MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Jèhófà Ló Bá Wa Tọ́ Àwọn Ọmọ Wa
Kí làwọn tọkọtaya lè rí kọ́ lára Baba wa ọ̀run Jèhófà, tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú? Wo fídíò náà Jèhófà Ló Bá Wa Tọ́ Àwọn Ọmọ Wa, kó o sì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí nípa Abilio àti Ulla Amorim:
Ṣé àwọn ohun tí wọ́n kọ́ nígbà tí wọ́n wà ní kékeré ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè tọ́ àwọn ọmọ wọn?
Àwọn nǹkan wo ni àwọn ọmọ wọn gbádùn nígbà tí wọ́n wà ní kékeré?
Báwo ni Abilio àti Ulla ṣe fi Diutarónómì 6:6, 7 sílò?
Kí nìdí tí wọn ò kàn kí ń pàṣẹ fún àwọn ọmọ wọn?
Báwo ni wọ́n ṣe ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ ní ìgbésí ayé wọn?
Àwọn nǹkan wo ni àwọn òbí yẹn yááfì bí wọ́n ṣe ń rọ àwọn ọmọ wọn pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún? (bt 178 ¶19)