ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 13 ojú ìwé 16
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tó Dára
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ìtara
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 13 ojú ìwé 16

Ẹ̀KỌ́ 13

Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Òwe 3:21

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí bí ohun tó ò ń sọ ṣe kan ìgbésí ayé wọn, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Ronú nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ, kó o sì ronú nípa apá tó máa ṣe wọ́n láǹfààní jù lọ lára ohun tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí.

  • Jálẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ni kó o jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe. Látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ ló ti yẹ kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ti máa sọ lọ́kàn ara wọn pé, ‘Ọ̀rọ̀ yìí wúlò fún mi.’ Bó o ṣe ń ṣàlàyé kókó pàtàkì kọ̀ọ̀kan, máa sọ àwọn ọ̀nà pàtó tí wọ́n lè gbà lò ó. Má ṣe máa sọ̀rọ̀ lóréfèé.

    Àwọn àbá

    Tó o bá ń ṣàlàyé bí wọ́n ṣe lè lo àwọn ìlànà Bíbélì, sọ ọ́ pẹ̀lú ìfẹ́, kó o sì fi ọ̀rọ̀ ro ara rẹ wò. Dípò tí wàá fi sọ̀rọ̀ táá mú kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa dá ara wọn lẹ́bi, ńṣe ni kó o sọ ohun tó máa jẹ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí Jèhófà àti ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i, kó o sì fọkàn tán wọn pé ohun tó tọ́ ni wọ́n máa ṣe.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Tó o bá fẹ́ lọ wàásù, ronú nípa àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ nínú ìròyìn àtàwọn ọ̀rọ̀ míì táwọn èèyàn máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ohun tó kan àwọn èèyàn jù lákòókò yẹn ni kó o sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Fọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kó o mọ ohun tí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó jẹ ẹ́ lọ́kàn. Fara balẹ̀ gbọ́ ohun tó bá sọ, lẹ́yìn náà kó o sọ ohun tó máa ràn án lọ́wọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́