ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 2 ojú ìwé 5
  • Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ̀rọ̀ Bí Ọlọ́run Ṣe Dá Ọ
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 2 ojú ìwé 5

Ẹ̀KỌ́ 2

Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀

Ẹsẹ Bíbélì

2 Kọ́ríńtì 2:17

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Sọ̀rọ̀ bó o ṣe máa ń sọ̀rọ̀ gangan, sọ̀rọ̀ látọkàn wá, jẹ́ kó hàn pé o nífẹ̀ẹ́ ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àtàwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Gbàdúrà, kó o sì múra sílẹ̀ dáadáa. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ sórí ohun tó o fẹ́ sọ láì pàfíyèsí sí ara rẹ. Jẹ́ kí àwọn kókó tó o fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí ṣe kedere lọ́kàn rẹ. Má ṣe máa ka ọ̀rọ̀ jáde bó ṣe wà nínú ìwé gẹ́lẹ́; ńṣe ni kó o sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ara rẹ.

    Àwọn àbá

    Tó o bá máa ka Bíbélì tàbí apá kan nínú ìtẹ̀jáde wa, rí i pé o múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa, kí ọ̀rọ̀ lè yọ̀ mọ́ ẹ lẹ́nu. Tó bá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan sọ lo fẹ́ kà, fi ìmọ̀lára tó yẹ kà á, àmọ́ má ṣe ki àṣejù bọ̀ ọ́.

  • Sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Ronú nípa ìdí tó fi yẹ kí àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ. Jẹ́ kí ọkàn rẹ wà lọ́dọ̀ wọn. Kíyè sí bó o ṣe dúró, bó o ṣe ń fara ṣàpèjúwe àti bí ojú rẹ ṣe rí. Àwọn nǹkan yìí máa fi hàn bóyá ohun tó ò ń sọ ti ọkàn rẹ wá àti bóyá o ka àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ sí ọ̀rẹ́.

    Àwọn àbá

    Ti pé o fẹ́ túra ká bó o ṣe ń sọ̀rọ̀ kò túmọ̀ sí pé kó o wá máa sọ̀rọ̀ láìbìkítà. Tó o bá fẹ́ buyì kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere, kó o sì lo èdè bó ṣe tọ́.

  • Máa wojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀. Máa wo ojú àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, ìyẹn níbi tí wọn ò bá ti kà á sí ìwà àrífín. Tó o bá ń sọ àsọyé, kì í ṣe àwùjọ lápapọ̀ nìkan ni kí o wò, tún wo àwọn tó wà nínú àwùjọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́