ORIN 55
Ẹ Má Bẹ̀rù Wọn!
1. Èèyàn mi, ẹ tẹ̀ síwájú,
Ẹ wàásù Ìjọba náà.
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ọ̀tá.
Ẹ jẹ́ kí aráyé mọ̀
Pé Jésù Ọmọ mi, Ọba
Ti lé ọ̀tá jù sáyé.
Láìpẹ́, yóò mú Èṣù, yóò sì
Tú àwọn tó dè sílẹ̀.
(ÈGBÈ)
Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá
Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.
Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́
Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.
2. Bí àwọn ọ̀tá yín tiẹ̀ pọ̀,
Tí wọ́n sì ń halẹ̀ mọ́ yín,
Tí wọ́n ń fi yín ṣẹlẹ́yà,
Kí wọ́n lè ṣì yín lọ́nà,
Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin tèmi
Bí wọ́n tiẹ̀ ń fìyà jẹ yín.
Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́
Títí wọn yóò fi ṣẹ́gun.
(Ègbè)
Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá
Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.
Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́
Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.
3. Má ṣe rò pé mo pa ọ́ tì,
Èmi ṣì ni ààbò rẹ.
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé o kú,
Èmi yóò jí ọ dìde.
Má bẹ̀rù àwọn tó ń para,
Tí wọn kò lè pa ọkàn.
Jẹ́ olóòótọ́ títí dópin,
Màá fún ọ ládé ìyè!
(Ègbè)
Ẹ má bẹ̀rù àwọn ọ̀tá
Bí wọ́n tiẹ̀ ń halẹ̀ mọ́ yín.
Èmi yóò pa olóòótọ́ mọ́
Gẹ́gẹ́ bí ẹyinjú mi.
(Tún wo Diu. 32:10; Neh. 4:14; Sm. 59:1; 83:2, 3.)