéré tán, lẹ́ẹ̀kan, ọ̀nà tí Jésù fẹ́ láti gbà bójú tó ọ̀ràn kan yàtọ̀ sí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ fún un. Síbẹ̀, ìgbọ́kànlé tó ní nínú Bàbá rẹ̀ mú kó sọ pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.” (Lúùkù 22:42) Wá bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ mo máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run kódà nígbà tí kò bá rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run ká bàa lè máa wà láàyè. A gbọ́dọ̀ máa ṣègbọràn sí i nínú ohun gbogbo torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa, òun ní Orísun ìwàláàyè wa, òun náà ló sì ń gbé ìwàláàyè wa ró. (Sm. 95:6, 7) Kò sí ohun tá a lè fi rọ́pò ìgbọràn. A kò lè rí ojú rere Ọlọ́run àfi tá a bá ń ṣègbọràn sí i.

Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

w07 2/1 6 ¶4

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Sọ Òótọ́?

Àpẹẹrẹ wo ni Jésù Kristi fi lélẹ̀ lórí èyí? Nígbà kan, Jésù ń bá àwọn kan sọ̀rọ̀ tí wọn kì í ṣe ọmọlẹ́yìn rẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fẹ́ mọ̀ nípa bó ṣe fẹ́ rin ìrìn rẹ̀. Wọ́n gbà á nímọ̀ràn, wọ́n ní: “Ré kọjá kúrò ní ìhín, kí o sì lọ sí Jùdíà.” Báwo ni Jésù ṣe dá wọn lóhùn? Ó sọ pé: “Ẹ̀yin ẹ máa gòkè lọ sí àjọyọ̀ náà [ní Jerúsálẹ́mù]; kò tíì yá mi tí èmi yóò gòkè lọ sí àjọyọ̀ yìí, nítorí àkókò yíyẹ mi kò tíì dé ní kíkún.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni Jésù wá lọ sí Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe àjọyọ̀ yẹn. Kí nìdí tó fi dá wọn lóhùn lọ́nà yẹn? Nítorí pé wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀ nípa bó ṣe fẹ́ rin ìrìn rẹ̀ ni. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò sọ ohun tí kì í ṣòótọ́, síbẹ̀ ìdáhùn tó fún wọn kò kún, torí àtilè dín jàǹbá tó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣe fóun tàbí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ kù. Èyí kì í ṣe irọ́, nítorí pé àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé nípa Kristi pé: “Kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀.”​—Jòhánù 7:1-13; 1 Pétérù 2:22.

nwtsty àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 8:58

èmi ti wà: Àwọn Júù tó ń tako Jésù fẹ́ sọ ọ́ ní òkúta nítorí pé Jésù sọ pé òun ti “rí Ábúráhámù,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí wọ́n ṣe sọ, Jésù “kò tíì tó ẹni àádọ́ta ọdún.” (Jo 8:57) Àmọ́, ohun tí Jésù fẹ́ kí wọ́n mọ̀ ni pé ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni òun lọ́run kí òun tó wá sáyé, òun sì ti wà kí wọ́n tó bí Ábúráhámù. Àwọn kan gbà pé ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí pé ìkan náà ni Jésù àti Ọlọ́run. Wọ́n jiyàn pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níbí, ìyẹn e·goʹ ei·miʹ (àwọn Bíbélì kan pè é ní “Mo wà”) àti ọ̀rọ̀ tí Bíbélì Septuagint lò nínú Ẹk 3:14 dọ́gbọ́n jọra, torí náà, ìtúmọ̀ kan náà ló yẹ kí ẹsẹ méjèèjì ní. (Wo àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Jo 4:26.) Àmọ́ nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà ei·miʹ fi hàn pé Jésù ti wà ṣáájú “kí Ábúráhámù tó wà” ó sì tún ń wà nìṣó. Torí náà, “Èmi ti wà” bá ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà mu dípò “Mo wà,” àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ti pẹ́ àti tòde oní náà lo ọ̀rọ̀ kan náà tó jọ “Èmi ti wà.” Kódà, nínú Jo 14:​9, ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì ei·miʹ kan náà ni Bíbélì lò nígbà tí Jésù sọ pé: “Èmi ha ti wà pẹ̀lú yín fún àkókò gígùn tó bẹ́ẹ̀, síbẹ̀, Fílípì, ìwọ kò sì tíì mọ̀ mí?” Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì ló lo ọ̀rọ̀ tó jọra pẹ̀lú èyí, ó ṣe kedere pé kì í ṣe àṣìṣe tí wọ́n bá túmọ̀ ei·miʹ sí “ti wà,” tó bá ti bá àyíká ọ̀rọ̀ mu. (Àwọn ibòmíì tí wọ́n ti lo ọ̀rọ̀ ìṣe nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ tó sì tún ń bá a nìṣó fún ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì tó ń ṣàpèjúwe nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ ni Lk 2:48; 13:7; 15:29; Jo 1:9; 5:6; 15:27; Iṣe 15:21; 2Co 12:19; 1Jo 3:8.) Bákan náà, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ tó wà ní Jo 8:54, 55 fi hàn pé kì í ṣe pé ó ń gbé ara rẹ̀ sípò kan náà pẹ̀lú Baba rẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́